Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn wọn sì wà ní ojú ìwé 31. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)
1. Lẹ́yìn tí Ọba Jèhóṣáfátì ti fìdí ètò ìdájọ́ tó dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ múlẹ̀, àṣẹ wo ló pa fún àwọn onídàájọ́ náà níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ni wọ́n ń ṣojú fún tí kì í ṣe èèyàn? (2 Kíróníkà 19:7)
2. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀run ni àwọn ọba àti àlùfáà tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi nígbà Ẹgbẹ̀rúndún Ìṣàkóso rẹ̀ máa wà, àwọn wo ni yóò wá máa ṣojú fún un lórí ilẹ̀ ayé tí wọn yóò sì máa rí sí i pé àwọn èèyàn ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀? (Sáàmù 45:16)
3. Láti àgbègbè wo ni gbogbo àwọn àpọ́sítélì Jésù mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ti wá? (Lúùkù 4:14)
4. Kí ni Jóṣúà bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọ́run ṣe nítorí ti àwọn ará Gíbéónì táwọn ọ̀tá sàga tì, kó bàa lè ṣeé ṣe láti ṣẹ́gun àwọn ará Ámórì? (Jóṣúà 10:12, 13)
5. Àwọn orúkọ wo la pe Òkun Òkú nínú Bíbélì? (Diutarónómì 3:17)
6. Kí nìdí tí Hámánì fi dìtẹ̀ láti pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní Ilẹ̀ Ọba Páṣíà run? (Ẹ́sítérì 3:5, 6, 10)
7. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Rábúṣákè, tí í ṣe agbẹnusọ Senakéríbù, sọ láti mú kí Hesekáyà juwọ́ sílẹ̀ láìjanpata? (2 Ọba 18:33-35)
8. Àwọn wòlíì méjì wo ló gbajúmọ̀ lákòókò tí Dáfídì ń ṣàkóso? (2 Sámúẹ́lì 12:1; 24:11)
9. Kí ni Ọlọ́run dá ní ọjọ́ ìṣẹ̀dá kejì? (Jẹ́nẹ́sísì 1:7)
10. Ibo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nígbà tí Jóṣúà rán àwọn amí méjì lọ sí Jẹ́ríkò? (Jóṣúà 2:1)
11. Kí làwọn èròjà tí wọ́n fi ṣe “òróró mímọ́ àfiyanni”? (Ẹ́kísódù 30:23-25)
12. Àwọn ẹ̀bùn wo ni Bẹliṣásárì sọ pé òún máa fún ẹni tó bá lè túmọ̀ ìkọ̀wé tí wọ́n fọwọ́ kọ sára ògiri? (Dáníẹ́lì 5:7)
13. Kòkòrò wo ní Bíbélì sọ pé ó jẹ́ òṣìṣẹ́ gidi àti pé ó ní ọgbọ́n àtinúdá? (Òwe 6:6)
14. Ọba ilẹ̀ Júdà wo ló dojú kọ ẹgbẹ́ ogun àwọn ará Etiópíà tó jẹ́ mílíọ̀nù kan jagunjagun? (2 Kíróníkà 14:9, 10)
15. Ẹranko tó ń padà sídìí èébì rẹ̀ wo la fi arìndìn èèyàn tó tún padà lọ hu ìwà òpònú tó ti hù lẹ́ẹ̀kan rí wé? (Òwe 26:11)
16. Àwọn odò méjì tó wà ní Damásíkù wo ni Náámánì sọ pé ó sàn ju “gbogbo omi Ísírẹ́lì” lọ? (2 Àwọn Ọba 5:12)
17. Ẹ̀sùn wo ni wọ́n fi kan Jésù nítorí tí ó sọ pé òún máa lọ sílé Sákéù tó jẹ́ agbowó orí? (Lúùkù 19:7)
18. Àwọn ará Asíríà mélòó ni áńgẹ́lì kan ṣoṣo pa lóru ọjọ́ kan? (2 Àwọn Ọba 19:35)
19. Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ti sọ, ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà fìyà jẹ “àwọn áńgẹ́lì tí ó ṣẹ̀”? (2 Pétérù 2:4)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. “Ẹ kíyè sára, kí ẹ sì gbé ìgbésẹ̀, nítorí pé kò sí àìṣòdodo tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa”
2. Àwọn olórí
3. Gálílì
4. Pé kí oòrùn àti òṣùpá dúró pa sójú kan
5. “Òkun Árábà, Òkun Iyọ̀”
6. Níwọ̀n bí a ti pe Hámánì ní “ọmọ Ágágì,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn ọmọ Ámálékì—àwọn èèyàn tí Ọlọ́run ti dẹ́bi ìparun yán-ányán-án fún nítorí ìkórìíra tí wọ́n ní fún àwọn Júù
7. Ó sọ pé Jèhófà kò lè gba Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ bí àwọn ọlọ́run àwọn ìlú tí àwọ́n ti ṣẹ́gun kò ṣe lè gbá wọ́n sílẹ̀
8. Nátánì àti Gáàdì
9. “Òfuurufú”
10. Wọ́n wà ní Ṣítímù, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù
11. Òjíá, sínámónì dídùn, ewéko kálámọ́sì dídùn, kaṣíà, àti òróró ólífì
12. Aṣọ aláwọ̀ àlùkò, ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí ó jẹ́ wúrà, àti ipò igbá-kẹta nínú ìjọba rẹ̀
13. Èèrà
14. Ọba Ásà
15. Ajá
16. “Ábánà àti Fápárì”
17. “Ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó lọ wọ̀ sí”
18. Ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000]
19. Nípa sísọ wọ́n sínú Tátárọ́sì