Wíwo Ayé
Wíwo Ayé
Àwọn Igbó Kìjikìji
Ní Íńdíà, ìpínlẹ̀ Kerala tó wà ní ìhà gúúsù nìkan ni wọ́n mọ̀ tẹ́lẹ̀ tí igbó kìjikìji wà. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìwé ìròyìn New Delhi náà Down to Earth, ròyìn pé, onímọ̀ nípa àyíká, Saumyadeep Dutta lọ kan igbó kìjikìji kan tó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kìlómítà níbùú àti lóòró lápá ìlà oòrùn sí apá àríwá ìpínlẹ̀ Assam àti Arunachal Pradesh. Onírúurú ẹranko ìgbẹ́ ló wà nínú igbó kìjikìji náà, bí “oríṣi ẹranko afọ́mọlọ́mú méjìlélọ́gbọ̀n àti ọ̀tàlérúgba oríṣiríṣi ẹyẹ, ọ̀wọ́ àwọn ẹranko tó ṣọ̀wọ́n bí erin, ẹkùn, àmọ̀tẹ́kùn, akika China, bíárì ayọ́kẹ́lẹ́, ìgalà, ìnàkí, ẹyẹ kalij pheasant, ẹyẹ àkàlà, àti pẹ́pẹ́yẹ oko.” Síbẹ̀, ìwé ìròyìn Down to Earth sọ pé bí àwọn èèyàn ṣe nílò àwọn igi inú igbó níbi gbogbo kárí ayé ń kó ọ̀pọ̀ igbó kìjikìji sínú ewu. Àwọn onímọ̀ nípa àwọn nǹkan àbáláyé ti bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù pé tí wọ́n bá lọ gé àwọn igi yìí tán, a jẹ́ pé kò ní sí àwọn igbó kìjikìji mọ́ nìyẹn, yóò sì di èyí tí wọ́n á máa lò fún iṣẹ́ àgbẹ̀ nìkan.
Bíbú Ẹkùn
Kí ló dé tí àyà ènìyàn àtẹranko fi máa ń là gààrà nígbà tí ẹkùn bá bú? Ìwé ìròyìn The Sunday Telegraph ti London sọ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti Ilé Ẹ̀kọ́ fún Ètò Ìbánisọ̀rọ̀ Nípa Ẹranko ní Àríwá Carolina, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà “ti ṣèwádìí pé ẹkùn máa ń dún àwọn dídún kan téèyàn kì í gbọ́ torí pé dídún yìí kì í ròkè. Ẹranko náà á wá da dídún abẹ́nú yìí pọ̀ mọ́ bíbú rẹ̀ èyí tí ààrẹ ilé ẹ̀kọ́ náà Elizabeth von Muggenthaler sọ pé èèyàn lè gbọ́ táa sì mú kí àyà èèyàn là gààràgà.” Kódà àwọn tó ti ń tọ́jú ẹkùn tipẹ́ ti nírìírí ohun àràmàǹdà yìí.
Fífi Ìgbì Alágbára Mú Ẹran Rọ̀
Ohun èèlò kan tí wọ́n fi máa ń lu ẹran tó bá yi títí táá fi rọ̀ tàbí àwọn nǹkan gbẹrẹfun kan tó ní àwọn èròjà tó ń mú kí ẹran rọ̀ làwọn olóúnjẹ sábàá máa ń lò láti mú kí ẹran tó bá yi tíṣọ́ntíṣọ́n rọ̀. Àmọ́ ṣá, ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé àwọn olùwádìí ní Maryland, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti ń ṣe àwọn àyẹ̀wò kan nípa lílo ìgbì alágbára. Àwọn olùwádìí náà fi ẹran sínú abọ́ onípáànù wọ́n sì gbé e sínú ike kan tí omi kúnnú rẹ̀. Wọ́n wá tanná ran ọ̀pá ohun abúgbàù kan nínú ike náà, ìyẹn sì dáhùn. Ìròyìn ọ̀hún sọ pé “omi yìí wá mú kí ìgbì alágbára náà lọ káàkiri inú ẹran náà ó sì mú kó rọ̀ àmọ́ ńṣe ló fọ́ ike náà yángá.” Yàtọ̀ fún pé ó mú kí ẹran náà rọ̀, ó tún máa ń pa àwọn kòkòrò tín-tìn-tín tó ń fa àrùn, irú bíi E. Coli, tó máa ń fa májèlé inú oúnjẹ. Síbẹ̀, Randy Huffman tó wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Nípa Ẹran Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Olórí ìṣòro tó wà níbẹ̀ ni báa ṣe máa sọ ọ́ dòun.”
Àwọn Ọkọ̀ Òkun Ń Tan Àrùn Kálẹ̀
Ìwé ìròyìn The Daily Telegraph ti London sọ pé, “omi kan tó máa ń wà nínú ọkọ̀ òkun tí kì í jẹ́ kó fì síbí fì sọ́hùn-ún ti bẹ̀rẹ̀ sí tan àrùn kálẹ̀ kárí ayé o, ó sì ń kó èèyàn àtẹranko àtàwọn nǹkan ọ̀gbìn sínú ewu.” Àwọn ọkọ̀ òkun máa ń lo omi yìí kí wọ́n má bàa máa fì síbí sọ́hùn-ún, wọ́n á sì dà á nù lójú òkun tàbí tí wọ́n bá dé èbúté. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àwọn olùwádìí láti Ilé Iṣẹ́ Ìṣèwádìí Nípa Àyíká ní Smithsonia, Maryland, ti rí i pé omi yìí táwọn ọkọ̀ òkun máa ń gbé ní àwọn kòkòrò tín-tìn-tín tó ń fa àrùn lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ. Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fún ọkọ̀ òkun mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní Chesapeake Bay fi hàn pé gbogbo wọn pátápátá ló ní kòkòrò tó ń fa àrùn onígbáméjì. Lítà kan omi yìí ní nǹkan bí ọgbọ̀n lé lẹ́gbẹ̀rin [830] mílíọ̀nù kòkòrò bakitéríà àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin ó lé irínwó [7,400] mílíọ̀nù kòkòrò fáírọ́ọ̀sì, èyí sì fi ìgbà mẹ́fà sí mẹ́jọ pọ̀ ju iye àwọn kòkòrò mìíràn lọ.
Ohun Ìṣiré Ti Pọ̀ Jù
Ìwé ìròyìn The Sunday Times ti London sọ pé “ìwádìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe fi hàn pé àwọn ọmọdé kì í fi bẹ́ẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe ń ṣeré gidi mọ́ o, nítorí àwọn ohun ìṣiré tí wọ́n ń fún wọn ti pọ̀ jù.” Ara ohun tó mú kí wọ́n ṣe ìwádìí náà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni bí “àwọn òbí kò ṣe ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, dípò bẹ́ẹ̀ tí wọ́n á kó àwọn ohun ìṣiré fún wọn, tí wọ́n á sì ní kí wọ́n máa fi kọ̀ǹpútà ṣeré kí wọ́n sì máa wo tẹlifíṣọ̀n.” Lẹ́yìn tí wọ́n ṣàyẹ̀wò ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àwọn ọmọ ọlọ́dún mẹ́ta sí márùn-ún, Ọ̀jọ̀gbọ́n Kathy Sylva ti Yunifásítì Oxford parí ọ̀rọ̀ pé: “Tí wọ́n bá ní àwọn ohun ìṣiré tó pọ̀ jàńtìrẹrẹ, ó dà bí ẹni pé ohun kan máa ń pín ọkàn wọn níyà, àwọn ọmọdé ò sì lè mọ báa ti ń ṣeré dáadáa bí ohunkóhun bá pín ọkàn wọn níyà.”
Ìsoríkọ́ Níbi Iṣẹ́
Ìwé ìròyìn The Guardian ti London sọ pé: “Àníyàn níbi iṣẹ́, kí gbogbo nǹkan máa sú èèyàn àti ìsoríkọ́ ti ń lọ sókè gidi gan-an.” Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé ti
Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe sọ, ó tó mẹ́ta nínú mẹ́wàá àwọn òṣìṣẹ́ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ní àìlera ọpọlọ, nígbà tí ìròyìn sì sọ pé ọ̀kan nínú mẹ́wàá àwọn òṣìṣẹ́ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló ní ìsoríkọ́ tó lékenkà. Ìsoríkọ́ ló fa ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín méje nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó fẹ̀yìn tì láìtọ́jọ́ ní Jámánì. Iye tó ju ìdajì àwọn òṣìṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Finland ni àwọn àrùn tó jẹ mọ́ másùnmáwo ń dà láàmú. Ní Poland, hílàhílo tí àìríṣẹ́ṣe tó ń ròkè sí i ń fà, fi ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè ní 1999, bẹ́ẹ̀ sì ni fífọwọ́ ẹni gbẹ̀mí ara ẹni náà ròkè. Ìròyìn náà sọ pé pẹ̀lú bí wọ́n ṣe túbọ̀ wá ń lo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tuntun níbi iṣẹ́, tí wọ́n sì ń fi àwọn ọ̀nà tuntun ṣàbójútó iṣẹ́ báyìí, ìsoríkọ́ máa ròkè gan-an. Ó wá ṣèkìlọ̀ pé “tó bá fi máa di ọdún 2020, másùnmáwo àti àìlera ọpọlọ á pọ̀ ju jàǹbá ọkọ̀ lọ, àrùn Éèdì àti ìwà ipá ló sì máa jẹ́ àkọ́kọ́ lára àwọn ohun tó ń fa fífi àkókò iṣẹ́ ṣòfò.”Iye Owó Tí Ìwà Ipá Ń Náni Ń Ròkè Sí I
Ìwé ìròyìn The Independent ti London sọ pé: “Ìwà ipá ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Wales ń ná àwùjọ ní bílíọ̀nù márùnlélọ́gọ́rin dọ́là lọ́dún.” Iye yìí tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Abẹ́lé sọ pé kò tó nǹkan kó iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín méje nínú ọgọ́rùn-ún àpapọ̀ owó tó ń wọlé fún orílẹ̀-èdè náà. Ìpànìyàn yálà èyí táa mọ̀ọ́mọ̀ ṣe tàbí tí a kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ni ìwà ipá tówó tó ń ná wọn pọ̀ gan-an ju tàwọn tó kù lọ, iye tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ ń ná orílẹ̀-èdè náà lé ní mílíọ̀nù kan dọ́là ní ìpíndọ́gba, nígbà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwà ọ̀daràn mìíràn ń lọ sí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27,000] dọ́là ní ìpíndọ́gba. Iye tó ń bá èrú àti ìwà awúrúju lọ jẹ́ ìdá kan nínú mẹ́rin gbogbo owó náà. Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé iye yìí kò mọ́ “iye tí ìbẹ̀rù ìwà ipá ń náni, ipa tó ní lórí ìdílé àwọn tó ṣẹlẹ̀ sí, owó tí Ìjọba ná láti fòpin sí ìwà ipá, . . . tàbí iye tó ń ná àjọ abánigbófò.”
Àwọn Èpò Ń Ṣiṣẹ́ Ju Oògùn Apakòkòrò
Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé èpò làwọn àgbẹ̀ tó wà ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà ń lò dípò oògùn apakòkòrò láti mú kí àgbàdo wọn túbọ̀ ṣe dáadáa sí i. Oríṣi nǹkan méjì tó ń pa irè oko ló ń han àwọn àgbẹ̀ alágbàdo ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà léèmọ̀. Ọ̀kan ni oríṣi àfòmọ́ kan tó ń jẹ́ Striga, ó máa ń ba àgbàdo tí owó rẹ̀ tó bílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là jẹ́ lọ́dọọdún. Olùwádìí ará Kẹ́ńyà náà Ziadin Khan, ti ṣàwárí pé béèyàn bá gbin èpò kan tí wọ́n ń pè ní desmodium sáàárín poro oko, àfòmọ́ yìí kò ní ráyè hù. Ohun kejì tó máa ń ba irè oko jẹ́ ni kòkòrò tó máa ń lu ihò sára nǹkan ọ̀gbìn, ọ̀pọ̀ ọdún ló sì máa ń ba ìpín kan nínú mẹ́ta àgbàdo jẹ́. Àmọ́ ṣá, Khan tí ṣàwárí pé àwọn kòkòrò tó máa ń lu ihò sára irè yìí fẹ́ràn láti máa jẹ koríko kan tó ń jẹ́ èésún. Báwọn àgbẹ̀ bá gbin koríko yìí sínú oko wọn àwọn kòkòrò wọ̀nyí kì í ya ìdí àgbàdo wọn mọ́. Omi kan tó máa ń lẹ̀ tìpẹ̀tìpẹ̀ tó ń jáde lára koríko yìí máa ń lẹ̀ mọ́ àwọn kòkòrò náà, wọ́n á sì kú. Khan wá sọ pé: “Ó dára ju oògùn apakòkòrò lọ, kò sì wọ́n rárá. Ó sì ti mú kí irè oko pọ̀ sí i ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà tó fi ìpín ọgọ́ta sí àádọ́rin lórí ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i.”
Jìbìtì Awalẹ̀pìtàn
Ọ̀kan lára àwọn ògbóǹkangí awalẹ̀pìtàn ilẹ̀ Japan tí wọ́n sọ pé òun ni awalẹ̀pìtàn tó tíì ṣe dáadáa jù lọ nítorí àwọn àwárí tó kàmàmà tó ti ṣe ló ti wà lákọọ́lẹ̀ báyìí pé ó ṣe awúrúju. Kámẹ́rà fídíò kan táwọn oníwèé ìròyìn Mainichi Shimbun kẹ́ sílẹ̀ ló ya ọ̀gbẹ́ni yìí níbi tó ti ń ri àwọn òkúta ìṣẹ̀ǹbáyé kan mọ́lẹ̀ ní ibùdó àwọn awalẹ̀pìtàn kan kí ikọ̀ tó ń walẹ̀ tó débẹ̀. Nígbà tí awalẹ̀pìtàn náà rí i pé gbangba ti dẹkùn, ló bá jẹ́wọ́ pé lára àwọn ohun tóun ti wà jáde tẹ́lẹ̀ rí lòun ń rì mọ́lẹ̀. Ní báyìí, gbogbo àbájáde iṣẹ́ tó ti ṣe fún odidi ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn ló wà lábẹ́ àyẹ̀wò. Àwọn tó ń ṣèwé jáde ti sọ pé àwọn máa ṣàtúnṣe àwọn ìwé táwọn tó ń ṣèwádìí nípa ìwalẹ̀pìtàn kọ àtàwọn ìwé tí wọ́n ń lò nílé ẹ̀kọ́ nítorí ọ̀rọ̀ náà.
Jàǹbá Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Ọmọdé
Ìwádìí kan tí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ṣe ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n fi hàn pé jàǹbá ni olórí ohun tó ń fa ikú àwọn ọmọdé láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ jù lọ. Ìwé ìròyìn Mainichi Daily News ti Japan sọ pé: “Fífara pa ló ń ṣokùnfà nǹkan bí ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún ikú àwọn ọmọ ọlọ́dún kan sí mẹ́rìnlá láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣàyẹ̀wò,” èyí ló sì ń fa ikú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún lọ́dọọdún. Àwọn ohun tó ń mú kó túbọ̀ ṣeé ṣe kí jàǹbá ṣe àwọn ọmọdé ni ipò òṣì, kí òbí kan nìkan máa tọ́mọ, kí ìdílé tóbi gan-an, àti pé kí àwọn òbí máa lo oògùn olóró tàbí kí wọ́n ya ọ̀mùtí. Àjọ UNICEF wá pàrọwà pé káwọn èèyàn fọwọ́ gidi mú ọ̀rọ̀ “àwọn ohun ìdáàbòbò tó jíire, àwọn nǹkan bí: àṣíborí, dídín eré sísá ọkọ̀ ìrìnnà kù láwọn àgbègbè téèyàn bá wà, àwọn ìjókòó tó ń dáàbò bo ọmọdé nínú ọkọ̀ ìrìnnà, bẹ́líìtì ààbò nínú ọkọ̀ ìrìnnà, àwọn ìdérí agolo oògùn tọ́mọdé kò ní lè ṣí, káwọn ẹ̀rọ tó ń kófìrí èéfín máa wà nínú ilé, àti pé kí ibi ìṣeré jẹ́ èyí tó láàbò.”