Bí Àrùn Oríkèé-ara-ríro Ṣe Máa Ń Ṣe Èèyàn
Bí Àrùn Oríkèé-ara-ríro Ṣe Máa Ń Ṣe Èèyàn
“TÓ BÁ TI DI ALẸ́, MÀÁ WO ỌWỌ́ ÀTI ẸSẸ̀ MI TÓ TI YÍ PADÀ, MÀÁ SÌ BÚ SẸ́KÚN.”—MIDORI, JAPAN.
ỌJỌ́ PẸ́ tí àrùn oríkèé-ara-ríro ti ń yọ ẹ̀dá ènìyàn lẹ́nu. Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe nípa òkú àwọn ará Íjíbítì tí wọ́n pa mọ́ fi hàn pé àrùn náà ti wà láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn. Ẹ̀rí fi hàn pé àrùn ọ̀hún ṣe ọ̀gbẹ́ni olùṣàbẹ̀wòkiri tó ń jẹ́ Christopher Columbus. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló sì ń dà láàmú lónìí. Àmọ́ irú àrùn wo tiẹ̀ ni àrùn tó ń sọni di akúrẹtẹ̀ yìí?
Ọ̀rọ̀ òyìnbó náà “arthritis” (làkúrègbé) wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “oríkèé ara wíwú,”
oríṣiríṣi ọ̀nà ló sì ń gbà ṣe èèyàn. Kì í ṣe oríkèé ara nìkan ni àrùn yìí lè bà jẹ́ o, ó tún lè ba àwọn iṣan, egungun àtàwọn nǹkan mìíràn tó so oríkèé ara pa pọ̀ jẹ́. Àwọn oríṣi làkúrègbé kan wà tó lè ba àwọ̀ rẹ, àwọn ẹ̀yà inú rẹ àti ojú rẹ pàápàá jẹ́. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àrùn méjì tó máa ń mú oríkèé ara wú, ìyẹn làkúrègbé tó ń mú oríkèé ara wú àti làkúrègbé tó ń sọ eegun ara di hẹ́gẹhẹ̀gẹ.Bá A Ṣe Ṣẹ̀dá Oríkèé Ara
Ibi tí eegun méjì bá ti pàdé la ń pè ní oríkèé. Oríṣi oríkèé kan wà tó jẹ́ pé àwọn iṣan tó nípọn ló yí i ká, tí wọ́n ń dáàbò bò ó tí wọ́n sì ń fún un lágbára. (Wo àwòrán tó wà lójú ìwé 4.) Awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan máa ń wà níbi oríkèé yìí. Awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí máa ń sun oríṣi omi kan tó máa ń yọ̀. Níbi tí egungun méjì bá sì ti pàdé, oríṣi iṣan kan máa ń wà níbẹ̀ tó máa ń ràn bíi rọ́bà, ìyẹn ni kèrékèré. Òun ni kì í jẹ́ kí egungun rẹ máa lọ ara wọn. Kèrékèré yìí tún ni kì í jẹ́ kí egungun máa dùn ọ́, ó máa ń jẹ́ kí egungun rí nǹkan tó ṣe dẹ̀mùdẹ̀mù sinmi lé, bó o bá sì ṣe iṣẹ́ alágbára, iṣan yìí kò ní jẹ́ kí ẹrù iṣẹ́ yìí pa egungun kan péré, yóò pín in kárí gbogbo egungun tó wà lára.
Fún àpẹẹrẹ, bó o bá ń rìn, sáré tàbí fò sókè, iṣẹ́ alágbára tó o ń fi ìgbáròkó rẹ àti eékún rẹ ṣe yìí fi ìgbà mẹ́ta sí mẹ́jọ ju gbogbo ìwọ̀n ara rẹ lọ! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi iṣan ń pín iṣẹ́ alágbára yìí ṣe, àwọn kèrékèré ló ń mú kí àwọn egungun rí ara gba wàhálà yìí sí nítorí pé ńṣe ni wọ́n máa ń sún kì.
Làkúrègbé Tó Ń Mú Oríkèé Ara Wú
Ní ti làkúrègbé tó ń mú oríkèé ara wú, ńṣe ni àwọn ohun tó ń dènà àrùn nínú ara máa ń gbéjà ko àwọn oríkèé ara. Nítorí àwọn ìdí kan tí kò yéni, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn èròjà ẹ̀jẹ̀ tín-tìn-tín tó ń kó ipa tí kò kéré láti dènà àrùn nínú ara títí kan àwọn tí wọ́n ń pè ní T cells á wọ́ lọ sí oríkèé ara. Àwọn nǹkan kan á ṣẹlẹ̀ nínú oríkèé ara yìí, tó bá yá ibẹ̀ á wá wú. Àwọn èròjà tín-tìn-tín kan nínú ẹ̀jẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i láìdáwọ́dúró, tí wọ́n á dà bíi kókó tí ọyún wà nínú rẹ̀. Àwọn kókó tó yọ jáde yìí ló máa wá mú àwọn mìíràn jáde to máa ń ba kèrékèré jẹ́. Àwọn ibi tí eegun ti pàdé lè wá lẹ̀ pọ̀ mọ́ra wọn, àwọn eegun kò ní lè máa lọ máa bọ̀ mọ́, ibẹ̀ á wá máa ro èèyàn burúkú burúkú. Bákan náà ló tún máa ń ba àwọn iṣan ara jẹ́, tá á wá mú káwọn oríkèé di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, wọn ò sì ní gún régé mọ́ lọ́pọ̀ ìgbà. Irú ọṣẹ́ kan náà ni làkúrègbé tó ń mú oríkèé ara wú yìí sábàá máa ń ṣe fún àwọn oríkèé ara, ó máa ń bá ọrùn ọwọ́, orúnkún àti ẹsẹ̀ jà. Iye tó ju ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí irú làkúrègbé yìí ń ṣe ló tún máa ń yọ kókó lábẹ́ awọ ara. Àwọn mìíràn kì í lókun nínú mọ́, ojú àti ọ̀fun wọn á gbẹ, á sì máa ro wọ́n. Àárẹ̀ tún máa ń mú àwọn tó ní àrùn yìí, ó sì lè máa ṣe wọ́n bí ibà, kí gbogbo ara sì máa ro wọ́n.
Bí làkúrègbé tó ń mú oríkèé ara wú ṣe máa ń ṣe àwọn èèyàn yàtọ̀ síra, bó ṣe ń bẹ̀rẹ̀ àti bó ṣe ń pẹ́ tó náà sì yàtọ̀ síra. Tó bá mú ẹnì kan, ìrora lè bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, kó má lè ṣẹ́ oríkèé ara po, èyí lè gba ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tàbí ọdún bíi mélòó kan pàápàá. Ó sì lè jẹ́ òjijì ló máa dé sí ẹlòmíràn. Ní ti àwọn mìíràn, àrùn yìí kàn lè yọ wọ́n lẹ́nu fún ìwọ̀nba oṣù díẹ̀ kó sì lọ láìṣe wọ́n ní jàǹbá kankan. Àwọn mìíràn sì rèé, àsìkò kan á wà tó máa dà wọ́n láàmú bí ẹni pé ó máa pa wọ́n, bó bá sì yá á tún tù wọ́n. Àrùn yìí máa ń da àwọn èèyàn mìíràn láàmú fún ọ̀pọ̀ ọdún, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n lè rìn tàbí gbé apá wọn.
Àwọn wo ni àrùn làkúrègbé tó ń mú oríkèé ara wú lè ṣe? Dókítà Michael Schiff sọ pé: “Àárín àwọn obìnrin ológójì sí ọlọ́gọ́ta ọdún ló ti wọ́pọ̀ jù.” Àmọ́ ṣá, Schiff tún sọ síwájú sí i pé “ó lè ṣe ẹnikẹ́ni láìka ọjọ́ orí sí, kódà ó lè mú àwọn ọmọdé àtàwọn ọkùnrin pàápàá.” Ó tún wọ́pọ̀ pé káwọn tí èèyàn wọn ní àrùn náà ní in. Ọ̀pọ̀ ìwádìí mìíràn tún fi hàn pé sìgá mímu,
kéèyàn sanra jù àti kéèyàn gba ẹ̀jẹ̀ sára tún lè mú kí àrùn náà mú èèyàn.Làkúrègbé Tó Ń Sọ Eegun Di Hẹ́gẹhẹ̀gẹ
Ìwé ìròyìn Western Journal of Medicine sọ pé: “Làkúrègbé tó ń sọ eegun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ kò yàtọ̀ sí ojú ọ̀run, ibi gbogbo la ti ń rí i. Àwọn èèyàn kì í tètè mọ̀ pé òun ni lọ́pọ̀ ìgbà, ó sì máa ń ṣe jàǹbá tó pọ̀.” Ní tirẹ̀, kò dà bíi làkúrègbé tó ń mú oríkèé ara wú, nítorí kì í sábàá tàn ká àwọn ẹ̀yà ara mìíràn, oríkèé ara kan tàbí mélòó kan ló máa nawọ́ gán tó sì máa ń bà á jẹ́. Bí kèrékèré bá ti bẹ̀rẹ̀ sí jẹ díẹ̀díẹ̀, eegun á wá máa lọ ara wọn. Àwọn eegun kan á bẹ̀rẹ̀ sí ta gọngọ kọjá ibi tó yẹ. Ọyún lè bẹ̀rẹ̀ sí dì síbẹ̀, káwọn eegun náà má lè ṣẹ́ po mọ́ kí wọ́n má sì rí bó ṣe yẹ kí wọ́n rí mọ́. Lára àwọn àmì rẹ̀ tún ni kí ibi ìṣẹ́po ọwọ́ wú, kí ibi oríkèé tí àrùn yìí ń bá jà máa dún bí eegun ibẹ̀ ṣe ń lọ ara wọn, kí iṣan ara máa buni so, kó máa roni, kí ó le gbagidi, kí àtirìn sì dìṣòro.
Láyé àtijọ́, àwọn èèyàn rò pé làkúrègbé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àrùn tó ń sọ eegun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ èyí tí ọjọ́ ogbó ń fà. Àmọ́, àwọn ògbógi ti sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́ ló rí. Ìwé The American Journal of Medicine sọ pé: “Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé oríkèé ara ẹnì kan lè kọṣẹ́ bó ti wù kí ẹni náà lò ó tó ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.” Nígbà náà, kí ló wá ń fa làkúrègbé tó ń sọ eegun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ? Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà The Lancet sọ pé gbogbo akitiyan láti mọ ohun tó ń fà á ni “kò tíì lójú.” Àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé jàǹbá kékeré kan lè kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ sí eegun, bí i kí eegun yẹ̀. Èyí lè mú kí eegun máa gùn lọ síbi tí kò tọ́ kó sì máa ba àwọn kèrékèré jẹ́. Àwọn mìíràn rò pé ibi kèrékèré gan-an ni àrùn náà ti ń bẹ̀rẹ̀. Wọ́n ronú pé bi kèrékèré náà bá ṣe ń jẹrà, eegun kò ní lágbára àtiṣe àwọn ohun tó máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Bí ara bá sì ṣe ń gbìyànjú láti mú kèrékèré yìí padà sípò ni àwọn ìṣòro pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mìíràn á máa yọjú.
Àwọn wo ni làkúrègbé tó ń sọ eegun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ lè ṣe? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ orí nìkan kọ́ ló ń fà àrùn yìí, kí kèrékèré eegun máa daṣẹ́ sílẹ̀ sábàá máa ń yọ àwọn àgbàlagbà lẹ́nu. Àwọn mìíràn tó tún lè ṣe làwọn tí eegun wọn kò jókòó lórí ara wọn dáadáa tàbí tí ẹsẹ̀ àti àwọn iṣan itan wọn kò dúró dáadáa, àwọn tí ẹsẹ̀ wọn gùn jura lọ àti àwọn tí eegun ẹ̀yìn wọn kò jókòó dáadáa. Téèyàn bá tún fi oríkèé ṣèṣe tàbí tó ń ṣiṣẹ́ alágbára tó sì jẹ́ pé oríkèé apá ibì kan ló ń lò jù, ó tún lè jẹ́ kéèyàn ní làkúrègbé tó ń sọ eegun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Bí oríkèé ara bá sì ti bẹ̀rẹ̀ sí bà jẹ́, téèyàn tún wá lọ tóbi jọ̀kọ̀tọ̀, ó lè mú kí àrùn yìí le sí i.
Dókítà Tim Spector sọ pé: “Làkúrègbé tó máa ń sọ eegun ara di hẹ́gẹhẹ̀gẹ jẹ́ àrùn kan tó ṣòro ó ṣàlàyé nítorí àwọn ohun kan pàtó tó wà lágbègbè èèyàn máa ń fà á, bákan náà lèèyàn sì tún lè jogún rẹ̀.” Àwọn tí àrùn yìí lè ṣe jù làwọn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ogójì ọdún sí ọgọ́ta ọdún àtàwọn obìnrin àgbàlagbà tí àrùn náà ti ṣe àwọn kan rí nínú ìdílé wọn. Àrùn yìí tún yàtọ̀ sí àrùn lílágbára mìíràn tó máa ń bá eegun jà nítorí pé ńṣe ni eegun túbọ̀ máa ń lágbára sí i tí làkúrègbé yìí bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀. Àwọn olùṣèwádìí mìíràn tún sọ pé afẹ́fẹ́ tá a ń fẹ́ símú tó ti díbàjẹ́ àti àìsí èròjà fítámì tó tó nínú ara, máa ń fà á.
Ìtọ́jú Rẹ̀
Ìtọ́jú tó wà fún àrùn oríkèé-ara-ríro sábàá máa ń ní nínú egbòogi, ṣíṣe eré ìmárale àti kéèyàn ṣe ìyípadà nínú bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ àti a
lílo irú àwọn egbòogi kan. Dókítà tó ń to ara tó sì tún ń fi ẹ̀rọ ṣètọ́jú aláìsàn lè sọ pé kó o máa ṣe àwọn eré ìmárale kan láti wò ọ́ sàn. Ó lè ní nínú àwọn eré ìmárale tó máa jẹ́ kí iṣan ara rẹ nà, èyí tó máa mú kó o lè mí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn símú dáadáa àti èyí tó la gbígbé irin tó wúwo lọ. Ẹ̀rí ti fi hàn pé àwọn eré ìmárale wọ̀nyí máa ń mú àwọn ohun tí àrùn yìí máa ń fà kúrò, bí i kí oríkèé máa roni kó sì wú, kó máa rẹni, kó máa dà bí ẹni pé ara èèyàn kò yá àti kéèyàn máa sorí kọ́. Eré ìmárale tún ń ṣàǹfààní fún àwọn tó ti darúgbó kùjọ́kùjọ́ pàápàá. Eré ìmárale kò tún ní jẹ́ kí eegun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Àwọn kan sọ pé ìtọ́jú olóoru àti olómi tútù pẹ̀lú ìlànà ìwòsàn akupọ́ńṣọ̀ máa ń mú kí ìrora náà dín kù.Ṣíṣọ́ irú oúnjẹ téèyàn ń jẹ lè ràn èèyàn lọ́wọ́ láti kojú àrùn oríkèé ara ríro, nítorí pé téèyàn kò bá sanra jù, ìrora náà kò ní pọ̀ jù. Àwọn kan tún sọ pé jíjẹ àwọn oúnjẹ tó ní èròjà káṣíọ̀mù nínú bí ẹ̀fọ́, èso àti ẹja odò, tí kì í ṣe àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti fi ẹ̀rọ yí padà tí ọ̀rá inú wọn kò sì pọ̀ jù kò ní jẹ́ kéèyàn sanra jù, bẹ́ẹ̀ ni á sì dín ìrora kù. Lọ́nà wo? Àwọn kan sọ pé irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí ara ríbi wú. A tún gbọ́ pé ohun tó máa ń ṣiṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíì ni pé wọn kì í jẹ́ ẹran, wọ́n máa ń jẹ àwọn ohun tá a fi wàrà ṣe, àwọn oúnjẹ tí a fi àlìkámà ṣe àtàwọn èso bíi tòmátì, ànàmọ́, ata àti ìgbá.
Nígbà mìíràn, ó lè jẹ́ pé iṣẹ́ abẹ ló máa dára. Ńṣe ni oníṣẹ́ abẹ tó máa ṣe irú iṣẹ́ abẹ yìí á ki ohun èlò iṣẹ́ abẹ kan sínú oríkèé náà, tá á sì gé iṣan fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ orí oríkèé tó ń fa ìrora náà kúrò. Àmọ́, irú iṣẹ́ abẹ yìí kì í gbéṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí pé ó máa ń mú kí oríkèé ara wú padà lọ́pọ̀ ìgbà. Oríṣi iṣẹ́ abẹ mìíràn tún ni èyí tí wọ́n á pààrọ̀ gbogbo oríkèé ara náà (èyí tó sábàá máa ń jẹ́ ìgbáròkó tàbí eékún) tí wọ́n á sì fi òmíràn tó jẹ́ àtọwọ́dá rọ́pò rẹ̀. Irú iṣẹ́ abẹ yìí máa ń gbéṣẹ́ fún nǹkan bí
ọdún mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó sì máa ń mú ìrora rọlẹ̀ dáadáa.Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn dókítà ti bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn ọ̀nà ìtọ́jú tó túbọ̀ rọrùn, bíi fífi abẹ́rẹ́ fa irú omi kan tó máa ń mú kí awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó wà lóríkèé ara san kí wọ́n sì gún un sínú oríkèé tí àrùn náà ń bá jà. Eékún ni wọ́n ti sábàá ń ṣe eléyìí. Àwọn ìwádìí kan ní ilẹ̀ Yúróòpù fi hàn pé fífi abẹ́rẹ́ fa àwọn èròjà sínú oríkèé ara láti mú kí kèrékèré san (chondroprotective agents) ti gbéṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì sí egbòogi kan pàtó láti wo àrùn oríkèé-ara-ríro, ọ̀pọ̀ egbòogi wà tó ń mú kí ìrora lọ sílẹ̀ tí kò sì ní jẹ́ kí ara wú. Àwọn mìíràn kò sì ní jẹ́ kí àrùn náà tètè ráyè so èèyàn mọ́lẹ̀. Lára ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn egbòogi tí wọ́n fi ń wo àrùn oríkèé-ara-ríro tó ń sọni di hẹ́gẹhẹ̀gẹ ni àwọn egbòogi tó ń pa ìrora, egbòogi corticosteroid, àwọn egbòogi tí kò ní èròjà aleṣan nínú tí wọ́n fi ń gbógun ti ara wíwú, àwọn egbòogi tó ń wo làkúrègbé, àwọn egbòogi tó ń bá agbára ìdènà àrùn ṣiṣẹ́, àwọn egbòogi tó ń yí àbùdá padà àti oríṣi àwọn egbòogi àtọwọ́dá mìíràn tí wọ́n ṣe láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbára ìdènà àrùn. Àmọ́ ṣá, gbogbo àwọn oògùn yìí ló ní jàǹbá tí wọ́n ń ṣe fún ara. Ó kù sọ́wọ́ dókítà àti aláìsàn náà láti wo àwọn àǹfààní àti ewu tó wà níbẹ̀.
Ọgbọ́n wo làwọn kan tí àrùn oríkèé-ara-ríro ti hàn léèmọ̀, tí wọ́n sì ti kojú àrùn tó ń roni lára náà dá sí i?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jí! kò sọ pé irú ìtọ́jú báyìí, irú oògùn báyìí tàbí irú iṣẹ́ abẹ báyìí ló dára tàbí ni kò dára. Ẹrù iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan tó bá ní àrùn náà ni láti fara balẹ̀ wá ìtọ́jú èyíkéyìí tó bá fẹ́ kó sì gbé e yẹ̀ wò dáadáa.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
TÉÈYÀN BÁ SANRA JÙ, TÓ Ń MU SÌGÁ TÀBÍ TÉÈYÀN BÁ GBA Ẹ̀JẸ̀ SÁRA, Ó LÈ MÚ KÓ NÍ ÁRÙN LÀKÚRÈGBÉ TÓ Ń MÚ ORÍKÈÉ ARA WÚ
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
ÀWỌN ÌTỌ́JÚ MÌÍRÀN TÉÈYÀN LÈ GBÀ
Àwọn ìtọ́jú kan wà tó dà bí ẹni pé wọ́n dára, tí wọn kì í ṣeni lọ́ṣẹ́ bí àwọn ìtọ́jú ayé àtijọ́. Lára wọn ni lílo omi inú kèrékèré (oral type II collagen) èyí táwọn olùṣèwádìí kan sọ pé ó máa ń jẹ́ kí oríkèé ara tó wú rọlẹ̀ ó sì tún máa ń jẹ́ kí ìrora làkúrègbé tí ń mú oríkèé ara wú rọlẹ̀. Báwo ló ṣe ń ṣiṣẹ́? Kì í fàyè gba àwọn omi ara tó máa ń mú kí ara wú tí wọ́n sì máa ń ṣe jàǹbá fún ara tí wọ́n ń pè ní interleukin-1 àti tumor necrosis factor α. Àwọn èròjà àbáláyé bí i mélòó kan tún wà tí a gbọ́ pé wọn kì í fàyè gba àwọn omi ara tí kò dára wọ̀nyí. Lára wọn ni èròjà fitamin E, fitamin C, niacinamide, òróró ẹja tó ní èròjà eicosapentaenoic àti èròjà gammalinolenic nínú, òróró èso borage àti òróró òdòdó evening primrose. Ní ilẹ̀ China, ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ń lo egbòogi ìbílẹ̀ tí wọ́n ń fi igi kan tó dà bí àjàrà tí wọ́n ń pè ní Tripterygium wilfordii Hook F ṣe. A gbọ́ pé ó ti ṣiṣẹ́ gan-an fún kíkojú làkúrègbé tó ń mú oríkèé ara wú.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ORÍKÈÉ TÍ NǸKAN KAN KÒ ṢE
ÀPÒ OLÓMI
IṢAN
KÈRÉKÈRÉ
TÁN-ÁNNÁ
IBI TÍ EEGUN TI PÀDÉ
AWỌ FẸ́LẸ́FẸ́LẸ́ TÓ WÀ LÓRÍKÈÉ
EEGUN
OMI TÓ WÀ LÁRA AWỌ FẸ́LẸ́FẸ́LẸ́ ORÍKÈÉ
ORÍKÈÉ TÍ LÀKÚRÈGBÉ TÓ Ń MÚ ORÍKÈÉ ARA WÚ Ń BÁ JÀ
ÀLÀFO TÓ YẸ KÓ WÀ KÒ SÍ MỌ́
EEGUN ÀTI KÈRÉKÈRÉ TI BÀ JẸ́
AWỌ FẸ́LẸ́FẸ́LẸ́ ORÍKÈÉ TI WÚ
ÈÉRÚN KÈRÉKÈRÉ TÓ TI BÀ JẸ́
ORÍKÈÉ TÍ LÀKÚRÈGBÉ TÓ Ń SỌ EEGUN DI HẸ́GẸHẸ̀GẸ Ń BÁ JÀ
KÈRÉKÈRÉ TI BÀ JẸ́
EEGUN TI TA JÁDE
[Credit Line]
Ibi Tí A Ti Rí Àwòrán: Ẹgbẹ́ Tó Ń Rí sí Àrùn Oríkèé-Ara-Ríro
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àrùn oríkèé-ara-ríro lè mú ẹnikẹ́ni láìka ọjọ́ orí sí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ṣíṣe eré ìmárale àti jíjẹ oúnjẹ tó tọ́ lè dín ìrora náà kù