Kí Ni Mo Lè Ṣe Táwọn Oníbìínú Èèyàn Bá Kò Mí Lójú?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ni Mo Lè Ṣe Táwọn Oníbìínú Èèyàn Bá Kò Mí Lójú?
“Inú ń bí i burúkú burúkú. Mo rò pé torí pé ó rí mi lọ́mọdé ló ṣe fẹ́ lù mí bolẹ̀. Bí mo ṣe ń tàdí mẹ́yìn ni mo ń sọ fún un pé: ‘Dúró ná! Tiẹ̀ ní sùúrù ná! Àní kó o dúró ná! Kí ló dé tó o fi fẹ́ lù mí ná? Mi ò ṣáà ṣe nǹkan kan fún ẹ. Mi ò tiẹ̀ mọ ohun tó ń bí ẹ nínú tó báyìí. Ṣé a lè jọ sọ ohun tó wà ńbẹ̀?’”—David, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.
ṢÉ ÌWỌ náà ti rí ìbínú jàǹdùkú èèyàn kan rí? Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn òde òní yóò jẹ́ “òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere.” (2 Tímótì 3:3) Àní lẹ́yìn tó o ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti má ṣe “bá ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ara fún ìbínú kẹ́gbẹ́ . . . , tí ó máa ń ní ìrufùfù,” àwọn ìgbà míì lè wà tó jẹ́ pé kò sí bóò ṣe ní í bọ́ sọ́wọ́ wọn. (Òwe 22:24) Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá bára rẹ nírú ipò yẹn?
Bó Ṣe Yẹ Kó O Hùwà sí Oníbìínú Ènìyàn
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lónìí lè fi ìbínú tiwọn náà hàn padà. Àmọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á wulẹ̀ dá kún wàhálà ni. Síwájú sí i, tíwọ náà bá fara ya padà, kò ní sí ìyàtọ̀ láàárín ìwọ àti ẹni tínú ń bí yẹn. Òwe 26:4 sọ pé: “Má ṣe dá arìndìn lóhùn ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀, kí ìwọ pẹ̀lú má bàa dà bí tirẹ̀.” Ojú ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Jeremy já a kó tó gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń jẹun ọ̀sán níléèwé pé: “Àwọn ọmọkùnrin kan wà tó jẹ́ pé wọn ò mọ̀ ju kí wọ́n máa fi ara wọn àtàwọn ẹlòmíràn ṣe yẹ̀yẹ́ lọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ mi. Màá kàn ṣe bíi pé mi ò gbọ́ nǹkan tí wọ́n ń sọ ni. Àmọ́ nígbà tí ọ̀kan nínú wọn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ sí màmá mi, ara mi kọ̀ ọ́ mo sì fìbínú pa kuuru mọ́ ọn.” Kí làbọ̀ rẹ̀? Jeremy sọ pé: “Ó nà mí játijàti.”
Bíbélì fúnni ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Òótọ́ ọ̀rọ̀, dídáhùn sí ìbínú pẹ̀lú “ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora,” á wulẹ̀ mú kí nǹkan burú sí i ni. Àmọ́ ṣá, lọ́pọ̀ ìgbà, dídáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́tù lè mú nǹkan rọlẹ̀ kó sì pẹ̀tù sí ìṣòro tó le koko náà.
Dá ọkàn rẹ padà sọ́dọ̀ David tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀. Ó bá ẹni tó fẹ́ lù ú bolẹ̀ náà sọ̀rọ̀ débi tíyẹn fi ṣàlàyé ohun tó ń bí i nínú. Ẹnì kan ló jí oúnjẹ ọ̀sán jàǹdùkú yìí gbé, ló bá fi ìkanra mọ́ ẹni tó kọ́kọ́ pàdé lọ́nà. David ṣàlàyé fún un pé: “Bó o bá nà mí, ìyẹn kọ́ ló máa dá oúnjẹ rẹ padà.” Ló bá sọ fún jàǹdùkú náà pé kó jẹ́ káwọn jọ lọ sí ilé oúnjẹ. David sọ pé: “Nítorí pé mo mọ ẹni tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ rí, mó Òwe 25:15.
bá a wá oúnjẹ mìíràn. Ó bọ̀ mí lọ́wọ́, àtìgbà náà ló sì ti ń ṣe dáadáa sí mi.” Ǹjẹ́ o rí bí ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ṣe lágbára tó? Ìwé Òwe sọ ọ́ lọ́nà yìí pé, ‘ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lè fọ́ egungun.’—Dídáhùn Lọ́nà Pẹ̀lẹ́ —Ìwà Ọ̀dẹ̀ Ló Jẹ́ Ni Àbí Ìwà Akin?
Òótọ́ ni pé èrò náà pé kéèyàn ní ‘ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́’ lè má dùn ún gbọ́ létí. Fífi ìbínú yanjú ìbínú lè dà bí ìwà akin. O tiẹ̀ lè máa bẹ̀rù pé tó o bá lọ ṣe jẹ́jẹ́, àwọn mìíràn á máa wò ẹ́ bí ẹni tí kò lágbára. Àmọ́ kí ló túmọ̀ sí ná láti jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé kan tí wọ́n fi ń ṣèwádìí sọ, jíjẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ túmọ̀ sí jíjẹ́ oníwà tútù. Bó ti wù kó rí, ìwé yìí kan náà tún fi kún un pé: “Okun tó lágbára bí irin ló ń bẹ nínú ìwà tútù yìí.” Nípa bẹ́ẹ̀, dípò tí ìwà pẹ̀lẹ́ ì bá fi jẹ́ àmì àìlera, ó lè jẹ́ àmì okun. Lọ́nà wo?
Ó dára, ìdí kan ni pé, ẹni tó bá ń ṣe pẹ̀lẹ́ máa ń lè ṣàkóso ara rẹ̀, àwọn mìíràn kò sì ní lè mú un ṣe ohun tí kò fẹ́. Àmọ́, ó dà bí ẹni pé ọkàn ẹni tí kò ní ìwà pẹ̀lẹ́ kò balẹ̀, wọ́n tètè máa ń tán an ní sùúrù, tàbí kó máà sí ohun tí kò lè dán wò. Kò tún ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Nítorí àìlèkóra rẹ̀ níjàánu yìí, ó ṣeé ṣe kó máa ní aáwọ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn nígbà gbogbo. Bẹ́ẹ̀ ni, “bí ìlú ńlá tí a ya wọ̀, láìní ògiri, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn tí kò kó ẹ̀mí rẹ̀ níjàánu.” (Òwe 25:28) Láìsí tàbí ṣùgbọ́n nígbà náà, onínú tútù èèyàn lẹni tó lágbára!
Àpẹẹrẹ Àwọn Oníwà Tútù Nínú Bíbélì
Gbé Jésù Kristi yẹ̀ wò. Ó pe ara rẹ̀ ní “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà.” (Mátíù 11:29) Kò le koko tàbí hùwà lọ́nà tí kò bọ́gbọ́n mu rí, kì í foró yaró. Kódà, àpọ́sítélì Pétérù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù tímọ́tímọ́ sọ pé: “Nígbà tí a ń kẹ́gàn [Jésù], kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” (1 Pétérù 2:23) Síbẹ̀ náà, rántí pé Jésù yìí kan náà “wọ inú tẹ́ńpìlì, ó sì lé gbogbo àwọn tí ń tà, tí wọ́n sì ń rà nínú tẹ́ńpìlì síta.” (Mátíù 21:12) Ká tún wá ní Jésù nílò àtìlẹ́yìn Ọlọ́run ni, ó lè ké sí “àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá” lọ! (Mátíù 26:53) Rárá o, Jésù kì í ṣe aláìlera.
Tún wo àpẹẹrẹ tí Gídíónì Onídàájọ́ fi lélẹ̀, tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì wà nínú Àwọn Onídàájọ́ 8:1-3. Lẹ́yìn tó ṣẹ́gun lọ́nà tó kàmàmà nínú ogun kan tó jà, inú bí àwọn sójà kan látinú ẹ̀yà Éfúráímù nítorí wọ́n rò pé kò jẹ́ káwọn náà gbà nínú ògo tó wá látinú ìjà náà. Wọ́n lọ kò ó lójú pé: “Irú ohun wo nìyí tí o ṣe sí wa ní ṣíṣàìpè wá nígbà tí o lọ bá Mídíánì jà? Wọ́n sì gbìyànjú kíkankíkan láti bẹ̀rẹ̀ aáwọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ “akíkanjú, alágbára ńlá” ni Gídíónì o. (Àwọn Onídàájọ́ 6:12) Ó lè fi ìjà dá wọn lóhùn ní kíákíá ká ló fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dá wọn lóhùn, àwọn tí orí wọn ń gbóná náà kò sì lè ṣe ohunkóhun mọ́. Gídíónì bi wọ́n léèrè pé: “Kí ni mo ṣe nísinsìnyí ní ìfiwéra pẹ̀lú yín?” Kí ni àbájáde ìdáhùn onírẹ̀lẹ̀ yìí? “Ẹ̀mí wọn rọ̀ wọ̀ọ̀ sí i.”
Ní paríparí rẹ̀, wo àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa obìnrin kan tó ń jẹ́ Ábígẹ́lì. Dáfídì jẹ́ ìsáǹsá tó ń sá kiri fún ọ̀tá rẹ̀ Sọ́ọ̀lù, ọba Ísírẹ́lì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lílé ni wọ́n lé àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú Dáfídì kúrò nílùú, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹgbẹ́ wọn tí wọ́n á sì pa wọ́n mọ́. Ọkùnrin kan tí wọ́n ràn lọ́wọ́ ń jẹ́ Nábálì, ọkọ Ábígẹ́lì, ọlọ́rọ̀ gidi ni. Àmọ́ Nábálì “le koko, ó sì burú ní àwọn ìṣe rẹ̀.” Nígbà tí àwọn èèyàn Dáfídì nílò oúnjẹ, wọ́n bẹ Nábálì pé kó fún wọn ní díẹ̀. Dípò kó fi ìmoore hàn fún dídáàbò bò ó tí àwọn ọmọlẹ́yìn Dáfídì dáàbò bò ó lọ́fẹ̀ẹ́, ńṣe ni Nábálì “fi ìkanra sọ̀rọ̀ sí” àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì ó sì dá wọn padà lọ́wọ́ òfo.—1 Sámúẹ́lì 25:2-11, 14.
Nígbà tí Dáfídì gbọ́ bẹ́ẹ̀, inú bí i ó sì pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Kí olúkúlùkù sán idà rẹ̀!” Dáfídì àti àwọn èèyàn rẹ̀ ti bọ́ sọ́nà láti lọ pa Nábálì àti gbogbo àwọn ọkùnrin tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ tó ń gbé pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tí Ábígẹ́lì yọ sí wọn. Ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tẹnu ń jẹ àti ohun mímu pàdé Dáfídì lọ́nà. Ó tọrọ àforíjì fún ìwà tí kò bójú mu tí ọkọ rẹ̀ hù ó sì bẹ Dáfídì pé kó má gba ẹ̀mí àwọn aláìṣẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 25:13, 18-31.
Bí Ábígẹ́lì ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ bẹ̀bẹ̀ ló yí ìbínú Dáfídì padà. Àní nígbà tí Dáfídì wá ronú nípa bí ìbínú òun ṣe mú ewu dání tó, ó sọ pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi! Ìbùkún sì ni fún ìlóyenínú rẹ, ìbùkún sì ni fún ìwọ tí o ti dá mi dúró lónìí yìí kí n má bàa wọnú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, kí n sì mú kí ọwọ́ ara mi wá ṣe ìgbàlà mi.” (1 Sámúẹ́lì 25:32-35) Dájúdájú, lọ́pọ̀ ìgbà, tí ‘ìdáhùn kan bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́,’ ó lè yí ìbínú àwọn ẹlòmíràn padà. Àmọ́ ká ní ìdáhùn pẹ̀lẹ́ rẹ kò yí ìbínú padà ń kọ́?
“Fi Ibẹ̀ Sílẹ̀”
O lè yẹra fún bíbu epo síná ìbínú náà nípa rírọra fi ibẹ̀ sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Níbi tí igi kò bá sí, iná a kú.” Ó tún kìlọ̀ pé: “Kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.” (Òwe 17:14; 26:20) Merissa tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ pé: “Ọmọkùnrin kan tó gbajúmọ̀ níléèwé wá bá mi láti bá mi sọ̀rọ̀. Ó sọ fún mi pé mo rẹwà. Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ ti wá bá mi, inú sì ń bí i burúkú burúkú. Ó ní ńṣe ni mo ń fẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin òun, ó sì múra láti bá mi jà! Mo gbìyànjú láti ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un, ṣùgbọ́n kò fẹ́ gbọ́. Lẹ́yìn tá a jáde iléèwé lọ́jọ́ yẹn, ó padà wá pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mìíràn láti wá lù mí! Kíá, mo sá lọ sọ́dọ̀ bàbá ọdẹ mo sì ṣàlàyé fún ọmọbìnrin tínú ń bí náà pé n kì í jà àti pé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ló wá bá mi. Lẹ́yìn náà ni mo wá ń lọ.” Merissa kò fi bínú ṣe ń bí i hùwà padà. Kì í ṣe pé ó rìn kúrò níbi ìjà nìkan ni àmọ́ ó tún ṣe àwọn ohun tó lè dáàbò bò ó. Bí ohun tí ìwé Òwe 17:27 sọ pé, “ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀, ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.”
Àmọ́ ká ní ìwọ gan-an lo lẹ̀bi fún mímú ẹlòmíràn bínú láìmọ̀ ń kọ́? Tọrọ ìdáríjì, ní kíákíá ni kó o yá a ṣe bẹ́ẹ̀! O lè má ṣe ju ìyẹn lọ tí inú ẹni náà á sì rọ̀. Àkókò tá a ń gbé yìí, àkókò wàhálà ni, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò sì rára gba nǹkan sí. Ṣùgbọ́n tó o bá fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú bó o ṣe ń bá àwọn èèyàn lò, ó ṣeé ṣe kó o yẹra fún kíkó sọ́wọ́ oníbìínú èèyàn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
“Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Nígbà míì kò sóhun méjì tí wàá ṣe ju pé kó o fibẹ̀ sílẹ̀ lọ