Aṣebi-ṣoore Ni Iná Jẹ́
Aṣebi-ṣoore Ni Iná Jẹ́
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ỌSIRÉLÍÀ
INÁ lè ṣeni lóore, ó sì lè ṣeni níbi. Ó lè sọ ojú ilẹ̀ di ọ̀tun tàbí kó bà á jẹ́ ráúráú. Àwọn iná ńláńlá lè di bàsèjẹ́ gbáà, tí yóò sì ṣòro gan-an láti kápá wọn.
Àpẹẹrẹ kan nípa ìparun tí kì í ṣe kékeré tí iná ń ṣe ni ti ohun tó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Indonesia lọ́dún 1997. Lọ́dún yẹn, igbó sísun ṣe orílẹ̀-èdè náà báṣubàṣu, ó sì ṣàkóbá tó kúrò ní kèrémí fún ilẹ̀, ìlera àwọn èèyàn àti ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè náà. Èéfín tó lè gbẹ̀mí èèyàn tó ń wá látinú iná náà sì tàn dé àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí ibẹ̀, tí gbogbo wọ́n jẹ́ mẹ́jọ. Àwọn èèyàn tí wọ́n fojú bù pé ọ̀rọ̀ iná náà kàn tó mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́rin. Ìròyìn jẹ́ ká mọ̀ pé, ogún mílíọ̀nù èèyàn ló dèrò ilé ìwòsàn látàrí àwọn àìsàn bí ikọ́ fée, ẹ̀dọ̀fóró wíwú, àìsàn ọkàn, títí kan ìṣòro ojú àti ti awọ ara tí èéfín iná náà fà.
Inú ewu ni orílẹ̀-èdè Singapore tó wà nítòsí ibẹ̀ wà. Ńṣe ni èéfín bo gbogbo ìlú náà mọ́lẹ̀ bámúbámú. Ẹnì kan tó ń gbé níbẹ̀ figbe bọnu pé: “Gbogbo wa ti di ẹlẹ́wọ̀n sínú ilé wa,” ẹ̀rù sì ń bà á láti jáde síta látinú ilé rẹ̀ tó ní ẹ̀rọ amúlétutù nínú. Láwọn ọjọ́ tí ọ̀rọ̀ náà burú gan-an, èéfín iná náà kò tiẹ̀ jẹ́ kí àwọn èèyàn rí oòrùn sójú rárá.
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ìyẹn 1998, ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ èèyàn tó ń gbé ní agbègbè British Columbia, ní orílẹ̀-èdè Kánádà ló di dandan fún láti sá kúrò nínú ilé wọn bí iná tó ń jó wòwò kan ti ń yára sún mọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Ọ̀kan ṣoṣo péré lèyí jẹ́ lára nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ìṣẹ̀lẹ̀ iná tó wáyé jákèjádò orílẹ̀-èdè Kánádà lọ́dún yẹn—márùndínlọ́gọ́fà lára àwọn iná náà ni wọ́n sì sọ pé apá fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ká. Igbó tó fẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún márùnlélọ́gbọ̀n hẹ́kítà ni iná jó kanlẹ̀ ní agbègbè àríwá Alberta, ní ilẹ̀ Kánádà. Ẹnì kan tó ń gbé níbẹ̀ sọ pé: “Ńṣe ló dà bí ìgbà tí bọ́ǹbù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé bá bú. Tí èéfín dúdú kirikiri sì bo gbogbo àgbègbè náà pitimu.”
Iná Léwu
Iná lágbára gan-an, aburú tó sì ń ṣe fún àyíká kì í ṣe kékeré. Iná tó ń jó fòfò láìdáwọ́dúró lè sọ ilẹ̀ dìdàkudà, ó lè dabarú ètò bí àwọn irúgbìn ṣe máa ń hù, ó lè ṣàkóbá fún àjọṣe àwọn ẹranko inú igbó, ó sì lè fi ẹ̀mí èèyàn àti dúkìá sínú ewu.
Iná ńlá lè dá kún ìṣànlọ erùpẹ̀. Nígbà tí òjò ńlá tó ń tẹ̀ lé àkókò ẹ̀ẹ̀rùn gbígbóná janjan bá ti rọ̀ sórí ilẹ̀, ńṣe ló máa gbá àwọn erùpẹ̀ tí iná ti fẹjú wọn síta lọ. Àwọn ọ̀wọ́ ewéko pàápàá kò mórí bọ́. Àwọn kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí ara gbàyà nínú wọn máa ń kàgbákò tí wọ́n á sì kú, nígbà tí àwọn kan á rù ú là láìfi bẹ́ẹ̀ rí ìpalára. Àmọ́ ohun tó dunni nínú ọ̀ràn ọ̀hún ni pé, àwọn èpò tí kò wúlò ló máa ń rù ú là, tí wọ́n á gba gbogbo ilẹ̀ kan, tí wọn kò sì ní jẹ́ kí àwọn ohun ọ̀gbìn tó ti ń hù níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ gbérí.
Àwọn ẹranko tó sì jẹ́ pé ó ní irú àwọn ewéko kan pàtó tí wọ́n máa ń jẹ pàápàá á wá kòṣòro. Àwọn ẹranko ilẹ̀ Ọsirélíà kan, irú bí koala àti possum onírù yẹtuyẹtu jẹ́ irú ọ̀wọ́ ẹranko tí ewu ti ń wu tẹ́lẹ̀, tó sì jẹ́ pé ìgbàkigbà ni wọ́n lè pòórá tí púpọ̀ nínú ibi tí wọ́n ń gbé bá di èyí tí iná jó run. Láàárín igba ọdún tó kọjá, ilẹ̀ Ọsirélíà ti pàdánù ìdá márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn igbó kìjikìji rẹ̀, ìdá mẹ́rìndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ẹgàn rẹ̀, ìdá mọ́kàndínlógún nínú ọgọ́rùn-ún ọ̀wọ́ ẹranko afọ́mọlọ́mú rẹ̀, àti ìdá méjìdínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ọ̀wọ́ irúgbìn rẹ̀, tó jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ni wọn kò lè rí níbikíbi mìíràn lágbàáyé.
Láti àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn, tí àwọn ìlú ńlá ti
túbọ̀ ń di èyí tó ń fẹ̀ sí i wọnú àwọn igbó tó wà láyìíká, àwọn èèyàn ti túbọ̀ fi ara wọn sínú ewu ńláǹlà tí dídáná sun igbó máa ń fà. Ní oṣù December ọdún 1997, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìṣẹ̀lẹ̀ iná ló wáyé láwọn àgbègbè kan lẹ́bàá ìlú Sydney, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà àti láwọn ìlú kéékèèké tó wà lágbègbè Blue Mountains, ó sì lé ní ẹgbàá márùnlélọ́gọ́fà [250,000] hẹ́kítà ilẹ̀ tí iná jó run. Nǹkan bí ìdajì lára àwọn iná yìí ló di ohun tápá ò ká mọ́. Kọmíṣọ́nnà fún ọ̀ràn tó jẹ mọ́ iná sọ pé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ iná náà jẹ́ èyí tó tíì burú jù lọ tí òún rí láti ọgbọ̀n ọdún sí àkókò náà. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló di dandan fún láti sá kúrò nínú ilé wọn, ilé àwọn kan sì jó kanlẹ̀ ráúráú nínú iná náà. Ẹ̀mí èèyàn méjì ló bá a rìn. Láti apá ìparí oṣù December ọdún 2001, dídáná sun igbó tí wọ́n gbà pé àwọn tí wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ dáná sun nǹkan ló fà á pa igbó tó tó ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáje [753,000] hẹ́kítà run.Ohun Tó Máa Ń Fa Iná
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè fa àwọn iná tí apá kì í ká. Ọ̀kan lára wọn tí kò ti ọwọ́ ẹ̀dá wá ni ipò ojú ọjọ́ tí kò ṣe déédéé tí wọ́n ń pè ní El Niño, tó máa ń fa ooru tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí gbogbo nǹkan á sì gbẹ táútáú yíká ayé. Ìlúkílùú tó bá kàgbákò ojú ọjọ́ gbígbẹ táútáú tí El Niño lè fà nígbàkigbà, wà nínú ewu iná.
Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, ìwà àìnírònú àwọn èèyàn ló ń fa àwọn iná ńláńlá tó máa ń ṣẹlẹ̀. Lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìwà ọ̀daràn ni wọ́n ka kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ ki iná bọ igbó sí. Wọ́n fojú bù ú pé mímọ̀ọ́mọ̀ sọ iná sí nǹkan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ iná tó ṣèèṣì wáyé ló fa ohun tó lé ní ìdajì lára àwọn iná tó jó igbó ìjọba run nílùú New South Wales, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà.
Ṣíṣàìbìkítà fún àyíká tún jẹ́ kókó mìíràn tó lè fa iná ńlá. Nítorí bí àwọn èèyàn ṣe ń pa igbó run tí wọ́n sì ń gé igi lulẹ̀, àwọn igbó túbọ̀ ń di èyí tó ń tètè gbaná. Àwọn ìràwé àti pàǹtírí gbígbẹ tí iná nílò láti jó ti pọ̀ sí i nítorí àwọn ẹ̀ka igi àti ewé tó ń wá látinú gígé gẹdú. Gígé gẹdú tún máa ń mú òjìji tí ewé ń pèsè kúrò, tí yóò wá jẹ́ kí oòrùn ráyè pa àwọn pàǹtírí tó wà nílẹ̀ tí wọ́n á sì gbẹ hán-únhán-ún. Tí iná bá sì fi lè kan àwọn pàǹtírí tára wọn ti gbẹ̀kan yìí pẹ́nrẹ́n, iná tó máa sọ lè lágbára gan-an, ó sì lè di èyí tí apá ò ní í ká.
Owó táwọn èèyàn máa rí tún lè dá kún iná ńláńlá tó ń ṣẹlẹ̀. Nílẹ̀ Indonesia, láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ dídánásungbó, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ ṣe àkóbá kankan fún àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn. Nígbà táwọn àgbẹ̀ bá fìṣọ́ra lo iná tí wọ́n sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, àbájáde kan náà ló máa ní lórí àyíká bí iná tá a dá fún ète rere. Àmọ́ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, iṣẹ́ àgbẹ̀ dídánásungbó ti wá fẹjú gan-an, ó sì ti di ti àwọn
onílé-iṣẹ́ ńláńlá. Pẹ̀lú bí àwọn irè oko bí epo pupa ṣe túbọ̀ ń di ohun táwọn èèyàn ń béèrè fún káàkiri ayé, ọ̀pọ̀ igbó ni wọ́n ti jó kanlẹ̀, tí wọ́n sì ń gbin àwọn igi ọ̀pẹ tó máa ń tètè dàgbà tó sì ń mú owó rẹpẹtẹ wá rọ́pò wọn. Dídánásungbó ni ọ̀nà tó rọrùn jù lọ tí kò sì tún fi bẹ́ẹ̀ náni lówó láti rí ibi gbin nǹkan sí. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún hẹ́kítà igbó làwọn èèyàn ń dáná sun, láìkọbiara sí àwọn àǹfààní tó wà pẹ́ títí tí níní igbó tó pọ̀ máa ń mú wá.Oore Tí Iná Ń Ṣe
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iná lè pa nǹkan run kó sì ba nǹkan jẹ́ ráúráú, ó tún lè ṣe ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ irúgbìn àti ẹranko láǹfààní tó pọ̀. Kódà, iná ní ipa pàtàkì tó ń kó lára àwọn ìṣẹ̀dá tó ń bẹ láyìíká. Ọ̀nà wo ló ń gbà ṣe èyí?
Iná jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀rẹ́ èèyàn tó ti wà tipẹ́. Ó ń mú ara móoru, ó ń pèsè ìmọ́lẹ̀, a sì ń fi se oúnjẹ. Àwọn ará Ọsirélíà ayé ọjọ́un ti lo iná fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún gẹ́gẹ́ bí ara iṣẹ́ wọn ojoojúmọ́, wọ́n sì tún máa ń lò ó láwọn àkókò kan pàtó. Iná ṣe pàtàkì gan-an fún àwọn èèyàn ìbílẹ̀ Yanyuwa débi pé, wọ́n ní ju ọ̀rọ̀ méjìlá lọ tí wọ́n ń fi ṣàpèjúwe oríṣiríṣi iná àti ohun táwọn iná náà wà fún. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè lo ọ̀rọ̀ náà kambambarra nígbà tí wọ́n bá ń sọ nípa irú iná tó máa ń jó igbó tàbí ẹgàn run. Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà warrman láti ṣàpèjúwe irú iná tí wọ́n lè fi sun àgbègbè eréko kan, èyí tó wúlò fún iṣẹ́ ọdẹ. Wọ́n sì máa ń pe iná tí èéfín rẹ̀ ń lọ sókè tààrà tó sì dà bí ìkúùkù ní rrumarri.
Àwọn èèyàn ìbílẹ̀ yìí máa ń fi ètùfù dáná sun igbó, kí koríko tútù lè hù, kí èyí sì lè fa àwọn ẹranko igbó wá síbẹ̀. Wọ́n máa ń lo iná kékeré, tó rọra ń jó láti dín àwọn pàǹtí igi àti ìràwé gbígbẹ tó ga pelemọ kù, èyí tó jẹ́ pé òun gan-an ni olórí ohun tó ń fa àwọn iná ńláńlá nínú igbó. Fífi ìṣọ́ra lo iná lọ́nà yìí ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà láti lo ilẹ̀ wọn lọ́nà tí wọ́n fi ń rí oúnjẹ déédéé láìsí pé ó ń ṣàkóbá fún ewéko àti ẹranko igbó. Ó tún ti dín ewu kí iná máa ká àwọn èèyàn mọ́nú ẹgàn lójijì kù.
Àǹfààní Tó Wà Nínú Fífi Ìṣọ́ra Lo Ìná
Nígbà táwọn ará Yúróòpù dé láti tẹ̀ dó sí ilẹ̀ Ọsirélíà ní ohun tó lé díẹ̀ ní igba ọdún sẹ́yìn, fífi ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ lo iná lọ́nà tó ń ṣàǹfààní fún ẹ̀dá èèyàn àtàwọn ìṣẹ̀dá yòókù yìí kò bá wọn lára mu. Lójú àwọn ará Yúróòpù, èèyàn ò gbọ́dọ̀ finá sígbó rárá. Bí fífi iná sun igbó ṣe di ohun tí kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ mọ́ nìyẹn, àmọ́ nítorí pé àwọn pàǹtírí igbó ti di èyí tó ga pelemọ tí wọ́n sì ti gbẹ, tí iná bá wá ṣẹlẹ̀, ó máa ń lágbára gan-an ó sì máa ń ṣòroó kápá. Ṣùgbọ́n, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ìjọba ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣà àwọn èèyàn ìbílẹ̀ Ọsirélíà yẹn wọ́n sì ti ń lo ìlànà kan tí wọ́n ń pè ní fífi ìṣọ́ra lo iná. Ìlànà yìí jẹ́ fífi ìṣọ́ra dá iná láti fi sun àwọn pàǹtírí igbó láti dènà àwọn iná ńlá tí apá kò ní ká. Wọ́n á dá iná kéékèèké láwọn ìgbà tí kì í ṣe àkókò ìdánásungbó. Àwọn iná yìí á rọra máa jó lọ, wọn ò ní jẹ́ kó jó bùlàbùlà, iná náà á sì máa palẹ̀ àwọn pàǹtírí mọ́ láìsí pé wọ́n ń ṣe ìpalára fún àwọn igi. Ìrì tó máa ń sẹ̀ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ ló sábà máa ń pa àwọn iná náà.
Ìdí tí wọ́n fi máa ń dáná sun igbó lọ́nà yìí ni láti dáàbò bo ẹ̀mí àti dúkìá, lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n tún ń dá ẹ̀mí onírúurú ohun ọ̀gbìn àti ẹranko sí. Fífi ìṣọ́ra sun igbó lọ́nà yìí sì tún ni ọ̀nà gbígbéṣẹ́ kan ṣoṣo láti dín àwọn èpò tó jẹ́ àjèjì tó máa ń yára tàn kálẹ̀ kù. Ó tún máa ń ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo onírúurú ibùgbé àdánidá àwọn ẹranko ìgbẹ́.
Àwọn ọ̀wọ́ irúgbìn kan wà tó dà bí ẹni pé iná ni wọ́n gbára lé kí àwọn hóró wọn tó lè hù. Èèpo ẹ̀yìn àwọn kan le débi pé, wọ́n nílò iná láti fọ́ wọn kí omi tó lè ráyè wọnú wọn. Àwọn olùwádìí tún ti rí i pé èéfín tó ń wá látinú iná máa ń ṣèrànwọ́ fún hóró irúgbìn láti dàgbà. Nǹkan bí àádọ́rin èròjà ló wà nínú èéfín iná, èyí tí wọ́n ronú pé ó máa ń jẹ́ kí irúgbìn dàgbà, ọ̀kan pàtàkì lára wọn ni èròjà nitrogen dioxide.
Ilẹ̀ tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ sun máa ń jẹ́ kí erùpẹ̀ ní àwọn èròjà tó máa ṣe ilẹ̀ lóore, irú bíi nitrogen àti phosphorus. Iná máa ń jẹ́ kí àwọn èròjà inú ìràwé ráyè jáde, ó máa ń jẹ́ kí ìtànṣán oòrùn túbọ̀ ráyè wọnú ilẹ̀, ó sì máa ń mú kí ilẹ̀ lẹ́tù lójú gan-an fún irúgbìn tuntun láti ta gbòǹgbò. Bí àpẹẹrẹ, igi bọn-ọ̀n-ní máa ń tún èso so lẹ́yìn tí iná bá ṣẹlẹ̀, ó sì máa ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lẹ́yìn náà.
Ó tún dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ ẹranko ló máa ń jàǹfààní lẹ́yìn tí iná bá ṣẹlẹ̀, àgàgà látinú àwọn ewéko tútù yọ̀yọ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rú yọ, èyí tó máa ń rọrùn fún wọn láti jẹ tó sì máa ń gbádùn mọ́ wọn. Àwọn ọ̀wọ́ ẹranko kangaroo àti wallaby kan nífẹ̀ẹ́ sí àwọn igbó tí wọ́n máa ń sun nígbà gbogbo, a sì gbọ́ pé iná ni wọ́n gbára lé. Ìdí èyí ni pé, iná ni àwọn ewéko tí wọ́n máa ń jẹ àti ibi tí wọ́n ń gbé sinmi lé láti tún rú yọ, kí wọ́n máà sì kú.
A Ṣì Ní Ọ̀pọ̀ Nǹkan Láti Kọ́
Àwọn èèyàn túbọ̀ ń lóye ọ̀nà tí iná ń gbà ṣe ibi àti ọ̀nà tó ń gbà ṣe oore, àmọ́ bí iná ṣe ń nípa lórí àyíká wa díjú púpọ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan la sì ní láti kọ́. Bí iná ṣe ń nípa lórí ọ̀wọ́ àwọn irúgbìn àtàwọn ẹranko kan ṣì jẹ́ ohun tó pọn dandan láti ṣèwádìí lé lórí. Àjọṣe tó sì wà láàárín iná, àwọn ohun alààyè àti àyíká, àti ipa tí iná ń ní lórí wọn lọ́nà tó gbòòrò náà tún nílò ìwádìí sí i. Lára àwọn ìbéèrè tó ń wá ìdáhùn ni: Ǹjẹ́ iná wà lára àwọn ohun tó ń fa bí ayé ṣe ń móoru? Ipa wo ni èéfín iná ń ní lórí ipò ojú ọjọ́? Báwo sì ni iná ṣe máa ń jó nínú àwọn ipò kan pàtó?
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí kọ̀ǹpútà kan ti wà tí wọ́n pè ní àwòkọ́ṣe, èyí tí wọ́n ṣe láti fi mọ bí iná ṣe máa ń jó nínú àwọn ipò kan pàtó. Wọ́n ṣe wọ́n lọ́nà tí wọ́n á fi lè ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ oríṣiríṣi ìsọfúnni lórí ipò ojú ọjọ́, ohun tó ń mú iná jó, bí afẹ́fẹ́ ṣe máa ń yára fẹ́ sí, àtàwọn ipò mìíràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ojú ọjọ́. Ó dunni pé, ní báyìí ná, àwọn irinṣẹ́ náà kò tíì ṣe é gbára lé lọ títí, wọn ò sì lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ iná ńlá, irú bí iná tó máa ń ṣàdédé ṣẹ́ yọ níbì kan tàbí bí iná ṣe máa ń di ńlá lójijì. Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ iná tó wáyé ní ìlú Sydney lọ́dún 1997, àwọn àgbà òṣìṣẹ́ panápaná méjì ló pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí iná náà ṣàdédé gba ibi tí wọn ò retí yọ. Orúkọ tí wọ́n fún ìṣesí iná yìí bá a mu gẹ́lẹ́, wọ́n pè é ní, “fingers of death” [ìbùlàlà iná tí ń ṣekú pani].
Ó máa ń ṣòro gan-an láti sọ pé ọ̀nà báyìí ni iná ńlá máa gbà jó, nítorí ó lè yí ipò ojú ọjọ́ padà fúnra rẹ̀, ó lè fa ẹ̀fúùfù líle, ìkùukùu, kódà ó lè mú kí àrá sán. Atẹ́gùn tó ń gbé iná lè kọrí sí ibòmíràn láìròtẹ́lẹ̀ tàbí kó di ńlá lójijì, kó má sì jẹ́ kí iná náà dúró sójú kan rárá. Àwọn olùwádìí ń retí láti mú kí àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ń lò lọ́wọ́ báyìí dára sí i, nípa ṣíṣiṣẹ́ lórí àwọn kókó yìí àtàwọn ìsọfúnni mìíràn, irú bí, bí àgbègbè ilẹ̀ kan ṣe rí, bó ṣe dagun sí, àti bí àwọn nǹkan tó ń mú iná jó ṣe wà káàkiri sí.
Kí ọwọ́ lè tẹ ohun tí wọ́n ń lépa yìí, Ibùdó Ìwádìí fún Mímọ Ipò Ojú Ọjọ́ Ti Ìjọba Àpapọ̀, èyí tó wà ní ìlú Colorado, nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ti bẹ̀rẹ̀ ètò kan tó máa jẹ́ kí ọwọ́ wọn tẹ ohun tí wọ́n ń lépa yìí. Ibùdó Ìwádìí yìí ní ọkọ̀ òfuurufú [C-130], èyí tó ní àwọn irinṣẹ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó díjú gan-an nínú àti ibi tí wọ́n ti ń fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́ tó jẹ́ méje, wọ́n sì fi àwọn nǹkan tí kò ní í jẹ́ kí ooru iná bà wọ́n jẹ́ dáàbò bò wọ́n. Wọ́n ṣe ọkọ̀ òfuurufú náà lọ́nà tó máa fi lè fò lórí iná kan tó ń jó gidi, tí wọ́n á sì gba àwọn ìsọfúnni nípasẹ̀ àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n so mọ́ àwọn apá ọkọ̀ òfuurufú náà. Lẹ́yìn náà ni wọ́n á fi àwọn ìsọfúnni náà ránṣẹ́ sínú àwọn kọ̀ǹpútà náà láti ṣiṣẹ́ lé wọn lórí. Ọkọ̀ òfuurufú náà ní kámẹ́rà kan tí wọ́n so mọ́ ọn lára tí wọ́n ń pè ní Thermacam, èyí tó lè fi bí apá ibì kọ̀ọ̀kan nínú iná náà ti lágbára tó hàn. Lọ́nà yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ń ṣiṣẹ́ ní ibùdó ìwádìí náà ń kẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe lè ṣàtúnṣe sí àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ń lò báyìí láti fi mọ̀ nípa iná, kí wọ́n sì mú kó sunwọ̀n sí i.
Ìrètí wọn ni pé àwọn irinṣẹ́ tó máa lágbára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ yìí á ran àwọn ògbógi lọ́wọ́ láti lè túbọ̀ kápá iná lọ́nà tó dára sí i tí kò sì ní mú ewu lọ́wọ́. Mímọ ọwọ́ tí iná lè yọ ní àmọ̀dunjú á tún dín ewu tí àwọn òṣìṣẹ́ panápaná máa ń dojú kọ kù nígbà tí wọ́n bá ń dáàbò bo ìlú.
Bẹ́ẹ̀ ni o, iná lè jẹ́ olubi tó ń fa ìsọdahoro àti ìparun nígbà tí apá kò bá ká a, síbẹ̀ ó tún lè jẹ́ olóore tó wúlò fúnni. Ipa kékeré kọ́ ló ń kó lára àwọn ìṣẹ̀dá tí Ẹlẹ́dàá ti fi sí ipò wọn, láti máa mú ojú ilẹ̀ ayé lẹ́wà àti láti mú kí àjọṣe tó wà láàárín onírúurú nǹkan ọ̀gbìn àti ẹranko ìgbẹ́ máa bá a lọ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ìgalà “elk” tí jìnnìjìnnì mú ń sá fún iná kan tó ń sọ kẹ̀ù ní àfonífojì Odò Bitterroot ní Montana
[Credit Line]
John McColgan, BLM, Alaska Fire Service
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Iná tí wọ́n fi ìṣọ́ra dá ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà
[Credit Line]
A fún wa ní fọ́tò yìí nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Queensland Rural Fire Service