Iyọ̀—Ohun Èlò Ṣíṣeyebíye
Iyọ̀—Ohun Èlò Ṣíṣeyebíye
JÉSÙ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:13) Àwọn Lárúbáwá máa ń sọ pé, “Iyọ̀ wà láàárín wa.” Agbára ti iyọ̀ ní láti pa nǹkan mọ́ ló mú kí ọ̀rọ̀ náà “iyọ̀” di àkànlò ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ń gbé gẹ̀gẹ̀ tí wọ́n sì ń bọlá fún nínú àwọn èdè ayé àtijọ́ àti tòde òní.
Wọ́n tún ń lo iyọ̀ bí àmì pé kí nǹkan wà pẹ́ títí. Ìdí rèé tí wọ́n fi ń pe májẹ̀mú tó bá máa wà pẹ́ títí nínú Bíbélì ní “májẹ̀mú iyọ̀.” Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó ń bára wọn dá májẹ̀mú náà á jọ jẹun pa pọ̀, wọ́n á fi iyọ̀ sí oúnjẹ náà láti fi òǹtẹ̀ lù ú. (Númérì 18:19) Lábẹ́ Òfin Mósè, wọ́n gbọ́dọ̀ fi iyọ̀ sínú àwọn ẹbọ tí wọ́n bá rú lórí pẹpẹ, èyí tó dúró fún pé ohun náà wà láìlẹ́gbin.
Àwọn Ojúlówó Ìtàn Tó Ń Fani Lọ́kàn Mọ́ra
Jálẹ̀ gbogbo ìtàn ni iyọ̀ ti jẹ́ ohun ṣíṣeyebíye débi pé àwọn kan tiẹ̀ ti jagun nítorí rẹ̀. Owó iyebíye tí Louis Kẹrìndínlógún sọ pé káwọn èèyàn máa san lórí iyọ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó fa ìyípadà ńláǹlà tó wáyé ní ilẹ̀ Faransé. Bákan náà, wọ́n tún máa ń fi iyọ̀ ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ohun èlò mìíràn. Ńṣe làwọn ẹ̀yà Moor tó jẹ́ oníṣòwò máa ń fi góòlù àti iyọ̀ ṣe pàṣípààrọ̀, wọ́n á fi gíráàmù kan iyọ̀ gba gíráàmù kan góòlù. Ègé iyọ̀ dídì tó le koránkorán làwọn ẹ̀yà kan ní àárín gbùngbùn Áfíríkà sì máa ń lò bí owó. Iyọ̀ làwọn Gíríìkì fi máa ń sanwó ẹrú tí wọ́n bá rà, òun ni wọ́n fi máa ń sọ gbólóhùn náà pé “ẹrú kan kò tó iyọ̀ tí wọ́n fi rà á.”
Nígbà Sànmánì Ojú Dúdú, àwọn èèyàn gba àwọn ohun asán kan gbọ́ nípa iyọ̀. Wọ́n sọ pé tí iyọ̀ bá dà sílẹ̀, àmì pé láburú máa ṣẹlẹ̀ ló jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nínú àwòrán “Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa” tí Leonardo da Vinci yà, ó ya Júdásì Ísíkáríótù tòun ti àwo kékeré tí wọ́n máa ń fi iyọ̀ sínú rẹ̀ tó dojú délẹ̀ níwájú rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, títí di ọ̀rúndún kejìdínlógún, téèyàn bá jókòó sídìí tábìlì níbi àpèjẹ, apá ibi tí àwo iyọ̀ bá wà sí olúwa rẹ̀ ló máa fi bí onítọ̀hún ṣe jẹ́ gbajúmọ̀ tó hàn. Ibi táwọn èèyàn sì buyì fún jù lọ ni ìkángun kìíní tábìlì nítorí pé ìtòsí ibẹ̀ ni wọ́n máa ń gbé àwo iyọ̀ sí.
Látìgbà ìwáṣẹ̀ làwọn èèyàn ti mọ ọgbọ́n tí wọ́n lè fi mú iyọ̀ jáde látinú omi oníyọ̀, omi ọ̀sà àti nínú àpáta. Àkọsílẹ̀ tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ táwọn ará China ṣe nípa oògùn pípò dárúkọ oríṣi iyọ̀ tó lé ní ogójì, ó sì sọ oríṣi ọ̀nà méjì tí wọ́n fi ń mú iyọ̀ jáde. O yani lẹ́nu pé ọ̀nà méjì tó dárúkọ yìí bára mu pẹ̀lú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe iyọ̀ lóde òní. Bí àpẹẹrẹ, agbára tó ń wá látinú oòrùn ni wọ́n fi ń yọ iyọ̀ kúrò nínú omi ọ̀sà ní ilé iṣẹ́ iyọ̀ tó tóbi jù lọ lágbàáyé, tó wà ní etíkun Bahía Sebastián Vizcaíno, ní Baja California Sur, nílẹ̀ Mẹ́síkò.
Ohun táwọn kan fojú bù yẹ fún àfiyèsí, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ ohun náà pé, tí wọ́n bá fa gbogbo òkun tó wà láyé gbẹ ráúráú, “iye iyọ̀ tó máa tinú wọ́n jáde á tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mọ́kàndínlógún kìlómítà níbùú àti lóòró, tàbí kó tó gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù nígbà mẹ́rìnlá àtààbọ̀.” Iye iyọ̀ tó wà ní Òkun Òkú sì fi ìgbà mẹ́sàn-án ju èyí tó wà nínú gbogbo òkun lọ!
Bí Wọ́n Ṣe Ń Lo Iyọ̀ Lóde Òní
Lónìí, nǹkan iyebíye ni iyọ̀ ṣì jẹ́, wọ́n fi ń mú oúnjẹ dùn, wọ́n fi ń tọ́jú ẹran kó má bàa bà jẹ́, wọ́n fi ń ṣe ọṣẹ, ó sì wà lára àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń ṣe gíláàsì. Àmọ́ lílò tí wọ́n tún ń lò ó fún ìlera tọmọdé-tàgbà ló tún wúni lórí jù. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lágbàáyé, wọ́n máa ń po èròjà iodine mọ́ iyọ̀ kí èròjà yìí bàa lè wà nínú ara. Àìtó èròjà iodine yìí nínú ara ló ń fa gẹ̀gẹ̀ ọrùn (tó máa ń wú sí ọrùn èèyàn) tó wọ́pọ̀ láwọn àgbègbè kan, ó tiẹ̀ tún lè burú débi pé ọpọlọ èèyàn ò ní lè ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Bákan náà, àwọn orílẹ̀-èdè kan máa ń fi èròjà fluoride sínú iyọ̀ torí pé kì í jẹ́ kí eyín jẹrà.
Nígbà tá a sọ pé iyọ̀ dára fún ìlera, pé kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ nínú ara àti pé kì í jẹ́ kí ìfúnpá ga ju bó ṣe yẹ lọ, èwo tún wá ni ti àríyànjiyàn nípa iyọ̀ àti ẹ̀jẹ̀ ríru? Àwọn dókítà máa ń sọ fún àwọn tó bá lárùn ẹ̀jẹ̀ ríru pé kí wọ́n dín iyọ̀ àti èròjà tó ní sodium tí wọ́n ń jẹ kù gan-an. Nǹkan bí ìdá ọgbọ̀n sí àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó lárùn ẹ̀jẹ̀ ríru ni iyọ̀ máa ń dà láàmú tí wọ́n bá jẹ ẹ́. Táwọn wọ̀nyí bá rọra ń jẹ iyọ̀ níwọ̀nba, ìfúnpá wọn ò ní ga ju bó ṣe yẹ lọ.
Ó dájú pé iyọ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn túbọ̀ gbádùn oúnjẹ, gẹ́gẹ́ bí Jóòbù ṣe fi hàn nígbà tó béèrè pé: “A ha lè jẹ ohun tí kò dùn láìsí iyọ̀?” (Jóòbù 6:6) Ó yẹ ká dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa, tó “ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa,” tó fi dórí ohun èlò ṣíṣeyebíye náà, iyọ̀.—1 Tímótì 6:17.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Díẹ̀ lára oríṣiríṣi iyọ̀ tó wà (apá ọ̀tún sápá òsì látòkè): (1) Iyọ̀ “Alaea” tí wọ́n ń rí nínú omi òkun, Hawaii; (2) iyọ̀ “fleur de sel,” ilẹ̀ Faransé; (3) iyọ̀ àbáláyé tí wọ́n ń rí nínú òkun; (4) iyọ̀ “sel gris” (iyọ̀ aláwọ̀ eérú), ilẹ̀ Faransé; (5) iyọ̀ wuuru tí wọ́n ń rí nínú òkun; (6) iyọ̀ dúdú tí wọ́n ń rí nínú ilẹ̀, Íńdíà