Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 29. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)

1. Nígbà tí Dáfídì kò rọ́nà gbe gbà mọ́, kí ló ṣe láti bo ẹ̀ṣẹ̀ tó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà mọ́lẹ̀? (2 Sámúẹ́lì 11:15-17)

2. Kí la fi ṣẹ̀dá obìnrin àkọ́kọ́? (Jẹ́nẹ́sísì 2:22)

3. Ìwà irú àwọn ẹranko wo ni Pétérù fi ìwà àwọn tó fi “ipa ọ̀nà òdodo” sílẹ̀ wé? (2 Pétérù 2:21, 22)

4. Ní ọjọ́ ta ni a bẹ̀rẹ̀ sí “pe orúkọ Jèhófà”? (Jẹ́nẹ́sísì 4:26)

5. Ta ni ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì, kí sì ni orúkọ bàbá rẹ̀? (Ìṣe 13:21)

6. Lábẹ́ Òfin Mósè, ẹlẹ́rìí mélòó, ó kéré tán la béèrè ká tó lè pa ẹnì kan? (Diutarónómì 17:6)

7. Ọ̀dọ̀ ta ni Pọ́ọ̀lù sọ pé “olúkúlùkù ìdílé ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé ti gba orúkọ rẹ̀”? (Éfésù 3:14, 15)

8. Kí la mọ àwọn ọmọkùnrin Lámékì náà Jábálì àti Júbálì bí ẹni mowó fún? (Jẹ́nẹ́sísì 4:20, 21)

9. Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù àti Pétérù ṣe jẹ́rìí sí i, àwọn wo ni Ọlọ́run máa ń fún ní “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí”? (Jákọ́bù 4:6; 1 Pétérù 5:5)

10. Nínú àkàwé amọ̀kòkò náà àti amọ̀ rẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ, gbólóhùn wo ló lò láti ṣàpèjúwe àwọn ẹni burúkú àti àwọn olódodo? (Róòmù 9:22-24)

11. Késárì wo ni Pọ́ọ̀lù ké gbàjarè sí? (Ìṣe 25:11, 21)

12. Lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn ohun méjì wo ni ẹranko kan gbọ́dọ̀ ní ká tó lè kà á sí mímọ́ tí yóò sì ṣe é jẹ? (Léfítíkù 11:2, 3)

13. Kí ni lẹ́tà àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù? (Sáàmù 119, àkọlé)

14. Kí la sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe sétí apá gbígbárìyẹ̀ ara aṣọ wọn láti rán wọn létí pé a ti yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn mímọ́ fún Jèhófà? (Númérì 15:38-41)

15. Ní títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ìlú wo ni Ábúrámù fi sílẹ̀ láti rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ Kénáánì? (Jẹ́nẹ́sísì 15:7)

16. Kí ló dé tí Símónì Farisí kò fi fara mọ́ bí obìnrin kan ṣe fi ẹnu ko ẹsẹ̀ Jésù lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó sì fi òróró onílọ́fínńdà pa á? (Lúùkù 7:37-39)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Ó ṣètò kí wọ́n pa Ùráyà lójú ogun

2. Egungun táa yọ níhà Ádámù

3. Ajá àti abo ẹlẹ́dẹ̀

4. Énọ́ṣì

5. Sọ́ọ̀lù, Kíṣì

6. Méjì

7. “Baba,” Jèhófà Ọlọ́run

8. Wọ́n di olùpilẹ̀ṣẹ̀ àwọn darandaran àtàwọn olórin

9. “Àwọn onírẹ̀lẹ̀”

10. “Àwọn ohun èèlò ìrunú” àti “àwọn ohun èèlò àánú”

11. Nérò

12. Ó gbọ́dọ̀ jẹ àpọ̀jẹ kó sì la pátákò

13. Áléfì

14. A ní kí wọ́n ṣe ìṣẹ́tí kí wọ́n sì fi okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù sókè ìṣẹ́tí náà

15. Úrì ti àwọn ará Kálídíà

16. Wọ́n mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni, ìgbésí ayé oníwà pálapàla ló ń gbé, síbẹ̀ Jésù gbà kó fọwọ́ kan òun