Àkókò Tí Ìfiniṣẹrú Máa Dópin Ti Sún Mọ́lé!
Àkókò Tí Ìfiniṣẹrú Máa Dópin Ti Sún Mọ́lé!
ÒMÌNIRA! Ṣàṣà ọ̀rọ̀ ló lè wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin bí ọ̀rọ̀ òmìnira. Àwọn èèyàn ti bára wọn jà nítorí rẹ̀, wọ́n ti jìyà jewé iyá nítorí rẹ̀, wọ́n ti fi gbogbo ìgbésí ayé wọn lépa rẹ̀, wọ́n sì ti fi ẹ̀mí wọn rúbọ lórí pé wọ́n ń lépa òmìnira. Síbẹ̀síbẹ̀, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ti ṣakitiyan lóòótọ́, àmọ́ kò dà bíi pé ọwọ́ wọn ti tẹ òmìnira tí wọ́n ń lépa. Ǹjẹ́ ìrètí wà pé a lè dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ìfiniṣẹrú, ìyẹn ìrètí kan tí kò ní já sásán tí kò sì ní já sófo? Bẹ́ẹ̀ ni, ìrètí wà.
Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti ṣàkọsílẹ̀ ìlérí rẹ̀, ìyẹn ni pé: “A óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Ṣùgbọ́n báwo ló ṣe dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò mú irú “òmìnira ológo” bẹ́ẹ̀ wá ní tòótọ́? Ọ̀nà kan láti rí ìdánilójú èyí ni nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ti gbà bá aráyé lò jálẹ̀ ìtàn.
Bíbélì sọ pé: “Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá . . . wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.” (2 Kọ́ríńtì 3:17) Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀mí Ọlọ́run, ìyẹn ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀, ní agbára tó pọ̀ gan-an ni. Fún ìgbà pípẹ́ ni Ọlọ́run ti ń lo ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ láti dá àwọn èèyàn sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ oríṣiríṣi ìfiniṣẹrú. Báwo lèyí ṣe rí bẹ́ẹ̀? Tóò, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé onírúurú ìfiniṣẹrú ló wà. A ti sọ̀rọ̀ lórí ọ̀kan lára irú ìfiniṣẹrú tí ó rorò jù lọ, ìyẹn ni báwọn tó lágbára ṣe máa ń fi tìpá tìkúùkù sọ àwọn tí kò lágbára tó wọn dẹrú. Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ ká tún wo irú àwọn ìfiniṣẹrú mìíràn tó wà.
Àwọn èèyàn lè sọ ara wọn dẹrú oríṣiríṣi àṣà tó máa ń di bárakú, ó sì máa ń nira gan-an fún wọn láti ja àjàbọ́. Àwọn èèyàn tún lè sọ ara wọn dẹrú irọ́ pípa àti ìtànjẹ, kí wọ́n gba àwọn ẹ̀kọ́ èké láyè láti máa dà wọ́n ríborìbo. Ìsìnrú kan tún wà tó burú jáì tó ń bá gbogbo wa fínra—bóyá a mọ̀ o tàbí a ò mọ̀—àwọn àbájáde rẹ̀ sì lè ṣekú pani. Àmọ́ ṣá o, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ńṣe la to gbogbo onírúurú ìsìnrú pọ̀ sọ́nà kan nínú ìjíròrò yìí, a ò sọ pé ọgbọọgba ni wọ́n jẹ́. Wọ́n jìnnà síra gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ. Síbẹ̀síbẹ̀, ohun kan wà tó so gbogbo wọn pọ̀. Bópẹ́ bóyá, Ọlọ́run òmìnira yóò rí i dájú pé òún mú gbogbo ẹrù ìnira tí onírúurú ìsìnrú wọ̀nyí dì sórí aráyé kúrò.
Àṣà Tó Ti Di Bárakú Lè Sọni Dẹrú
Kíyè sí bí ìwé náà, When Luck Runs Out ṣe ṣàpèjúwe tẹ́tẹ́ títa láìníjàánu, ó sọ pé: “Ó jẹ́ ìṣòro kan tó máa ń wáyé nígbà tí agbára ìsúnniṣe kan tí kò ṣeé ṣàkóso bá ń sún ẹnì kan láti máa ta tẹ́tẹ́ ṣáá láìlè dáwọ́ dúró. Agbára ìsúnniṣe yìí kì í lọ bọ̀rọ̀, ńṣe ló máa ń jingíri sí i, tí yóò sì máa sún onítọ̀hún ta tẹ́tẹ́ ṣáá . . . títí dìgbà tó fi máa sọ ìgbésí ayé rẹ̀ di báṣubàṣu, tó sì máa bà á jẹ́ ráúráú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.” Kò sẹ́ni tó mọ iye àwọn tí tẹ́tẹ́ títa ti sọ dẹrú. Àwọn oníṣirò fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, àwọn èèyàn tó ti sọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú tó mílíọ̀nù mẹ́fà.
Sísọ ọtí líle di bárakú pàápàá lè ba tèèyàn jẹ́, àfàìmọ̀ ni kò sì burú ju tẹ́tẹ́ títa lọ tó sì tún wọ́pọ̀ jù ú lọ. Ní orílẹ̀-èdè ńlá kan, nǹkan bí ìdajì gbogbo àwọn àgbàlagbà ọkùnrin ibẹ̀ ló ń jìyà lọ́wọ́ àbájáde ọtí líle tí wọ́n ń mu ní àmuyíràá. Ricardo, ẹni tó di ọ̀mùtípara ní ogún ọdún sẹ́yìn ṣàlàyé ohun tí irú àṣà bárakú yìí túmọ̀ sí. Ó sọ pé: “Látìgbà tó o bá ti jí báyìí ni ara rẹ á ti máa ké tantan fún ọtí líle, wàá fẹ́ mu ún kára lè ta kébé, láti fi pàrònú rẹ́ tàbí kó o kàn tiẹ̀ lè ní agbára láti kojú àwọn àlámọ̀rí ìgbésí ayé. Èrò àtimu ọtí ni yóò máa gbà ọ́ lọ́kàn ṣáá, síbẹ̀ wàá máa gbìyànjú láti fọkàn ara rẹ àti tàwọn tó wà láyìíká rẹ balẹ̀ pé o mọ ohun tó ò ń ṣe, pé kò sí ìṣòro kankan.”
Ọtí líle nìkan kọ́ lohun tó ń sọ àwọn èèyàn di ẹrú. Jákèjádò ayé, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń lo àwọn oògùn líle tí kò bófin mu nílòkulò. Láfikún sí i, àwọn èèyàn tó ń mu sìgá lé ní bílíọ̀nù kan, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oògùn líle táwọn èèyàn ń sọ di bárakú jù lọ. Ó wu ọ̀pọ̀ èèyàn gan-an láti jáwọ́ lílo tábà, àmọ́ wọ́n máa ń rò pé ó ti sọ àwọn dẹrú. Ǹjẹ́ Jèhófà tiẹ̀ ti fi hàn rí pé lóòótọ́ lòún jẹ́ Olùdáǹdè fún àwọn èèyàn tó bá wà lábẹ́ irú àwọn ìsìnrú lílágbára bẹ́ẹ̀? a
Òwe 23:20, 21) Mo fẹ́ láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run, àdúrà àtọkànwá tí mo fi ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i pé kó ràn mí lọ́wọ́ ló sì jẹ́ kí n lè bá ara mi sọ òótọ́ ọ̀rọ̀. Ọ̀gbẹ́ni kan kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì wá fi hàn pé ọ̀rẹ́ àtàtà ni òún jẹ́ fún mi. Láwọn àkókò tí mo bá tún padà lọ mutí àmupara, kàkà kí ọ̀rọ̀ mi sú ọ̀rẹ́ mi yìí, ńṣe ló máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ fún mi, kì í sì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ rárá.”
Wo àpẹẹrẹ Ricardo. Ó sọ pé: “Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, mo ṣàkíyèsí pé ọtí líle ló ń darí ìgbésí ayé mi. Ó ń jin ìgbéyàwó mi lẹ́sẹ̀, ó ń pa iṣẹ́ mi lára, ó tún ń ṣàkóbá fún ìdílé mi, mo sì mọ̀ pé mi ò lè yanjú àwọn ìṣòro mi àfi bí mo bá lè bọ́ lọ́wọ́ ohun tó ń fà á. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mo kọ́ ló jẹ́ kí n mọ̀ pé òṣì nípa tara àti nípa tẹ̀mí ló máa ń ta ẹni tó bá jẹ́ ọ̀mùtípara. (Lónìí Ricardo mọ̀ pé òún ti bọ́ lọ́wọ́ àṣà tó ti sọ òun dẹrú nígbà kan, ó kéré tán ìyàtọ̀ wà láàárín ìgbésí ayé tó ń gbé báyìí àti ti tẹ́lẹ̀. Ó sọ pé nígbà tóun kọ́kọ́ ń gbìyànjú láti dáwọ́ àṣà yìí dúró, òún ṣì máa ń mutí àmupara lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ó fi kún un pé: “Láìka bí àwọn ìsapá mi ṣe ń fẹ́ forí ṣánpọ́n sí, ìfẹ́ àtọkànwá mi láti fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà, pa pọ̀ pẹ̀lú ìtìlẹyìn ìyàwó mi àti tàwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi yòókù, ti ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yẹn. Mò ń fojú sọ́nà fún àkókò náà tí Ọlọ́run ṣèlérí, nígbà tí ‘ẹnì kankan kò ní sọ pé, “àìsàn ń ṣe mí,”’ tí ìmukúmu ọtí yóò di ohun àtijọ́. Ní báyìí ná, mi ò ní jáwọ́ láti máa jìjàkadì lójoojúmọ́ kí n bàa lè fi ara mi fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ‘ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.’”—Aísáyà 33:24; Róòmù 12:1.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn kárí ayé ti fúnra wọn rí bí Ọlọ́run ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, bí wọ́n ti ń sapá láti ja àjàbọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn àṣà oríṣiríṣi tó ti di bárakú. Lóòótọ́, àwọn fúnra wọn ló sọra wọn dẹrú, ó lè jẹ́ pé wọ́n ti juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn ìdẹwò kan tàbí àwọn ìṣòro kan. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ti rí i pé Jèhófà jẹ́ Olùdáǹdè tó ní sùúrù gan-an. Ó múra tán láti ran gbogbo àwọn tó bá fẹ́ sìn ín ní ti tòótọ́ lọ́wọ́, kó sì fún wọn lókun.
“Òtítọ́ Yóò . . . Dá Yín Sílẹ̀ Lómìnira”
Bó bá jẹ́ pé irọ́ pípa àti ìtànjẹ ló sọ wá dẹrú ńkọ́? Jésù Kristi mú kó dá wa lójú pé a lè dòmìnira kúrò lọ́wọ́ irú àwọn àṣà wọ̀nyí. Ó sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:31, 32) Lásìkò tó ń sọ̀rọ̀ yẹn, púpọ̀ lára àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ni òfin má-ṣu-má-tọ̀, tó jẹ́ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Farisí, ti sọ dẹrú. Kódà, Jésù sọ nípa àwọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ rẹ̀ pé: “Wọ́n di àwọn ẹrù wíwúwo, wọ́n sì gbé wọn lé èjìká àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò fẹ́ láti fi ìka wọn sún wọn kẹ́rẹ́.” (Mátíù 23:4) Àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ àwọn èèyàn tú wọn sílẹ̀ kúrò nínú irú ìsìnrú bẹ́ẹ̀. Jésù tú àwọn ẹ̀kọ́ èké tó wà nínú ìsìn fó, kódà ó tún sọ ẹni tó ń ṣagbátẹrù wọn. (Jòhánù 8:44) Ó wá fi òtítọ́ rọ́pò àwọn irọ́ wọ̀nyẹn, ó sì ṣàlàyé àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ ìran ènìyàn fún wọn yékéyéké.—Mátíù 11:28-30.
Bíi ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lónìí ń rí i pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, àwọn lè ja àjàbọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké tó wà nínú ìsìn àti kúrò lọ́wọ́ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tó ti sọ wọ́n dẹrú. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ Bíbélì tí ń mára tuni, wọ́n á rí i pé àwọ́n ti wà lómìnira kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù àwọn òkú, tó ń sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di ẹdun arinlẹ̀, wọn kò sì ní máa gbọ̀n jìnnìjìnnì mọ́ nítorí àtimá bàa jìyà ìdálóró ayérayé nínú ọ̀run àpáàdì. Wọ́n á tún rí i pé kò sẹ́ni tó máa mú wọn lọ́ràn-an-yàn láti san owó tí wọ́n ṣiṣẹ́ àṣelàágùn kí wọ́n tó rí fún àwọn àlùfáà tí wọ́n ń fẹnu lásán sọ pé àwọn ń ṣojú fún Kristi—ẹni tó fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Ìyẹn nìkan kọ́ o, òmìnira tó pabanbarì jùyẹn lọ ti sún mọ́lé.
Ìfiniṣẹrú Tó Burú Jù Lọ
Kíyè sí bí Jésù ṣe ṣàpèjúwe irú ìfiniṣẹrú kan tó burú jáì, èyí tá a ti mẹ́nu kàn níṣàájú, tí ó kan gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé, àtọkùnrin, àtobìnrin àtọmọdé àtàgbà. Ó sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Olúkúlùkù ẹni tí ń dá ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.” (Jòhánù 8:34) Ta ló lè fọwọ́ sọ̀yà pé òun kì í dẹ́ṣẹ̀? Kódà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nítorí rere tí mo fẹ́ ni èmi kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́ ni èmi fi ń ṣe ìwà hù.” (Róòmù 7:19) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó lè já ara rẹ̀ gbà kúrò lọ́wọ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé a ò nírètí kankan.
Jésù mú un dá àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ lójú pé: “Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ ó di òmìnira ní tòótọ́.” (Jòhánù 8:36, Bibeli Mimọ) Ìmúṣẹ ìlérí yìí yóò túmọ̀ sí pé, a óò gba òmìnira tòótọ́ tí a ó sì bọ́ lọ́wọ́ ìfiniṣẹrú tó burú jù lọ. Láti lè mọ bá a ṣe lè jàjàbọ́ lọ́wọ́ irú ìfiniṣẹrú yìí, a ní láti kọ́kọ́ mọ bó ṣe sọ wá dẹrú láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá.
Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run dá èèyàn ní ẹ̀dá tó lómìnira láti ṣe ohun tó wù ú, ẹni tó lè pinnu fúnra rẹ̀ pé òun ò ní dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n, ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí kan, tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, di onímọtara-ẹni-nìkan, ó wá fẹ́ láti máa jẹ gàba lórí aráyé, láìka ìyà tí èyí máa fi jẹ ẹ̀dá èèyàn sí. Kó bàa lè ṣe ohun tó ní lọ́kàn yìí, áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ náà, tá a wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù lẹ́yìn ìgbà yẹn, fa àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Ádámù ti mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí àwọn ìtọ́ni pàtó tí Ọlọ́run fún un, ó di ẹlẹ́ṣẹ̀ ó sì tún fa àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ sínú àìpé àti ikú. (Róòmù 5:12) Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Sátánì di “olùṣàkóso ayé,” ‘ẹ̀ṣẹ̀ sì ti ṣàkóso lórí aráyé gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú ikú.’—Jòhánù 12:31; Róòmù 5:21; Ìṣípayá 12:9.
Báwo la ṣe lè gbòmìnira? Bá a bá di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, a lè jàǹfààní látinú ikú ìràpadà tí Kristi kú, èyí tó lágbára láti “sọ ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá di asán, èyíinì ni, Èṣù” tí ó sì lè “dá gbogbo àwọn tí a ti fi sábẹ́ ìsìnrú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn nítorí ìbẹ̀rù ikú nídè kúrò lóko ẹrú.” (Hébérù 2:14, 15) Fojú inú wò ó ná—ìyẹn ni pé a lè bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú! Ǹjẹ́ mímọ̀ nípa irú òmìnira bẹ́ẹ̀ kò mú inú wa dùn?
Ṣùgbọ́n, kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí irú ìfiniṣẹrú tá a mẹ́nu kan níbẹ̀rẹ̀ ìjíròrò yìí? Ǹjẹ́ fífi ipá mú àwọn èèyàn ṣẹrú máa dópin láé?
Ìrètí Tá A Ní Lẹ́sẹ̀ Nílẹ̀
Dájúdájú, ó yẹ ká fọkàn balẹ̀ pé a óò mú irú ìfiniṣẹrú bíburú jáì bẹ́ẹ̀ kúrò. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó dára, ronú lórí èyí: Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ lẹni tó ṣílẹ̀kùn òmìnira tó pabanbarì jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Ó ṣeé ṣe kó o mọ ìtàn yẹn dáadáa.
Àwọn ará Íjíbítì sọ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dẹrú, wọ́n fipá mú wọn láti máa ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó, wọ́n sì ń fi palaba ìyà jẹ wọ́n. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi omijé rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run Ọba aláàánú fún ìrànlọ́wọ́, ó tẹ́tí sí wọn ó sì gbà wọ́n. Jèhófà lo Mósè àti Áárónì gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀, ó ní kí wọ́n sọ fún Fáráò ọba Íjíbítì pé kó jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa lọ lọ́fẹ̀ẹ́. Ńṣe ni ọba onígbèéraga ọ̀hún yarí kanlẹ̀, kódà lẹ́yìn tí Jèhófà ti mú kí ọ̀pọ̀ ìyọnu tó ń hanni léèmọ̀ kọ lu ilẹ̀ náà. Níkẹyìn, Ọlọ́run sọ agbára Fáráò di òtúbáńtẹ́. Bí òmìnira ṣe dé bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nìyẹn!—Ẹ́kísódù 12:29-32.
Ìtàn ọ̀hún fakíki, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? O lè máa wò ó pé kí ló dé tí Ọlọ́run ò tíì ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lásìkò tiwa yìí. Kí nìdí tí kò fi tíì dá sí ọ̀ràn àwa ẹ̀dá ènìyàn, kó sì fòpin sí ìfiniṣẹrú? Rántí pé Jèhófà kọ́ Oníwàásù 8:9.
ni “olùṣàkóso ayé,” Sátánì ni. Nítorí àwọn ìpèníjà tó dìde ní Édẹ́nì nígbà yẹn lọ́hùn-ún ni Jèhófà fi fàyè gba Elénìní búburú yìí láti ṣàkóso fún ìgbà díẹ̀. Ìfiniṣẹrú, ìninilára àti ìwà ìkà wulẹ̀ jẹ́ ara àwọn àmì tó ń jẹ́ ká mọ bí ìṣàkóso Sátánì ṣe rí ni. Láti ìgbà pípẹ́ ni ìṣàkóso ènìyàn ti kùnà pátápátá níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Èṣù ló ń darí wọn. Bíbélì sọ kókó kan ní ṣàkó láti fi sọ bí ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn ṣe rí, ó sọ pé: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Àmọ́ báwo lèyí ṣe máa pẹ́ tó? Bíbélì ṣàlàyé pé à ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àkókò tí ìmọtara-ẹni-nìkan àti ojúkòkòrò máa gbòde kan. (2 Tímótì 3:1, 2) Èyí túmọ̀ sí pé láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù kọ́ wa láti máa gbàdúrà fún, yóò wá fìdí àwùjọ òdodo kan múlẹ̀ níbi tí kò ti ní í sí ìfiniṣẹrú mọ́. (Mátíù 6:9, 10) Jésù Kristi, Ọba tí Ọlọ́run yàn, yóò gbé ìgbésẹ̀ láti mú gbogbo ìràlẹ̀rálẹ̀ ìfiniṣẹrú kúrò títí dìgbà tí ọ̀tá ìkẹyìn náà, ikú, yóò fi di asán.—1 Kọ́ríńtì 15:25, 26.
Nígbà tí ọjọ́ náà bá dé, ìran ènìyàn olóòótọ́ yóò rí i pé dídá tí Ọlọ́run dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì jẹ́ àpẹẹrẹ ráńpẹ́ kan tá a bá fi wéra pẹ̀lú ìdáǹdè tó pabanbarì tó ń bọ̀ yìí. Bẹ́ẹ̀ ni o, bó bá tó àkókò, “a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́.” Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, yóò ṣeé ṣe fún gbogbo àwa èèyàn láti gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run” dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.—Róòmù 8:21.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn èèyàn sábà máa ń jẹun ní àjẹkì nígbà táwọn ará Róòmù bá ń ṣe àríyá tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀. Èyí ló mú kí a pàṣẹ fàwọn Kristẹni láti má ṣe gba oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tó bá fara jọ ọ́ láyè láti sọ wọ́n dẹrú.—Róòmù 6:16; 1 Kọ́ríńtì 6:12, 13; Títù 2:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn èèyàn tí ó tó mílíọ̀nù mẹ́fà làwọn oníṣirò fojú bù pé tẹ́tẹ́ títa ti sọ dẹrú ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan ṣoṣo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni oògùn líle, ọtí líle àti sìgá mímu ti sọ dẹrú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Bíi ti Ricardo, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ti fúnra wọn rí bí Ọlọ́run ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ja àjàbọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn àṣà tó ti di bárakú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́hun nídè kúrò lóko ẹrú, láìpẹ́ àwọn tó jẹ́ olùjọ́sìn tòótọ́ fún Ọlọ́run yóò gba ìdáǹdè tó pabanbarì jùyẹn lọ