Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kó O Máa Kàwé Sókè Ketekete fún Ọmọ Rẹ?
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kó O Máa Kàwé Sókè Ketekete fún Ọmọ Rẹ?
“Ó rá gun orí itan mi. Ìwé rẹ̀ tó ti já jákujàku tó sì ti fi bọ́tà yí lára wà lọ́wọ́ rẹ̀ . . . , bẹ́ẹ̀ ló ń gbìyànjú láti sọ fún mi pé . . . , ‘Ẹ bá mi kà á, Dádì; ẹ bá mi kà á.’”—Ọ̀mọ̀wé Clifford Schimmels, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́.
ÀWỌN ọmọdé máa ń tètè lóye nǹkan. Ìwádìí fi hàn pé ìdàgbàsókè yíyára kánkán máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ọpọlọ àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọdún mẹ́ta. Àwọn ohun tí òbí máa ń ṣe fún àwọn ọmọ lójoojúmọ́ bíi kíkàwé, kíkọrin, àti fífìfẹ́ hàn sí wọn lè kó ipa pàtàkì nínú ìdàgbàsókè ọmọ kan lọ́nà tó dára. Àmọ́ o, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwádìí kan sọ, kìkì nǹkan bí ìdajì lára àwọn òbí tọ́mọ wọn wà láàárín ọdún méjì sí mẹ́jọ ló ń kàwé fáwọn ọmọ wọn lójoojúmọ́. O lè wá máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣé ohun gidi kan wà tí kíkàwé fún ọmọ mi lè ṣe fún un ni?’
Gbígbin Ìfẹ́ Láti Kàwé Sínú Wọn
Àwọn ògbógi dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, nǹkan gidi wà tó máa ṣe. Ìròyìn kan tí wọ́n pè àkọlé rẹ̀ ní Becoming a Nation of Readers sọ pé: “Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ láti mú ìmọ̀ tí àwọn ọmọ nílò láti ṣàṣeyọrí nínú ìwé kíkà dàgbà bí àkókò ti ń lọ ni kíkàwé sókè ketekete fún wọn. Ìgbà tí èyí sì ṣe pàtàkì jù ni ìgbà tí wọn ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ síléèwé.”
Bí àwọn ọmọ ṣe ń tẹ́tí sí àwọn ìtàn tí wọ́n ń kà fún wọn nínú ìwé, wọ́n máa ń mọ̀ láti kékeré pé àwọn lẹ́tà tí wọ́n ń kà jáde fún wọn bá ọ̀rọ̀ tá a ń sọ lẹ́nu mu. Òye èdè ìwé á tún yé wọn. Ìwé ìléwọ́ kan tó dá lórí kíkàwé sókè ketekete sọ pé: “Ìgbàkígbà tá a bá ti ń kàwé fún ọmọ kan, ńṣe ni a ń mú kí ọpọlọ ọmọ náà mọ ‘adùn’ kan. O tiẹ̀ tún lè pè é ní ọ̀nà ìpolówó kan, tó ń mú kí ọmọ náà mọ̀ pé ìgbádùn wà nínú ìwé kíkà tàbí ohun kan tá a tẹ̀ fún kíkà.” Àwọn òbí tó bá fún ọmọ wọn níṣìírí láti nífẹ̀ẹ́ sí ìwé á jẹ́ kí àwọn ọmọ náà fẹ́ràn láti máa kàwé jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé wọn.
Ríràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Lóye Àgbáyé Tó Yí Wọn Ká
Ẹ̀bùn kékeré kọ́ làwọn òbí tó bá ń kàwé fún àwọn ọmọ wọn máa fún wọn o, á jẹ́ kí wọ́n ní ìmọ̀ nípa àwọn ènìyàn, oríṣiríṣi àgbègbè àti onírúurú nǹkan. Láìsí pé ó ń ná wọn ní ohun púpọ̀, wọ́n lè “mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀” láyé látinú àwọn ìwé. Wo àpẹẹrẹ Anthony tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì, tí màmá rẹ̀ ti máa ń kàwé fún un látìgbà tó ti bí i. Màmá rẹ̀ sọ pé: “Ọjọ́ tó kọ́kọ́ lọ ṣèbẹ̀wò
sọ́gbà ẹranko, àtúnwò ló kàn jẹ́.” Àtúnwò kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí Anthony máa rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, kìnnìún, àgùnfọn, àtàwọn ẹranko mìíràn lójúkojú nìyẹn, ó ti mọ àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí tẹ́lẹ̀.Ìyá rẹ̀ tún ṣàlàyé síwájú sí i pé: “Anthony ti fi tìdùnnú-tìdùnnú pàdé àìmọye èèyàn, ẹranko, oríṣiríṣi àwọn nǹkan, ó sì ti ní oríṣiríṣi èrò lọ́kàn, inú ìwé ló sì ti mọ gbogbo wọn pátá láàárín ọdún méjì péré tó délé ayé.” Bẹ́ẹ̀ ni, kíkàwé sókè ketekete fún àwọn ọmọ nígbà tí wọ́n bá ṣì kéré lè fi kún òye wọn nípa ayé tí wọ́n ń gbé nínú rẹ̀.
Mímú Àjọṣe Tímọ́tímọ́ Dàgbà
Láàárín ìgbà táwọn ọmọ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà, wọ́n máa ń kọ́ àwọn ìṣesí kan tó máa nípa lórí bí wọ́n á ṣe máa hùwà lọ́jọ́ iwájú. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òbí gbọ́dọ̀ fi ìpìlẹ̀ tí àjọṣe rẹ̀ á wà tímọ́tímọ́ lélẹ̀, èyí tá á fi ìgbẹ́kẹ̀lé, ọ̀wọ̀ tọ̀tún-tòsì, àti lílóye ara ẹni hàn. Kíkàwé fún wọn lè jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó máa mú kí ìyẹn ṣeé ṣe.
Nígbà táwọn òbí bá wá àyè láti gbé àwọn ọmọ wọn mọ́ra tí wọ́n sì ń kàwé fún wọn, ohun tí wọ́n ń sọ ní kedere ni pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ.” Phoebe, abiyamọ kan ní Kánádà sọ́ nípa kíkàwé fún ọmọ rẹ̀ tó ti pé ọmọ ọdún mẹ́jọ báyìí pé: “Èmi àti ọkọ mi mọ̀ pé bí Nathan ṣé sún mọ́ wa tímọ́tímọ́ kò ṣẹ̀yìn kíkà tí a ń kàwé fún un. Kì í fi ohun kankan pa mọ́ fun wa ó sì máa ń sọ bí nǹkan bá ṣe rí lára rẹ̀ fún wa. Ó ti mú wa wà pa pọ̀ gan-an ni.”
Cindy ti sọ ọ́ dàṣà láti máa kàwé sókè ketekete fún ọmọbìnrin rẹ̀ látìgbà tó ti wà ní bí ọmọ ọdún kan ó sì ti gbọ́n tó láti jókòó kó sì tẹ́tí sílẹ̀ fún bí ìṣẹ́jú kan tàbí méjì. Ǹjẹ́ gbogbo àkókò àti ìsapá náà tiẹ̀ mú àṣeyọrí kankan jáde? Cindy sọ pé: “Bá a ṣe máa ń fi ọ̀yàyà kàwé pẹ̀lú rẹ̀, tá a kì í jágbe mọ́ ọn lohun tá a nílò lọ́pọ̀ ìgbà láti mú kí Abigail máa sọ tinú rẹ̀ jáde fún wa nípa ohun tó bá ṣẹlẹ̀ níléèwé tàbí àwọn ìṣòro tó bá ní pẹ̀lú ọ̀rẹ́. Òbí wo ni kò ní fẹ́ irú ìyẹn?” Ó dájú pé, kíkàwé sókè lè yọrí sí àjọṣe tímọ́tímọ́ láàárín òbí àti ọmọ.
Gbígbin Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé sí Wọn Lọ́kàn
Ìwé 3 Steps to a Strong Family sọ pé: “Lónìí, ìkókúkòó táwọn ọmọ wa ń kó sí ọpọlọ látinú tẹlifíṣọ̀n àti láwọn ibòmíì ti pọ̀ jù débi pé, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, wọ́n nílò ohun tó lè ṣe ọpọlọ wọn lóore, tó lè mú wọn ronú lọ́nà tó já gaara, tó lè fún wọn ní ọgbọ́n, àti ọ̀nà ìrònú kan tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti hùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tó dára kí wọ́n sì gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó bójú mu.” Àwọn òbí gan-an ló ni ẹrù iṣẹ́ náà láti ní ipa tó gbámúṣé tó sì wúlò lórí àwọn ọmọ wọn.
Jíjẹ́ kí ọmọ mọ̀ ju ẹyọ ọ̀rọ̀ kan lọ kó sì dá àwọn gbólóhùn tó nítumọ̀ mọ̀ nínú ìwé lè jẹ́ irinṣẹ́ wíwúlò fún kíkọ́ ọmọ láti mọ ọ̀rọ̀ ọ́ sọ àti láti mọ̀wéé kà. Dorothy Butler tó ṣe ìwé Babies Need Books sọ pé: “Bí ẹnì kan á ṣe mọ inú rò sí sinmi lórí bí èdè rẹ̀ bá ṣe já gaara sí. Láìsí àní-àní, èdè ṣe pàtàkì gan-an tá a bá ń sọ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àti níní làákàyè.” Mímọ bá a ti ń báni sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára ṣe kókó fún àjọṣe tó dán mọ́rán.
Kíka àwọn ìwé tó bójú mu tún lè fi kún híhu ìwà rere àti ìwà ọmọlúwàbí. Àwọn òbí tó ń kàwé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn tí wọ́n sì ń bá wọn ronú pọ̀ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ bí èèyàn ṣe ń yanjú ìṣòro. Bí Cindy bá ń kàwé pẹ̀lú
ọmọbìnrin rẹ̀, Abigail, ó máa ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kíyè sí bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn náà ṣe rí lára Abigail. “Gẹ́gẹ́ bí òbí, ó ṣeé ṣe fún wa láti mọ̀ nípa àwọn ìṣesí kan tó kù díẹ̀ káàtó nínú ìwà rẹ̀ ká sì gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́ láti tètè mú irú ìrònú tí kò tọ̀nà bẹ́ẹ̀ kúrò nígbà tó ṣì wà ní kékeré.” Lódodo, kíkàwé sókè ketekete fún àwọn ọmọ lè sọ èrò inú wọn àti ọkàn wọn di olóye.Mú Kí Ìwé Kíkà Gbádùn Mọ́ Wọn
“Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́” ni kó o máa fi kàwé fún wọn, jẹ́ kí àkókò náà tù wọ́n lára, má fi dandan lé e, sì jẹ́ kó gbádùn mọ́ wọn. Àwọn òbí tó lóye mọ̀gbà tó yẹ káwọn dáwọ́ kíkàwé dúró. Lena sọ pé: “Nígbà mìíràn á ti rẹ Andrew tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì kò sì ní lè jókòó jẹ́ẹ́ lọ títí. A máa ń dín àkókò tá a fi ń kàwé kù kó lè bá a lára dé. A ò fẹ́ kí Andrew bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra ìwé kíkà, nítorí náà, a kì í fi ọ̀ràn-an-yàn mú un ju bí agbára rẹ̀ bá ṣe gbé e lọ.”
Kíkàwé sókè ketekete kọjá wíwulẹ̀ máa pe ohun tó wà nínú ìwé. Mọ àkókò tó yẹ kó o ṣi ibi tí àwòrán wà nínú ìwé náà kínú ọmọ náà lè máa dùn láti túbọ̀ gbọ́ sí i. Kà á kó já gaara. Lílo ohùn òkè, ohùn ìsàlẹ̀ àti ohùn àárín àti títẹnumọ́ àwọn kókó tún lè mú kí ìtàn náà gbádùn mọ ọn gan-an ni. Ohùn rẹ tí ń tuni lára lè túbọ̀ fi ọmọ rẹ lọ́kàn balẹ̀.
Àwọn àǹfààní tó wà nínú rẹ̀ á ti lọ ga jù tí ọmọ rẹ pẹ̀lú bá ń kópa nínú rẹ̀. Máa dánu dúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kó o sì máa béèrè àwọn ìbéèrè tó máa lè dáhùn fúnra rẹ̀ bó ṣe fẹ́. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn tí ọmọ rẹ mú wá nípa ṣíṣe àwọn àlàyé mìíràn tó tún lè wúlò.
Ṣọ́ Irú Ìwé Tí Wàá Máa Kà fún Un
Àfàìmọ̀ ni kò ní jẹ́ pé kókó tó ṣe pàtàkì jù lọ ni yíyan ìwé tó dára fún kíkà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń béèrè pé kó o ti kọ́kọ́ wá wọn rí. Yẹ àwọn ìwé wò dáadáa, kó o sì lo kìkì àwọn tí wọ́n ní ohun tó wúlò nínú, tí wọ́n ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ní àwọn ìtàn tó ń sọ nípa ìwà rere. Wo èèpo ẹ̀yìn wọn wò dáadáa, àwòrán inú wọn, àtàwọn ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú wọn. Yan àwọn ìwé tó máa gbádùn mọ òbí àti ọmọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, oríṣi ìtàn kan náà ni àwọn ọmọ á máa sọ pé kí wọ́n máa kà fún wọn léraléra.
Àwọn òbí káàkiri ayé mọrírì Iwe Itan Bibeli Mi lọ́pọ̀lọpọ̀. a Wọ́n ṣe é fáwọn òbí láti máa kà á pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn kéékèèké, kì í ṣe pé ó lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti di ẹni tó mọ̀wéé kà dáadáa nìkan ni, àmọ́ ó tún máa ń mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì.
Àwọn òbí tó ń kàwé fún àwọn ọmọ wọn lè gbin àṣà kíkàwé lọ́nà tó dára sí wọn nínú, èyí tó lè mú àṣeyọrí pàtàkì wá jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé wọn. JoAnne sọ nípa ọmọbìnrin rẹ̀ pé: “Kì í ṣe pé Jennifer ti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà kó tó bẹ̀rẹ̀ iléèwé, tó sì tún nífẹ̀ẹ́ gan-an sí kíkàwé nìkan ni, àmọ́ olórí ohun tó wà níbẹ̀ ni pé, ó ti kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà. Jennifer ti kọ́ láti gbára lé Bíbélì, tí í ṣe àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, láti máa tọ́ ọ nínú gbogbo ìpinnu tó bá fẹ́ ṣe.” Òótọ́ ni, ohun tó o kọ́ ọmọ kan láti nífẹ̀ẹ́ sí lè ṣe pàtàkì ju ohun tó o kọ́ ọ láti mọ̀ lọ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Tó O Bá Ń Kàwé fún Ọmọ Rẹ
• Bẹ̀rẹ̀ nígbà tó ṣì wà ní ìkókó.
• Fún ọmọ rẹ̀ láyè kí ara rẹ̀ balẹ̀ kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í kàwé.
• Àwọn ìtàn tí ẹ̀yin méjèèjì bá fẹ́ràn ni kó o máa kà fún un.
• Máa kàwé fún un ní gbogbo ìgbà kó o sì jẹ́ kí ohùn rẹ bá bí ìtàn náà ṣe rí mu.
• Jẹ́ kí ọmọ rẹ máa dá sí i nípa bíbi í ní àwọn ìbéèrè.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
Fọ́tò tí wọ́n yà ní Ọgbà Ẹranko Conservation Society’s Bronx