Eré Ìdárayá Àwọn Èwe—Ìwà Ipá Tuntun Tó Ń tàn Kálẹ̀
Eré Ìdárayá Àwọn Èwe—Ìwà Ipá Tuntun Tó Ń tàn Kálẹ̀
◼ Àwùjọ àwọn ọmọ ilé ìwé gíga kan pàdé pọ̀ láti jọ gbá bọ́ọ̀lù aláfọwọ́gbá, àmọ́ ìjà ni wọ́n fi kẹ́yìn eré ọ̀hún. Ńṣe ni àwọn òbí, àwọn kóòṣì, àtàwọn eléré ìdárayá náà, tí gbogbo wọ́n lé ní ọgọ́rùn-ún ń pariwo gèè tí wọ́n sì ń ju ẹ̀ṣẹ́ síra wọn nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà borí ìdíje náà láàárín àfikún àkókò tí wọ́n fún wọn.
◼ Àwùjọ àwọn èwe kan tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá jọ ń gbá bọ́ọ̀lù aláfọwọ́gbá tó wà fún ọkùnrin àtobìnrin. Nígbà tí ọmọ ọlọ́dún mẹ́wàá kan sọ bọ́ọ̀lù tí ẹlòmíràn jù sí i sílẹ̀, ńṣe ni kóòṣì gbé ọmọ náà, tó sọ ọ́ mọ́lẹ̀, tó sì dá a lápá méjèèjì.
◼ Kóòṣì ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù baseball kan tó jẹ́ ti àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ yọ ọ̀kan lára àwọn ọmọ tó ń kópa nínú eré ìdárayá náà kúrò. Ní bàbá ọmọdékùnrin náà bá ń lérí sí kóòṣì náà pé pípa lòún máa pà á, ńṣe ni wọ́n sì ju bàbá náà sẹ́wọ̀n ọjọ́ márùnlélógójì.
◼ Nígbà ìdánrawò eré bọ́ọ̀lù orí yìnyín àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ kan, awuyewuye wáyé láàárín àwọn bàbá méjì fún bí wọ́n ṣe lo àwọn òfin eré náà. Bàbá kan sì lu èkejì pa fin-ín-fin-ín lójú àwọn ọmọ onítọ̀hún mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
IRÚ àwọn ìròyìn tó ń dáyà jáni báyìí ti wá di èyí tó wọ́pọ̀ gan-an. Ó dà bíi pé oríṣi ìwà ipá tuntun kan ti ń tàn kálẹ̀ báyìí láwọn pápá ìṣeré, láwọn ibi tí wọ́n ti ń gbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀, láwọn ibi tí wọ́n ti ń gbá bọ́ọ̀lù orí yìnyín àti láwọn ibi
ìṣeré. Ìwà ipá táwọn òbí àtàwọn kóòṣì ń hù, tó jẹ́ pé wọ́n múra tán láti jà ju kí wọ́n gbà pé ọmọ fìdí rẹmi lọ. Jeffrey Leslie, ààrẹ Ẹgbẹ́ Àwọn Eléré Ìdárayá ti Jupiter-Tequesta (Florida), sọ pé: “Mo ti rí àwọn òbí tó ń kígbe mọ́ àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n á máa sọ fún wọn kíkankíkan pé wọ́n gbọ́dọ̀ rí i pé àwọ́n rọ́wọ́ mú; mo ti rí àwọn ọmọdé tí wọ́n ń gbá àwọn ọmọ mìíràn lẹ́ṣẹ̀ẹ́ nínú eré, tó jẹ́ pé àwọn òbí wọn ló ń tì wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀; mo sì ti rí àwọn ọmọ tí wọ́n ń sunkún lórí pápá ìṣeré nítorí pé àwọn òbí wọn dójú tì . . . wọ́n.” Jeffrey fi kún un pé: “Kò sí ibòmíràn tí ìwàkiwà àwọn òbí ti ń fara hàn gbangba-gbàǹgbà tó ibi eré ìdárayá àwọn èwe.” Láti dáàbò bo àwọn èwe lọ́wọ́ irú ìwà ipá bẹ́ẹ̀, láwọn àgbègbè kan, wọ́n ní láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó lágbára nípa fífòfinde àwọn òbí kan pé wọn ò gbọ́dọ̀ wá síbi eré ìdárayá àwọn ọmọ wọn.Kí ló ti jẹ́ àbájáde ìbínú òdì tó ń tàn kálẹ̀ yìí? Fred Engh, olùdásílẹ̀ àti ààrẹ Àjọ Eléré Ìdárayá Àwọn Èwe ti Ìjọba Àpapọ̀, èyí tó fìdí kalẹ̀ sílùú Florida, sọ pé: “Àwọn ìwà tí ń kótìjú báni táwọn àgbàlagbà tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ń hù yìí ti ń sọ eré ìdárayá àwọn ọ̀dọ́ dìdàkudà, ó ń ba ìgbádùn tó wà nínú rẹ̀ jẹ́, ó sì ń jẹ́ kí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èwe máa rò pé ohun tó bójú mu ni láti máa hu ìwà jàgídíjàgan.”
Kò Sóhun Tí Wọn Ò Lè Ṣe Láti Borí Lọ́nàkọnà
Ohun tó jọ pé ó jẹ́ gbòǹgbò ìṣòro yìí ni pé, àwọn òbí máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé àwọn ọmọ wọn ló máa ta gbogbo àwọn ọmọ tó kù yọ kí wọ́n sì borí lọ́nàkọnà. Aṣojú kan fún Àjọ Tó Ń Dènà Ṣíṣe Àwọn Ọmọdé Níṣekúṣe, èyí tó wà ní orílẹ̀-èdè Kánádà, sọ pé: “Nígbà tí bíborí bá di ohun tó ṣe kókó jù lọ, tó jẹ́ pé ẹni tó bá lágbára jù sì ni ẹni tó ṣe pàtàkì jù, èyí máa ń jẹ́ kí ìyà jẹ àwọn tí kò bá lágbára. Nínú àwọn eré ìdárayá wọ̀nyí, àwọn ọmọdé làwọn tí ìyà máa ń jẹ.” Ọ̀gá kan nínú Ẹgbẹ́ Tó Ń Bójú Tó Ẹ̀kọ́ Nípa Ìlera àti Eré Ìdárayá ní Ontario (Kánádà) sọ pé, àwọn ọmọ tí wọ́n bá ń fúngun mọ́ pé wọ́n ní láti borí ní dandan “lè ti kékeré di ẹni tó ń ní ìdààmú ọkàn. Nígbà tí wọ́n bá sì dàgbà, kíkojú ìjákulẹ̀ [lè] máà rọrùn fún wọn.”
Abájọ tó fi jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà, irú ìbínú táwọn òbí ń fi hàn yìí àti ìtara òdì táwọn kóòṣì máa ń ní máa ń fara hàn lára àwọn ọ̀dọ́ tó ń kópa nínú àwọn eré ìdárayá náà. Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin kan ń gbá bọ́ọ̀lù volley, ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn tó ń kópa dojú ìjà kọ kóòṣì. Ọmọbìnrin kan lọ ba ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ọ̀gá kan jẹ́ nítorí pé wọ́n lé e jáde nínú eré ìdárayá tẹníìsì kan. Nígbà tí wọ́n fun fèrè pé ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ṣòjóró nínú eré ìjàkadì kan, ńṣe ló lọ sẹ orí rẹ̀ mọ́ orí rẹfirí kan, tí ìyẹn sì dákú lọ rangbandan. Darrell Burnett, tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú àwọn ọmọdé àti olùgbaninímọ̀ràn lórí eré ìdárayá àwọn èwe, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, eré ìdárayá àwọn ọ̀dọ́ [ló ti fìgbà kan rí] jẹ́ èyí tí kì í ní ìjàngbọ̀n nínú rárá. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́ o. Kì í tún ṣe eré lásán tó wà fún ìgbádùn àwọn ọ̀dọ́ mọ́.”
Ohun Tí Àwọn Òbí Lè Ṣe
Ó dára kí àwọn òbí máa rántí pé ayọ̀ tí àwọn ọmọ ń rí nínú eré ìdárayá àti bó ṣe máa ń mú ara wọn le ló ń mú kí wọ́n máa gbádùn rẹ̀. Tí eré ìdárayá àwọn èwe bá wá di ohun tó ń kó másùnmáwo bá wọn, tó sì jẹ́ pé èébú àti àbùkù ni wọ́n ń gbà nídìí ẹ̀, á jẹ́ pé eré ìdárayá náà ti di nǹkan mìíràn nìyẹn, èyí kò sì fi ìfẹ́ hàn. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe ṣe ohun tó máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ yín sí wọn láé.”—Éfésù 6:4, The Jerusalem Bible.
Kí ló lè ran òbí kan lọ́wọ́ láti lo ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ọ̀ràn yìí? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, rírántí ìgbà tí ìwọ náà jẹ́ èwe lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Ṣé òótọ́ lo máa ń ta gbogbo àwọn ẹgbẹ́ rẹ yọ nínú eré ìdárayá? Ǹjẹ́ ó wá bọ́gbọ́n mu nígbà náà kó o máa retí pé kí ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ obìnrin ṣe bẹ́ẹ̀? Ó ṣe tán, “àwọn ọmọ jẹ́ ẹlẹgẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 33:13) Bákan náà, gbìyànjú láti ní èrò tó tọ́ nípa bíborí àti fífìdírẹmi. Bíbélì pe ìbára-ẹni-díje láìníjàánu ní “asán . . . àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 4:4.
Ìdí rèé tí ẹnì kan tó ti wà nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù baseball nígbà kan rí fi rọ àwọn òbí láti má ṣe máa wo bíborí àti fífìdírẹmi bí ohun bàbàrà. Bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí wọ́n máa bínú nígbà tí ọmọ wọn kò bá ṣe dáadáa tàbí kí inú wọn máa dùn kọjá ààlà nígbà tó bá gbégbá orókè. Dípò tí wọ́n á fi máa ka bíborí sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìgbádùn táwọn ọmọ ń rí nínú eré ìdárayá àti bó ṣe ń mú ara wọn jí pépé ló yẹ kí àwọn òbí máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo.
Èyí ló mú kí àwọn òbí kan parí èrò pé, ìbára-ẹni-díje tí kò tọ́ ni eré ìdárayá ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń yọrí sí. Èyí kò wá túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ wọn kì í bá àwọn ọmọ mìíràn ṣe 1 Tímótì 4:8) Nípa níní ojú ìwòye tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì yìí nípa eré ìdárayá, wàá lè gba ọmọ rẹ lọ́wọ́ àwọn ewu tó wà nínú ìwà ipá tuntun tó ń tàn kálẹ̀ yìí.
eré ìdárayá pọ̀ o. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ti rí i pé àwọn ọmọ wọn máa ń gbádùn bíbá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ṣe eré ìdárayá pọ̀ lẹ́yìnkùlé ilé wọn tàbí ní pápá ìṣeré kan ládùúgbò wọn. Lọ́nà yìí, ó túbọ̀ máa ń ṣeé ṣe fún àwọn òbí láti lè ṣàkóso irú àwọn ẹni tí àwọn ọmọ wọn ń bá kẹ́gbẹ́. Kí gbogbo ìdílé jọ máa najú jáde tún lè pèsè àwọn àǹfààní mìíràn fún eré ìdárayá gbígbámúṣé. Lóòótọ́, eré ìdárayá téèyàn ṣe lẹ́yìnkùlé ilé lè máà mú orí yá gágá tó kéèyàn wà nínú ẹgbẹ́ tó gbégbá orókè. Àmọ́, má ṣe gbà gbé o, pé, “ara títọ́ ṣàǹfààní fún [kìkì] ohun díẹ̀; ṣùgbọ́n fífọkànsin Ọlọ́run ṣàǹfààní fún ohun gbogbo.” ([Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Nǹkan ìgbádùn ló yẹ kí eré ìdárayá jẹ́, kì í ṣe ohun tó ń fa ìjà