Fífi Àwọn Ọmọdé Ṣèfà Jẹ Máa Dópin Láìpẹ́!
Fífi Àwọn Ọmọdé Ṣèfà Jẹ Máa Dópin Láìpẹ́!
“NÍNÚ Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé, Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé àwọn ọmọdé lẹ́tọ̀ọ́ sí àbójútó pàtàkì àti àkànṣe ìrànwọ́” ni ohun tí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ fún Àdéhùn Nípa Ẹ̀tọ́ Ọmọdé sọ. Lórí bí ìdílé ṣe ṣe pàtàkì tó, ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà fi kún un pé: “Kí ọmọdé kan tó lè dàgbà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, kó sì tún ní ìwà àti ìṣesí tó dára, ó gbọ́dọ̀ dàgbà nínú ìdílé kan tí ayọ̀ àti ìfẹ́ wà, tí wọ́n sì ń fi òye bá a lò.” Àmọ́ o, ìrètí yìí ṣì jìnnà fíìfíì sí ohun tí ọwọ́ lè tẹ̀.
Ká kàn máa fẹnu lásán sọ pé a fẹ́ kí ayé àwọn ọmọdé dára sí i kò tó. Ńṣe ni ìwà ìbàjẹ́ túbọ̀ ń gogò sí i, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò fi bẹ́ẹ̀ kà á sí. Apá àwọn agbófinró kò ká bí ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ojúkòkòrò ṣe ń ràn bí iná ọyẹ́. Èyí táwọn òbí gan-an ń ṣe níbẹ̀ kò kéré, torí pé dípò kí wọ́n máa fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì máa dáàbò bò wọ́n, ńṣe ni wọ́n máa ń gbà wọ́n láyè láti ṣe ohun tó bá wù wọ́n. Ìrètí wo la wá ní báyìí o fún fífi òpin sí iṣẹ́ aṣẹ́wó tí àwọn ọmọdé ń ṣe?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé tá à ń gbénú rẹ̀ yìí ti kùnà láti rí sí i pé gbogbo ọmọdé ló ní ìdílé onífẹ̀ẹ́ àti ọjọ́ ọ̀la tó fọkàn wọn balẹ̀, Ẹlẹ́dàá wa yóò mú gbogbo onírúurú ìwà pálapàla kúrò láìpẹ́, títí kan iṣẹ́ aṣẹ́wó tí àwọn ọmọdé ń ṣe. Láìpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run yóò dá sí ọ̀ràn àwa ẹ̀dá èèyàn nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀, ìyàlẹ́nu sì lèyí máa jẹ́ fún aráyé. Àwọn tó ń ba ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn jẹ́ àtàwọn tó ń fi àwọn Òwe 2:21, 22.
ẹlòmíràn ṣèfà jẹ kò lè bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. Kìkì àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn nìkan ló máa là á já, tí wọn yóò sì máa gbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”—Fojú inú wo irú ìtura tó máa dé nígbà tí àwọn ọmọdé àtàwọn àgbàlagbà á máa gbé láìsí pé àwọn kan ń ṣe wọ́n níṣekúṣe tàbí pé wọ́n ń fi ìbálòpọ̀ fìtínà wọn! Kódà, ọgbẹ́ ọkàn àti ti ara tí wọ́n ti ní látàrí bí wọ́n ti ṣe fi wọ́n ṣèfà jẹ tí wọ́n sì hu ìwà ìkà sí wọn yóò di ohun ìgbàgbé. Yóò ṣeé ṣe fún àwọn tí wọ́n ti fi ṣèfà jẹ nípa bíbá wọn lò pọ̀ láti máa gbé láìsí ìrora ọkàn ti rírántí ìwà àìdáa tí wọ́n ti hù sí wọn. “Àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò . . . mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.”—Aísáyà 65:17.
Nígbà yẹn, kò ní sí ọmọ kankan tí wọn yóò bí fún ìyà jẹ tàbí kí wọ́n máa fi ìbálòpọ̀ fìtínà rẹ̀. Ayọ̀, ìfẹ́, àti fífi òye báni lò kò tún ní jẹ́ àlá tí kò lè ṣẹ mọ́. Aísáyà 11:9 polongo nípa àwọn èèyàn tí yóò máa gbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí.”
Àní sẹ́, ayọ̀ ńlá ni yóò mà jẹ́ o, nígbà tí àìríná-àìrílò, lílo oògùn olóró, àwọn ìdílé aláìláyọ̀, àti ìwà ìbàjẹ́ kò bá sí mọ́! Àlàáfíà, òdodo, àti ìfọ̀kànbalẹ̀ yóò gbayé kan. “Àwọn ènìyàn mi yóò . . . máa gbé ní ibi gbígbé tí ó kún fún àlàáfíà àti ní àwọn ibùgbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé àti ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ní ìyọlẹ́nu.”—Aísáyà 32:18.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Báwọn Òbí Bá Bìkítà fún Àwọn Ọmọ, Ìdílé Á Dúró Sán-ún
● “Àwọn òbí mi rọ̀ mí pé kí n lo àkókò tí mo fi wà níléèwé láti rí i pé mo mọ iṣẹ́ kan dunjú. Wọn ò fi tipátipá mú mi láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, àmọ́ wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti yan àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni ní àwọn iṣẹ́ tí mo nílò.”—Tais.
● “Nígbà tí èmi àti àbúrò mi obìnrin bá ń lọ ra nǹkan lọ́jà, màmá wa máa ń bá wa lọ. Yàtọ̀ sí pé ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣọ́ owó ná, ó tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe ra àwọn aṣọ ṣekárími tàbí tó ń fi ara sílẹ̀.”—Bianca.
● “Nígbà tá a bá ń lọ sí àpèjẹ, ìgbà gbogbo làwọn òbí wa máa ń béèrè nípa àwọn tó máa wá síbẹ̀, irú àwọn orin tí wọ́n máa lò níbẹ̀, àti ìgbà tí àpèjẹ náà máa bẹ̀rẹ̀ àtìgbà tó máa parí. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àpèjẹ tá a máa ń lọ ló jẹ́ pé gbogbo ìdílé wa lápapọ̀ ló máa ń wà níbẹ̀.”—Priscila.
● “Nígbà tí mo wà ní kékeré àti ìgbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́langba, èmi àtàwọn òbí mi jọ máa ń sọ̀rọ̀ gan-an. Ọmọ iléèwé mi kan kíyè sí èyí ó sì sọ pé: ‘Mo jowú rẹ o, fún bó o ṣe ń lè bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa ohunkóhun pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Àní ń kì í lè bá màmá mi pàápàá sọ̀rọ̀ fàlàlà, ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn ni mo sì máa ń lọ lọ́pọ̀ ìgbà tí mo bá fẹ́ mọ ohun kan.’”—Samara.
● “Nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́langba, mo láyọ̀ gan-an. N kì í rí ohun kankan tí kò dára nípa àwọn èèyàn, ńṣe ni mo sì máa ń rẹ́rìn-ín ṣáá. Èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi mọwọ́ ara wa gan-an mo sì máa ń gbádùn kí n máa sọ ohun tó máa pa wọ́n lẹ́rìn-ín fún wọn. Àwọn òbí mi lóye pé irú ẹ̀dá tí mo jẹ́ nìyẹn, wọn ò sì gbìyànjú láti mú mi yí ànímọ́ mi padà. Àmọ́ wọ́n fi tìfẹ́tìfẹ́ ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé mo gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, àti pé ó yẹ kí n máa hùwà lọ́nà tó bójú mu nínú àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin.”—Tais.
● “Gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀dọ́, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí fà sí àwọn ẹ̀yà òdìkejì. Bàbá mi sọ iye ọdún pàtó tí mo lè bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́sọ́nà. Èyí kò bà mí nínú jẹ́ rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo rí i pé àwọn òbí mi bìkítà nípa mi ni, àti pé wọ́n fẹ́ dáàbò bò mí lọ́wọ́ ìṣòro ọjọ́ iwájú.”—Bianca.
● “Mo rí ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ohun tó dára, ní pàtàkì nítorí àpẹẹrẹ àwọn òbí mi. Àárín wọn gún, wọ́n sì jọ máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ dáadáa. Mo rántí pé, nígbà tí èmi àti ọkọ mi ń fẹ́ra wa sọ́nà, màmá mi fún mi ní ìmọ̀ràn nípa ọ̀nà tí mo lè gbà hùwà lábẹ́ àwọn ipò kan ó sì ṣàlàyé bí èyí ṣe máa nípa lórí ìgbéyàwó mi.”—Priscila.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, kò sí ọmọ kankan tí a óò máa ṣe níṣekúṣe