Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Tó Kàmàmà

Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Tó Kàmàmà

Ọ̀ràn Ìbànújẹ́ Tó Kàmàmà

Ọmọ oṣù mẹ́fà ni Erik. a Àmọ́, bó ṣe gùn àti bó ṣe tẹ̀wọ̀n tó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ju ti ọmọ oṣù kan tàbí méjì lọ. Yàtọ̀ sí pé kò tẹ̀wọ̀n, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì wú ikùn rẹ̀ sì wú gbentọ. Gbogbo ojú rẹ̀ wú rọ̀tọ́rọ̀tọ́. Àwọ̀ ara rẹ̀ ti ṣì. Irun orí rẹ̀ lẹ̀ pẹ́típẹ́tí mọ́ ọn lórí, ó sì gbẹ táútáú, bẹ́ẹ̀ ló fi gbogbo ara ṣe kìkì àléfọ́. Ó jọ pé ara ń kan án gan-an ni. Bí dókítà bá fẹ́ ṣàyẹ̀wò ojú Erik, àfi kó ṣọ́ra gan-an, nítorí àwọn ẹran ìsàlẹ̀ ojú rẹ̀ lè já bútẹ́. Àfàìmọ̀ ni ìṣòro yìí ò ti ṣàkóbá fún ọpọlọ Erik. Ó ṣeni láàánú pé kì í ṣe ọmọdé yìí nìkan ló wà nínú irú ipò yìí.

“ÒUN ló ń fa ikú èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọmọdé yíká ayé—iye yìí sì pọ̀ ju iye àwọn tí àrùn èyíkéyìí mìíràn tí ń gbèèràn ń pa lọ láti ìgbà tí àjàkálẹ̀ àrùn Black Death ti wáyé. Síbẹ̀, nǹkan ọ̀hún kì í ṣe àrùn tí ń gbèèràn. Ńṣe ló máa ń sọ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó bá ní in àmọ́ tí kò pa di aláàbọ̀ ara níkẹyìn. Àrùn máa ń tètè kọ lù wọ́n, ọpọlọ wọn kò sì ní jí pépé. Ó lè fi àwọn obìnrin, àwọn ìdílé, àti ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo àwùjọ lódindi sínú ewu.”—Ìwé The State of the World’s Children tí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣètò fún Àwọn Ọmọdé tẹ̀ jáde.

Àìsàn wo ni ìwé yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Àìjẹunrekánú ni. Ní pàtàkì, àìjẹunrekánú tó máa ń wáyé nígbà tí kò bá sí èròjà protein nínú ara, èyí tí Àjọ Ìlera Àgbáyé pè ní “àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí táráyé ò kọbi ara sí.” Báwo ni ọ̀ràn ìbànújẹ́ yìí ti burú jáì tó? Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé ó “wà lára ohun tó ń ṣokùnfà, ó kéré tán, ìdajì nínú ikú àwọn ọmọdé tí iye wọn tó mílíọ̀nù mẹ́wàá ó lé ogún ọ̀kẹ́ lọ́dọọdún.”

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni àìjẹunrekánú pín sí. Bíi kí èèyàn máà rí àwọn èròjà aṣaralóore tó tó jẹ, ìyẹn irú àwọn èròjà bíi vitamin àti mineral. Ó sì lè jẹ́ sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ tàbí àwọn àìsàn bárakú mìíràn tó jẹ mọ́ ìṣòro oúnjẹ jíjẹ. Àmọ́, èyí tó jẹ mọ́ àìtó èròjà protein nínú ara “ni èyí tó léwu jù lọ nínú gbogbo oríṣi ìṣòro àìjẹunrekánú tó wà,” gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe sọ. Àwọn ọmọdé tí ò tíì tó ọmọ ọdún márùn-ún ló máa ń sábà kọ lù.

Ronú fún ìṣẹ́jú díẹ̀ ná nípa Erik, tá a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, àti nípa ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọdé tí àìjẹunrekánú ń yọ lẹ́nu. Àwọn kọ́ ló fa ipò tí wọ́n bá ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè jàjàbọ́ lọ́wọ́ ìṣòro náà. Georgina Toussaint, tó jẹ́ onímọ̀ nípa oúnjẹ aṣaralóore fún àwọn ọmọdé, sọ fún àwọn òǹṣèwé Jí! pé: “Àwọn tí ìṣòro yìí ń bá fínra kọ́ ló fọwọ́ ara wọn fà á, síbẹ̀ àwọn ni àìsàn yìí ń tètè kọ lù jù lọ.”

Àwọn kan lè rò pé ìṣòro yìí kò lè ní ojútùú rárá—pé kò sí oúnjẹ tó lè tó gbogbo èèyàn tó wà lágbàáyé jẹ. Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe sọ, “oúnjẹ pọ̀ yamùrá nínú ayé tá à ń gbé lónìí.” Oúnjẹ tó lè bọ́ gbogbo èèyàn wà lórí ilẹ̀ ayé wà—kódà á tún ṣẹ́ kù. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àìjẹunrekánú ló rọrùn jù lọ láti dènà, òun sì ni owó téèyàn máa fi wò ó sàn kéré jù lọ. Ǹjẹ́ ohun tó o gbọ́ yìí ò bà ọ́ nínú jẹ́?

Ta Ni Ìṣòro Náà Kàn?

Kì í ṣe àwọn ọmọdé nìkan ló ń ní ìṣòro àìjẹunrekánú. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé gbé jáde lóṣù July 2001 ti wí, “ìṣòro tó gbilẹ̀ ni àìjẹunrekánú, torí pé àwọn tó kàn ń lọ sí ẹgbẹ̀rin mílíọ̀nù èèyàn—ìyẹn jẹ́ ìdá márùn-ún gbogbo èèyàn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.” Èyí túmọ̀ sí pé, ìdá kan nínú mẹ́jọ gbogbo èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé ló ní ìṣòro yìí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Éṣíà ni àwọn èèyàn tí kò rí oúnjẹ aṣaralóore jẹ tó pọ̀ sí jù lọ—pàápàá ní àgbègbè gúúsù àti àárín gbùngbùn Éṣíà—àmọ́ ilẹ̀ Áfíríkà ni ìpín àwọn èèyàn tí kò rí oúnjẹ aṣaralóore jẹ ti pọ̀ jù lọ. Àwọn orílẹ̀-èdè kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ní Látìn Amẹ́ríkà àti àgbègbè Caribbean ni ìṣòro yìí ti tún pọ̀ lẹ́yìn àwọn tá a mẹ́nu kàn lókè.

Ǹjẹ́ àìjẹunrekánú yọ àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà sílẹ̀? Rárá o. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, The State of Food Insecurity in the World 2001 ti wí, mílíọ̀nù mọ́kànlá èèyàn tí kò rí oúnjẹ jẹ kánú ló wà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà. Láfikún sí i, mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n èèyàn tí kò rí oúnjẹ jẹ kánú ló wà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gòkè àgbà, pàápàá àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù àtàwọn orílẹ̀-èdè olómìnira ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́.

Kí nìdí tí àìjẹunrekánú fi wá di ìṣòro ńlá bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tó lè mú kí ipò àwọn tí kò rí oúnjẹ jẹ kánú sunwọ̀n sí i nísinsìnyí? Ǹjẹ́ àìjẹunrekánú lè kásẹ̀ ńlẹ̀ pátápátá lórí ilẹ̀ ayé? Àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gan-an.

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 4]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ TÍ ÀWỌN OLÙGBÉ WỌN NÍ ÌṢÒRO ÀÌTÓ OÚNJẸ AṢARALÓORE

ÀWỌN TÍ WỌN Ò FI BẸ́Ẹ̀ NÍ ÌṢÒRO

ÀWỌN TÍ ÌṢÒRO WỌN MỌ NÍWỌ̀N

ÀWỌN TÍ ÌṢÒRO WỌN PỌ̀

ÀWỌN TÍ KÒ NÍṢÒRO TÀBÍ TÍ ÌSỌFÚNNI NÍPA WỌN KÒ PÉ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Àwọn tó ń dúró de ìpèsè ìrànwọ́ nílẹ̀ Sudan

[Credit Line]

Fọ́tò UN/DPI tí Eskinder Debebe yà