Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Oògùn—Ta Ló Ń Lò Ó?

Oògùn—Ta Ló Ń Lò Ó?

Oògùn—Ta Ló Ń Lò Ó?

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ GÚÚSÙ AFÍRÍKÀ

“GBOGBO èèyàn ló ń loògùn.” Wọ́n lè fi gbólóhùn tó gbajúmọ̀ yìí tan ẹnì kan tí kò tíì tọ́ oògùn olóró wò rí láti ṣe bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ọ̀rọ̀ kúkú ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yẹn, àmọ́ ó sinmi lórí irú “oògùn” táa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Bí wọ́n ṣe ṣàpèjúwe “oògùn tó ń rani níyè” ni pé: “Ó jẹ́ kẹ́míkà èyíkéyìí, ì báà jẹ́ àbáláyé tàbí èyí táwọn èèyàn ṣe tó bá ṣáà ti lè ra èèyàn níyè, tó lè yí ìmọ̀lára èèyàn padà tàbí kó mú kéèyàn máa ròròkurò tàbí hùwàkiwà.” Àpèjúwe yẹn dára, ó sì bá àwọn oògùn tó máa ń nípa lórí ìrònú àti ìṣesí èèyàn mu, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò kan ọ̀pọ̀ egbòogi tí wọ́n fi ń wo àìsàn.

Níbàámu pẹ̀lú àpèjúwe yẹn, ọtí líle jẹ́ ọ̀kan lára irú oògùn bẹ́ẹ̀. Ibi tí ewu wà ni lílò ó lálòjù, èyí tó jẹ́ ìṣòro kan tí ń gbèèràn lásìkò táa wà yìí. Ìwádìí tí wọ́n ṣe láwọn kọ́lẹ́ẹ̀jì àtàwọn yunifásítì ní orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé kan fi hàn pé “ọtí àmuyíràá ni ìṣòro àṣìlò oògùn tó ga jù lọ láàárín àwọn ọmọ yunifásítì.” Ìwádìí náà fi hàn pé ìpín mẹ́rìnlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló ń mutí àmuyíràá. a

Bí ọtí líle ṣe wà káàkiri ni tábà náà wà káàkiri, òfin ò sì kà á léèwọ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé èròjà olóró tí wọ́n ń pè ní nicotine wà nínú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ti sọ, sìgá mímu ń pa nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn lọ́dún. Síbẹ̀, àwọn tó lọ́rọ̀, táwọn èèyàn ń wárí fún láwùjọ ni bàbá ìsàlẹ̀ nídìí òwò tábà. Sìgá mímu tún máa ń yára di bára kú, kódà, ju àwọn oògùn mìíràn tí kò bófin mu lọ.

Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti fòfin de pípolówó tábà tí wọ́n sì ti ṣe àwọn òfin mìíràn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń wo sìgá mímu bí ohun kan tó bẹ́gbẹ́ mu. Àwọn ilé iṣẹ́ sinimá ń gbé sìgá mímu lárugẹ bí nǹkan tó gbayì. Ìwádìí kan tí Yunifásítì California kan ní San Francisco ṣe lórí àwọn fíìmù tó mówó wọlé jù lọ láàárín ọdún 1991 sí 1996 fi hàn pé, ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin tí wọ́n kó ipa pàtàkì nínú àwọn eré náà ni wọ́n mu sìgá.

Àwọn Oògùn Tó Bófin Mu Tó Sì Ń Ṣèèyàn Láǹfààní Ńkọ́?

Ó dájú pé àwọn egbòogi ti ṣe ọ̀pọ̀ láǹfààní, àmọ́ èèyàn lè ṣì wọ́n lò. Nígbà mìíràn, àwọn dókítà lè yára fún èèyàn lóògùn tàbí kí aláìsàn fúngun mọ́ wọn tí wọ́n á fi ní kó lọ lo àwọn oògùn tí kò pọndandan. Oníṣègùn kan sọ pé: “Àwọn dókítà kì í fìgbà gbogbo fara balẹ̀ láti ṣàwárí ohun tó ń ṣe aláìsàn. Ó rọrùn láti sọ pé, ‘Gba oògùn yìí.’ Àmọ́ ohun tó jẹ́ ìṣòro náà gan-an á ṣì wà níbẹ̀.”

Kódà, béèyàn bá ṣi àwọn egbòogi pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó ń pa ìrora bí aspirin àti paracetamol (Tylenol, Panadol) lò, ó lè yọrí sáwọn ìṣòro àìlera tó lágbára. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì èèyàn tó ń kú lọ́dọọdún nítorí ṣíṣi paracetamol lò.

Gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe táa ṣe ṣáájú, èròjà kaféènì tó wà nínú tíì àti kọfí pẹ̀lú máa ń nípa lórí iyè wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í kà á sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ nígbà táa bá ń mu tíì tàbí kọfí láàárọ̀. Kò tiẹ̀ ní bọ́gbọ́n mu ká máa fojú egbòogi olóró bí heroin wo tíì tàbí kọfí táwọn èèyàn ń lò déédéé. Ńṣe ló máa dà bí kéèyàn máa fi ológbò inú ilé wé kìnnìún olóólà ijù. Àmọ́ ṣá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ògbóǹkangí nípa ìlera ti sọ, bóo bá ń mu ife kọfí márùn-ún tàbí ife tíì mẹ́sàn-án lójúmọ́, ó lè pa ọ́ lára. Síwájú sí i, ká ní iye tóo ń mu tẹ́lẹ̀ pọ̀ gan-an tóo wá dín-in kù lójijì, o lè bẹ̀rẹ̀ sí bì, kórí máa fọ́ ẹ gan-an, kí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ sì máa dà ẹ́ láàmú bíi ti obìnrin kan báyìí tó dín iye tíì tó ń mu kù lójijì.

Lílo Àwọn Oògùn Olóró Ńkọ́?

Ọ̀rọ̀ tó tún ń fa awuyewuye báyìí ni ti lílo oògùn olóró lágbo eré ìdárayá. Ìdíje Tour de France tó wáyé lọ́dún 1998 ló túbọ̀ gbé èyí sáyé, nígbà tí wọ́n yọ àwọn agunkẹ̀kẹ́ mẹ́sàn-án nínú ikọ̀ kan tó ń gbégbá orókè bí ẹni yọ jìgá torí pé wọ́n lo oògùn olóró. Onírúurú ọgbọ́n làwọn eléré ìdárayá ti hùmọ̀ kọ́wọ́ má bàa tẹ̀ wọ́n tí wọ́n bá ń ṣe àyẹ̀wò fún wọn. Ìwé ìròyìn Time sọ pé àwọn kan tiẹ̀ ti báa débi pé wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ “ ‘ìpààrọ̀ ìtọ̀,’ ìyẹn ni pé wọ́n á jẹ́ kí wọ́n fi rọ́bà fa ìtọ̀ ẹnì kan tí kò loògùn olóró sínú àpòòtọ̀ tiwọn, èyí sì máa ń mú ìrora dání lọ́pọ̀ ìgbà.”

A ò tíì mẹ́nu ba àwọn oògùn olóró tó ń dáyà foni táwọn èèyàn fi ń “ṣeré ìnàjú” o. Àwọn bíi igbó (marijuana), àti oríṣiríṣi àwọn oògùn líle mìíràn, àwọn oògùn amóríyá (bíi kokéènì àti amphetamines), àtàwọn apaniníyè (bí egbòogi amárarọni), àti heroin. A ò sì gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn kan tí wọ́n ń fà ságbárí, bíi glue àti gasoline, tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èwe. Òótọ́ ni pé wọn ò fòfin de àwọn tí wọ́n ń fà ságbárí yìí wọ́n sì wà káàkiri.

Èrò tó wọ́pọ̀ pé ńṣe làwọn ajoògùnyó máa ń rù hangogo tí wọ́n á máa ki abẹ́rẹ́ oògùn olóró bọnú iṣan ara wọn nínú iyàrá jáujàu kan lè tanni jẹ. Ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti sọ oògùn líle di bára kú ṣì máa ń dà bíi tàwọn èèyàn gidi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sọ́gbọ́n kí oògùn líle tí wọ́n ń lò má nípa lórí ìgbésí ayé wọn dé àyè kan. Síbẹ̀, a ò lè gbójú fo ọṣẹ́ tí oògùn olóró ń ṣe dá. Òǹkọ̀wé kan ṣàpèjúwe bí àwọn kan tó ń lo kokéènì ṣe “máa ń fa oògùn olóró sára wọn láìmọye ìgbà láàárín àkókò kúkúrú, tí wọ́n á ti fi abẹ́rẹ́ gún ara wọn ṣákaṣàka, tí gbogbo ara wọn á sì máa ṣẹ̀jẹ̀.”

Lẹ́yìn tí lílo oògùn tí kò bófin mu ti lọ sílẹ̀ dáadáa lópin àwọn ọdún 1980, ó tún ti bẹ̀rẹ̀ sí gbèèràn káàkiri ayé. Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Àwọn aláṣẹ ò mọ ohun tí wọ́n á ṣe sọ́ràn fàyàwọ́ oògùn olóró tó ń ròkè sí i, àti báwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń lò ó lóríṣiríṣi tí kò sì wá sí owó àti ìsọfúnni láti lè kojú rẹ̀.” Ìwé ìròyìn The Star ti Johannesburg, Gúúsù Áfíríkà, sọ pé ní ìbámu pẹ̀lú ìṣirò tí ìjọba ṣe, “ẹnì kan nínú mẹ́rin lára àwọn tó ń gbé ní Gúúsù Áfíríkà ló ti sọ ọtí líle tàbí oògùn olóró di bárakú.”

Ilé Ẹ̀kọ́ fún Ìdàgbàsókè Gbogbo Gbòò ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fi yéni pé “àwọn tó ń ṣe oògùn olóró àtàwọn tó ń ṣe fàyàwọ́ rẹ̀ ti ṣètò ara wọn káàkiri ayé wọ́n sì ti fi iye tó jọjú lára owó tùùlù-tuulu tí wọ́n ń jèrè nínú òwò oògùn olóró pamọ́ sáwọn báńkì àtàwọn ilé iṣẹ́ ìdókòwò níbi tówó wọn á ti máa mú èrè tàbùà-tabua wọlé lábẹ́lẹ̀. . . . Ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn onífàyàwọ́ oògùn olóró báyìí láti lo àkáǹtì àwọn báńkì láti gbé owó wọn láti ibì kan sí ibòmíràn láìní lùgbàdì òfin.”

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ará Amẹ́ríkà ló ń fọwọ́ kan kokéènì lójoojúmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ̀. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Discover ṣàlàyé pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn owó oníbébà ní Amẹ́ríkà ló tọ̀dọ̀ àwọn olówò oògùn olóró jáde.

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé lónìí, lílo egbòogi àti oògùn olóró, títí dórí àwọn oògùn tí kò bófin mu ti di ohun tí ọ̀pọ̀ ń gbà bí ẹni gba igbá ọtí, wọ́n kà á mọ́ ara ohun táa wáyé wá ṣe. Béèyàn bá wá wo ọṣẹ́ táwọn oògùn tí kò bófin mu wọ̀nyí, àti ohun tí tábà àti ọtí líle ti ṣe, ìbéèrè náà wá hàn gbangba pé, Kí ló dé táwọn èèyàn fi ń lò wọ́n? Báa ṣe ń ronú lórí ìbéèrè yìí, á dára táwa náà bá ronú nípa èrò wa lórí irú àwọn oògùn bẹ́ẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wọ́n túmọ̀ ọtí àmuyíràá sí ‘mímu ìgò ọtí márùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ níjokòó ẹ̀ẹ̀kan fún àwọn ọkùnrin, àti mímu ìgò mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ níjokòó ẹ̀ẹ̀kan fún àwọn obìnrin.’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ọtí àmuyíràá jẹ́ ìṣòro ńlá ní ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ọ̀pọ̀ ka sìgá àti àwọn oògùn “tí wọ́n fi ń ṣeré ìnàjú” sí ohun tí kò lè pani lára