Irú Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìwà Ipá?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Irú Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìwà Ipá?
ÌWÀ ipá ti gbilẹ̀, onírúurú ọ̀nà ló sì ń gbà ṣẹlẹ̀. Yàtọ̀ sí pé ó máa ń wáyé nígbà ogun, ìwà ipá tún máa ń ṣẹlẹ̀ nínú eré ìdárayá, nígbà táwọn èèyàn bá ti lo oògùn olóró, láàárín àwọn àjọ ìpàǹpá, ní ilé ẹ̀kọ́, àti níbi iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ipá sì tún máa ń wà nínú eré ìnàjú. Ó tiẹ̀ dà bíi pé ìwà ipá abẹ́lé ti wá wọ́pọ̀ báyìí nínú ọ̀pọ̀ ìdílé. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí fi hàn pé ní orílẹ̀-èdè Kánádà, ọgọ́ta ọ̀kẹ́ [1,200,000] àwọn ọkùnrin àti obìnrin ni ọkọ wọn tàbí aya wọn lù lálùbolẹ̀, ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan láàárín ọdún márùn-ún. Ìwádìí mìíràn sọ pé nǹkan bí ìdajì àwọn ọkùnrin tó máa ń lu àwọn aya wọn ló tún máa ń lu àwọn ọmọ wọn náà nílùkulù.
Ó dájú pé bí ìwà ipá ṣe máa ń já ọ láyà náà ló ń já ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn mìíràn láyà. Síbẹ̀, ìwà ipá ti di apá pàtàkì kan nínú ọ̀pọ̀ jù lọ eré ìnàjú tó wà lónìí. Àwọn ìwà ipá tí wọ́n díbọ́n rẹ̀ nínú sinimá nìkan kọ́ ló máa ń mórí àwọn èèyàn yá, ṣùgbọ́n wọ́n tún máa ń gbádùn wíwo àwọn tó dìídì ṣẹlẹ̀ gan-an tí wọ́n máa ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n. Ẹ̀ṣẹ́ kíkàn àtàwọn eré ìdárayá mìíràn tó ní ìwà ipá nínú ti wá di ohun táwọn èèyàn kúndùn jù lọ lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè. Àmọ́ irú ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìwà ipá?
Ọjọ́ Ìwà Ipá ti Pẹ́
Ìwà ipá ti ń bá a bọ̀ ọjọ́ pẹ́. Ìwà ipá àkọ́kọ́ tó tọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn ṣẹlẹ̀, tá a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 4:2-15. Kéènì, ọmọkùnrin tí Ádámù àti Éfà kọ́kọ́ bí jowú àbúrò rẹ̀, Ébẹ́lì, ó sì mọ̀ọ́mọ̀ ṣekú pa á. Kí ni Ọlọ́run ṣe? Bíbélì ṣàlàyé pé Jèhófà Ọlọ́run fìyà ńlá jẹ Kéènì fún pípa tó pa arákùnrin rẹ̀.
Ní Jẹ́nẹ́sísì 6:11, a kà pé ní ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ilẹ̀ ayé “kún fún ìwà ipá.” Lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ni Ọlọ́run ṣe? Ó pàṣẹ fún Nóà tó jẹ́ olódodo èèyàn láti kan ọkọ̀ áàkì tí yóò lò láti gba ẹ̀mí òun àti ìdílé rẹ̀ là nígbà tí Jèhófà bá mú àkúnya omi wá sórí ilẹ̀ ayé, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ “pa” àwùjọ oníwà ipá yẹn “run.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:12-14, 17) Àmọ́ kí ló fà á tó fi jẹ́ pé kò sóhun méjì tó máa ń wà lọ́kàn àwọn èèyàn yẹn ju ìwà ipá lọ?
Ipa Tí Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ń Kó
Àkọsílẹ̀ tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ká mọ̀ pé, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ọlọ́run, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn, gbé ara èèyàn wọ̀, wọ́n fẹ́yàwó, wọ́n sì bí àwọn ọmọ. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-4) Àwọn ọmọ tí wọ́n bí, tá a mọ̀ sí àwọn Néfílímù, tóbi kọjá ààlà wọ́n sì lókìkí gan-an. Lábẹ́ ìdarí àwọn bàbá wọn tí wọ́n jẹ́ ẹ̀mí èṣù, wọ́n di abúmọ́ni wọ́n sì kún fún ìwà ipá gan-an. Nígbà tí ìkún omi náà pọ̀ gidigidi tó sì bo ilẹ̀ ayé mọ́lẹ̀, àwọn abúmọ́ni olubi náà ṣègbé. Àmọ́ ó jọ pé ńṣe làwọn ẹ̀mí èṣù náà bọ́ ara èèyàn tí wọ́n gbé wọ̀ sílẹ̀ tí wọ́n sì padà sí ilẹ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí.
Bíbélì fi yé wa kedere pé látìgbà náà wá ni àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí ti ń darí àwọn ẹ̀dá èèyàn lọ́nà tó lágbára. (Éfésù 6:12) Bíbélì pe olórí wọn, ìyẹn Sátánì, ní “apànìyàn” láti ìpilẹ̀ṣẹ̀. (Jòhánù 8:44) Nípa bẹ́ẹ̀, a ò ṣì sọ tá a bá sọ pé àwọn ẹ̀mí èṣù tàbí Sátánì ló wà lẹ́yìn ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.
Bíbélì ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé ìwà ipá ní òòfà lílágbára. Ní Òwe 16:29, ó sọ pé: “Ènìyàn tí ń hu ìwà ipá yóò sún ọmọnìkejì rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀, dájúdájú, yóò mú kí ó rin ọ̀nà tí kò dára.” Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ti di ẹni tí a sún láti gbà pé kò sóhun tó burú nínú ìwà ipá, wọ́n á wá máa gbé e lárugẹ tàbí kí wọ́n máa hù ú níwà. Bákan náà, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti di ẹni tá a tàn jẹ láti máa fi àwọn eré ìnàjú tó ń gbé ìwà ipá lárugẹ ṣe ohun ìgbádùn. A lè lo ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 73:6 lọ́nà tó ṣe rẹ́gí láti fi ṣàpèjúwe ìran èèyàn ọjọ́ òní. Onísáàmù náà sọ pé: “Ìrera . . . dà bí ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn fún wọn; ìwà ipá bò wọ́n kanlẹ̀ bí ẹ̀wù.”
Ọlọ́run Kórìíra Ìwà Ipá
Báwo ló ṣe yẹ káwọn Kristẹni máa hùwà nínú ayé oníwà ipá yìí? Àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù, ìyẹn Síméónì àti Léfì fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó yè kooro. Dínà, arábìnrin wọn, lọ da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ Ṣékémù tí wọ́n jẹ́ oníṣekúṣe. Bí ọmọ ilẹ̀ Ṣékémù kan ṣe bá a lò pọ̀ nìyẹn. Láti gbẹ̀san, Síméónì àti Léfì pa gbogbo àwọn ọkùnrin Ṣékémù nípakúpa. Lẹ́yìn ìgbà náà, lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run, Jékọ́bù gégùn-ún fún ìbínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ èyí tí wọn kò kápá rẹ̀. Ó sọ pé: “Síméónì àti Léfì jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò. Ohun èlò ìwà ipá ni ohun ìjà ìpani wọn. Inú àwùjọ tímọ́tímọ́ wọn ni kí o má ṣe dé, ìwọ ọkàn mi. Má ṣe bá ìpéjọ wọn so pọ̀ ṣọ̀kan.”—Jẹ́nẹ́sísì 49:5, 6.
Níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí, àwọn Kristẹni máa ń yẹra fún níní àjọṣe pẹ̀lú àwọn tó bá ń gbé ìwà ipá lárugẹ tàbí tí wọ́n máa ń hù ú níwà. Ó ṣe kedere pé, Ọlọ́run kórìíra àwọn tó ń gbé ìwà ipá lárugẹ. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) A gba àwọn Kristẹni níyànjú láti yẹra fún ìbínú èyíkéyìí tí a kò ṣàkóso rẹ̀, títí kan ṣíṣe ẹ̀rẹ̀kẹ́ èébú pàápàá.—Gálátíà 5:19-21; Éfésù 4:31.
Ǹjẹ́ Ìwà Ipá Lè Dópin Láé?
Wòlíì ìgbàanì náà, Hábákúkù, béèrè lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá?” (Hábákúkù 1:2) Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run dá Hábákúkù lóhùn, ó ṣèlérí pé òún máa mú “ẹni burúkú” náà kúrò. (Hábákúkù 3:13) Ìwé àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà kọ tún fún wa nírètí. Níbẹ̀, Ọlọ́run ṣèlérí pé: “A kì yóò gbọ́ ìwà ipá mọ́ ní ilẹ̀ rẹ, a kì yóò gbọ́ ìfiṣèjẹ tàbí ìwópalẹ̀ ní ààlà rẹ.”—Aísáyà 60:18.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìdánilójú pé láìpẹ́, Ọlọ́run yóò mú gbogbo onírúurú ìwà ipá kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àtàwọn ẹni tó ń gbé e lárugẹ. Nígbà yẹn, dípò tí ayé ì bá fi kún fún ìwà ipá, ńṣe ni “ilẹ̀ ayé yóò kún fún mímọ ògo Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Hábákúkù 2:14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ìwà ipá bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Kéènì pa Ébẹ́lì