Kò Sí Àṣírí Mọ́
Kò Sí Àṣírí Mọ́
“OHUN TÓ BÁ WU ÈÈYÀN LÓ LÈ ṢE LÁBẸ́ ÒRÙLÉ RẸ̀.”—WILLIAM PITT, ÒṢÈLÚ ỌMỌ ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ, 1759-1806.
OHUN tí ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Pitt túmọ̀ sí ni pé ó yẹ kí olúkúlùkù ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ohun tó bá wù ú ní ìkọ̀kọ̀. Ó lè mọ ògiri yí apá kan ìgbésí ayé rẹ̀ ká, kó máà jẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa tojú bọ ọ̀ràn òun láìnídìí.
Ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn látinú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fi ń wo ọ̀ràn àṣírí. Bí àpẹẹrẹ, ní àgbègbè Samoa tó wà lára àwọn erékùṣù Pàsífíìkì, wọn kì í mọ ògiri yí ilé wọn ká, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tí ìdílé kan bá ń ṣe nínú ilé làwọn èèyàn máa ń rí láti ìta gbangba. Síbẹ̀síbẹ̀, ìwà àfojúdi ni wọ́n kà á sí níbẹ̀ téèyàn bá wọnú ilé ẹnì kan láìjẹ́ pé wọ́n ké sí i.
Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti rí i pé ó yẹ kí kálukú lómìnira láti máa ṣe nǹkan rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí William Pitt tó sọ ọ̀rọ̀ tó gbajúmọ̀ yẹn ni Bíbélì ti fi hàn pé ó yẹ ká ṣọ́ra fún títojúbọ ọ̀ràn àṣírí àwọn ẹlòmíràn. Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ṣọ̀wọ́n ní ilé ọmọnìkejì rẹ, kí ọ̀ràn rẹ má bàa sú u, òun a sì kórìíra rẹ dájúdájú.” (Òwe 25:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ . . . fi í ṣe ìfojúsùn yín láti . . . [má ṣe] yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn.”—1 Tẹsalóníkà 4:11.
Ọ̀ràn pípa àṣírí ẹni mọ́ ṣe pàtàkì gan-an débi pé, ìwé ìròyìn The UNESCO Courier pè é ní “ìpìlẹ̀ pàtàkì fún ẹ̀tọ́ aráàlú.” Bákan náà, òṣèlú pàtàkì kan ní àgbègbè Látìn Amẹ́ríkà sọ pé: “Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, gbogbo ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn
ló so mọ́ pípa àṣírí ẹni mọ́.”Àmọ́ ṣá o, nínú ayé òde òní tí ìwà ọ̀daràn túbọ̀ ń peléke sí i tí ìwà ìpániláyà sì ti kárí ayé, àwọn ìjọba àtàwọn àjọ agbófinró ti túbọ̀ ń rí i pé kí àwọn tó lè dáàbò bo àwọn aráàlú àwọn, ó di dandan káwọn tojú bọ ọ̀ràn àṣírí wọn. Kí nìdí? Nítorí pé àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn tó wà láwùjọ máa ń lo àǹfààní pé kálukú lẹ́tọ̀ọ́ láti pa àṣírí rẹ̀ mọ́ bíi bojúbojú fún ìwà búburú. Nítorí náà, ó ṣòro láti mọ ààlà tó yẹ kó wà láàárín ojúṣe ìjọba láti dáàbò bo àwọn aráàlú àti ẹ̀tọ́ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ní láti pa àṣírí rẹ̀ mọ́.
Pípa Àṣírí Ẹni Mọ́ àti Ọ̀ràn Ààbò
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó wáyé látọwọ́ àwọn apániláyà ní September 11, 2001 ti yí ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn padà lórí ẹ̀tọ́ tí ìjọba ní láti máa tojú bọ díẹ̀ lára àṣírí àwọn aráàlú. Kọmíṣọ́nnà kan tẹ́lẹ̀ rí fún ètò ìṣòwò nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ fún ilé iṣẹ́ ìròyìn BusinessWeek pé: “Ìṣẹ̀lẹ̀ September 11 ti yí ọ̀pọ̀ nǹkan padà.” Ó fi kún un pé: “Ńṣe làwọn apániláyà ń rìn fàlàlà nínú àwùjọ kan tí kò sẹ́ni tó ń tojú bọ àṣírí wọn. Bó bá jẹ́ pé títojúbọ díẹ̀ lára àṣírí aráàlú ló máa tú wọn síta, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ pé ‘Ó ti dáa, ẹ máa báṣẹ́ lọ.’” Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn ìwádìí tí wọ́n ń ṣe láti September 11 láti mọ èrò àwọn aráàlú fi hàn pé ìdá mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Amẹ́ríkà ló fẹ́ kí ìjọba túbọ̀ máa lo àwọn ẹ̀rọ tó ń fi ojú ẹni hàn; ìdá mọ́kànlélọ́gọ́rin ló fẹ́ kí wọ́n túbọ̀ máa mójú tó ọ̀ràn ìfowópamọ́ àti lílo káàdì ìrajà àwìn; ìdá méjìdínláàádọ́rin ló fọwọ́ sí i pé kí olúkúlùkù ní káàdì ìdánimọ̀ ti orílẹ̀-èdè rẹ̀.”
Irú àwọn káàdì ìdánimọ̀ tí àwọn ìjọba tó wà láwọn orílẹ̀-èdè kan ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé ń ṣètò láti máa lò yóò ní òǹtẹ̀ ìka ọwọ́ àti àwòrán ẹyinjú ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú, yóò sì lè jẹ́ kí àwọn agbófinró mọ àkọsílẹ̀ gbogbo ìwà ọ̀daràn tí onítọ̀hún ti hù sẹ́yìn àti àkọsílẹ̀ tó ní nípa ọ̀ràn ìnáwó. Wọ́n tún lè lo ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ láti fi ìsọfúnni tó wà nínú káàdì ìdánimọ̀ ẹnì kan wéra pẹ̀lú ohun tó wà nínú káàdì ìrajà àwìn rẹ̀, kí wọ́n sì wá fi méjèèjì wéra pẹ̀lú ojú ẹni tí kámẹ́rà tó ń ṣọ́ni fi hàn. Nípa báyìí, wọ́n lè mú àwọn ọ̀daràn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ra àwọn ohun èlò tí wọ́n fẹ́ lò fún iṣẹ́ ibi wọn tán.
Bí àwọn ọ̀daràn bá gbìyànjú láti fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ nípa títọ́jú bọ́ǹbù, ìbọn tàbí ọ̀bẹ sábẹ́ aṣọ, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ sá pa mọ́ sẹ́yìn ògiri ilé pàápàá, ọwọ́ ṣì lè tó wọn. Àwọn àjọ aláàbò kan ní àwọn ohun èlò tó lè fi ohunkóhun tó wà lábẹ́ aṣọ hàn. Àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣàyẹ̀wò nǹkan tó wà lọ́nà jíjìn, èyí táwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde, lè jẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá mọ àwọn ẹni tó ń rìn-lọ rìn-bọ̀ nínú iyàrá kejì sí wọn, tàbí bí wọ́n ṣe ń mí pàápàá. Àmọ́, ǹjẹ́ mímú kí àwọn ohun tí wọ́n fi ń ṣọ́ni túbọ̀ lágbára sọ pé kí ìwà ọ̀daràn lọ sílẹ̀?
Ǹjẹ́ Kámẹ́rà Dí Àwọn Ọ̀daràn Lọ́wọ́?
Nígbà tí ìwà ọ̀daràn bẹ̀rẹ̀ sí peléke ní ìlú Bourke, tó jẹ́ àgbègbè ìgbèríko kan lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, wọ́n gbé àwọn kámẹ́rà mẹ́rin tó ń yàwòrán ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo sáwọn ibì kan nínú ìlú náà. Àbájáde èyí ni pé ìwà ọ̀daràn lọ sílẹ̀ gan-an. Àmọ́ kì í ṣe ibi gbogbo ni irú àṣeyọrí yìí ti ń wáyé o. Nígbà táwọn aláṣẹ ń gbìyànjú láti dín ìwà ọ̀daràn kù ní ìlú Glasgow nílẹ̀ Scotland, wọ́n gbé irú àwọn kámẹ́rà wọ̀nyí tí iye wọn jẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n sáwọn ibì kan káàkiri ìlú náà lọ́dún 1994. Ìwádìí kan tí Ẹ̀ka Tó Ń Ṣèwádìí fún Ìjọba Àpapọ̀ Ilẹ̀ Scotland ṣe fi hàn pé lọ́dún tó tẹ̀ lé ọdún tí wọ́n gbé àwọn kámẹ́rà sáwọn ibì kan káàkiri ìlú náà, iye àwọn ìwà ọ̀daràn pàtó kan dín kù. Àmọ́, ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn ìwà tí kò bójú mu, títí kan iṣẹ́ aṣẹ́wó, lọ sókè ní nǹkan bí ìlọ́po méjì; ìwà àìṣòótọ́
lọ sókè ní nǹkan bí ìlọ́po okòólérúgba; ìwà ìrúfin ní ọ̀kan-ò-jọ̀kan (títí kan ìwà ìrúfin tó jẹ mọ́ oògùn olóró) lọ sókè ní nǹkan bí ìlọ́po márùn-ún.”Kódà bí fífi kámẹ́rà ṣọ́ni bá dín ìwà ọ̀daràn kù láwọn àgbègbè kan, ó lè máà dín gbogbo ìwà ọ̀daràn kù káàkiri ìlú. Ìwé ìròyìn The Sydney Morning Herald sọ̀rọ̀ lórí àṣà kan tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn arúfin, èyí táwọn ọlọ́pàá àtàwọn onímọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn ń pè ní “ṣíṣí kiri.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Nígbà táwọn ọ̀daràn bá rí i pé ọwọ́ lè tẹ àwọn nípasẹ̀ kámẹ́rà tàbí àwọn ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ àgbègbè kan pàtó, wọ́n á ṣí lọ sí àgbègbè mìíràn láti lọ hùwà ọ̀daràn.” Bóyá èyí lè jẹ́ kó o rántí ohun kan tí Bíbélì ti sọ nígbà pípẹ́ sẹ́yìn pé: “Ẹni tí ó bá ń fi ohun búburú ṣe ìwà hù kórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sínú ìmọ́lẹ̀, kí a má bàa fi ìbáwí tọ́ iṣẹ́ rẹ̀ sọ́nà.”—Jòhánù 3:20.
Ìṣòro tó ń dojú kọ àwọn àjọ
agbófinró ni pé, kódà àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣọ́ni tó lágbára jù lọ pàápàá kò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹnì kan tàbí ohun téèyàn ń rò lágbárí, síbẹ̀ inú ọkàn ni èèyàn ti gbọ́dọ̀ ja ìjà gidi láti dín ìwà ọ̀daràn, ìkórìíra, àti ìwà ipá kù.Àmọ́ o, ohun kan wà tó ń ṣọ́ni ju ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ èyíkéyìí tí ẹ̀dá èèyàn tíì ṣe rí lọ, èyí tí kò sí ibi kankan tí kò rí. Ohun tí nǹkan yìí jẹ́ àti ipa rere tó lè ní lórí ìwà àwa ẹ̀dá èèyàn ni a óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 18]
“Ńṣe làwọn apániláyà ń rìn fàlàlà nínú àwùjọ kan tí kò sẹ́ni tó ń tojú bọ àṣírí wọn”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Báwo Ni Àkọsílẹ̀ Dókítà Nípa Ìlera Rẹ Ṣe Pa Mọ́ tó?
Ọ̀pọ̀ èèyàn lè máa rò pé àkọsílẹ̀ dókítà nípa ìlera wọn—ìyẹn gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni nípa ìlera wọn tó wà lọ́wọ́ dókítà àti nílé ìwòsàn—ló dájú pé wọ́n ń bá àwọn pa mọ́ láṣìírí. Àmọ́ ṣá o, àjọ kan tó ń mójú tó àwọn ìsọfúnni tó jẹ́ àṣírí, ìyẹn àjọ Privacy Rights Clearinghouse kìlọ̀ pé, “àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ibi tó o fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀.” Nínú ìwé Database Nation—The Death of Privacy in the 21st Century tí Simson Garfinkel kọ, ó sọ pé: “Lóde òní, àwọn èèyàn ti ń lo àwọn àkọsílẹ̀ nípa ìlera ju ti tẹ́lẹ̀ lọ . . . Àwọn agbanisíṣẹ́ àtàwọn ilé iṣẹ́ abánigbófò máa ń lò ó láti fi pinnu ẹni tí wọ́n lè gbà síṣẹ́ tàbí ẹni tí wọ́n lè gbà sínú ètò ìbánigbófò. Àwọn ilé ìwòsàn àtàwọn ètò ẹ̀sìn kan máa ń lò ó láti fi bẹ̀bẹ̀ fún ọrẹ àánú. Kódà, àwọn oníṣòwò ńláńlá máa ń ra ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé àkọsílẹ̀ nípa ìlera láti fi wá ìsọfúnni tó máa wúlò fún wọn láti lè rí àwọn oníbàárà púpọ̀ sí i.”
Garfinkel tún sọ pé: “Ohun tó wá mú kí ọ̀ràn pípa ìsọfúnni mọ́ láṣìírí yìí túbọ̀ burú sí i ni pé, àwọn èèyàn tí iye wọn tó àádọ́ta sí márùndínlọ́gọ́rin ló pọn dandan pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ aláìsàn kan tó bá lọ sí ilé ìwòsàn.” Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn aláìsàn lè fọwọ́ sáwọn ìwé kan láìfura nígbà tí wọ́n bá ń gbà wọ́n sílé ìwòsàn. Àwọn fọ́ọ̀mù tí àlàyé inú wọn kò ṣe kedere yìí ń fi hàn pé gbogbo ohun tí ilé ìwòsàn náà bá ṣe ni aláìsàn náà fara mọ́. Àjọ Privacy Rights Clearinghouse sọ pé béèyàn bá fọwọ́ sí irú àwọn fọ́ọ̀mù bẹ́ẹ̀, “onítọ̀hún ti fún àwọn olùtọ́jú rẹ̀ láǹfààní láti sọ àwọn ìsọfúnni nípa ìtọ́jú rẹ̀ fún àwọn ilé iṣẹ́ abánigbófò, àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba, àtàwọn ẹlòmíràn.”
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ọ̀ràn Àṣírí Àti Iṣẹ́ Ajé
Ó rọrùn gan-an fún àwọn ẹlòmíràn láti tojú bọ ọ̀ràn àṣírí àwọn tó máa ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àjọ Privacy Rights Clearinghouse sọ pé: “Kò sí ìgbòkègbodò orí kọ̀ǹpútà tàbí ètò ìbánisọ̀rọ̀ èyíkéyìí téèyàn lè lò pẹ̀lú ìdánilójú pé gbogbo àṣírí òun ló pa mọ́. . . . Àwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lè mú àwọn ìsọfúnni kan tàbí àwọn àkọsílẹ̀ mìíràn látinú ibi ìkósọfúnnisí orí Íńtánẹ́ẹ̀tì . . . , tàbí kí àwọn tó ń lò ó kàn ‘wo’ àwọn nǹkan wọ̀nyí láìsí pé wọ́n ń mú ìsọfúnni èyíkéyìí níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń rò pé kò sí ẹnikẹ́ni tó lè mọ̀ pé àwọ́n wo àwọn ìsọfúnni náà. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ o. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ọ̀pọ̀ ohun tí ẹnì kan bá ṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, irú bíi wíwo àwọn ibi tí ìròyìn máa ń wà tàbí wíwo àwọn ibi tí ìsọfúnni máa ń wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. . . . Àwọn àkọsílẹ̀ nípa ‘bí ẹnì kan ṣe máa ń ṣàyẹ̀wò ìsọfúnni‘ . . . máa ń mú owó tabua wọlé fún àwọn oníṣòwò . . . Ìsọfúnni yìí lè ran àwọn òǹtajà lọ́wọ́ láti mọ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, tí wọ́n jọ máa ń yẹ irú ìsọfúnni kan náà wò, tí wọ́n á sì fẹ́ láti ra irú ọjà kan náà.”
Àwọn ọ̀nà mìíràn wo ni orúkọ rẹ lè gbà wọ inú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ tí wọ́n fi ń kó ọjà ránṣẹ́ síni? Wọ́n lè fi orúkọ rẹ kún àkọsílẹ̀ wọn nígbà tó o bá ṣe ọ̀kan lára àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí:
◼ Tó o bá kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tí iléeṣẹ́ pèsè láti fi hàn pé ọjà tó o rà dára.
◼ Tó o bá dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan, àjọ kan tàbí ètò àánú kan, tàbí tó o fi owó ṣètìlẹyìn fún wọn.
◼ Tó o bá sanwó àsansílẹ̀ láti máa gba ìwé ìròyìn kan, tàbí tó o forúkọ sílẹ̀ láti máa gba ìwé tàbí àwo orin látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ kan.
◼ Tó o bá fi orúkọ rẹ àti àdírẹ́sì rẹ sílẹ̀ nínú ìwé tẹlifóònù.
◼ Tó o bá forúkọ sílẹ̀ láti kópa nínú tẹ́tẹ́ lọ́tìrì tàbí àwọn ìdíje mìíràn.
Láfikún sí i, tó o bá lo káàdì ìrajà àwìn tàbí káàdì tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé sọ̀wédowó láti fi sanwó àwọn ohun tó o rà, èyí á mú kí ilé iṣẹ́ náà lè fi orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ mọ àwọn ọjà tó o rà, bí ẹ̀rọ tó ń ṣírò iye owó ọjà ṣe ń ṣírò owó rẹ. Wọ́n wá lè lo èyí láti fi ṣàkójọ ìsọfúnni nípa bó o ṣe ń rajà tó, wọ́n sì lè lò ó fún ète ọjà títà tiwọn lọ́jọ́ iwájú. a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ṣàkójọ ìsọfúnni yìí látinú ibi ìkósọfúnnisí orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó jẹ́ ti Àjọ Privacy Rights Clearinghouse.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
Ǹjẹ́ fífi kámẹ́rà ṣọ́ni lè dín ìwà ọ̀daràn kù?