Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lájọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Àwọn Òbí Mi Àgbà?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lájọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Àwọn Òbí Mi Àgbà?
“Bàbá bàbá mi àti bàbá ìyá mi fẹ́ràn láti máa sọ ìtàn nípa ara wọn. Ìtàn wọn máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti lóye èrò tèmi fúnra mi.”—Joshua.
ÌGBÀ kan wà tó wọ́pọ̀ pé àwọn ìran tó wá látinú ìdílé kan náà máa ń gbé nítòsí ara wọn—ó sì sábà máa ń jẹ́ nínú ilé kan náà. Ó jẹ́ àṣà nígbà yẹn pé káwọn èèyàn máa lájọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn òbí wọn àgbà.
Lóde ìwòyí, nítorí ọ̀nà jíjìn, àwọn èwe lè máà sí nítòsí àwọn òbí wọn àgbà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìdílé tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni ìkọ̀sílẹ̀ ń fọ́ yángá. Ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé “ìṣòro tí ìkọ̀sílẹ̀ ń fà lè kan àwọn òbí àgbà pẹ̀lú, ó sì lè má ṣeé ṣe fún wọn láti rí àwọn ọmọ ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn.” Láwọn ọ̀ràn mìíràn, ìṣòro náà ni pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ní èrò òdì nípa àwọn àgbàlagbà, wọ́n ń fojú ẹni tí kò mọ nǹkan tó ń lọ mọ́ wò wọ́n, pé èrò wọn, ohun tó jẹ́ pàtàkì sí wọn, àtàwọn ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí kò bá tàwọn mu rárá. Kí ni àbájáde èyí? Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò sún mọ́ àwọn òbí wọn àgbà tó bó ṣe yẹ.
Èyí ò bójú mu rárá. Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ kan tó ṣáájú nínú ọ̀wọ́ yìí ti fi hàn, kò sóhun tó dáa tó kéèyàn lájọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn òbí àgbà—pàápàá tí wọ́n bá jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, ohun tó dáa ni, ó ṣàǹfààní, ó sì ń gbádùn mọ́ni. a Ọ̀dọ́bìnrin kan tí kò ì pé ogún ọdún tó ń jẹ́ Rebekah sọ nípa àwọn òbí rẹ̀ àgbà pé: “Kò sígbà táa kì í jọ rẹ́rìn-ín.” Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Peter sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ pé: “Ẹ̀rù kì í bà mí láti sọ bí nǹkan bá ṣe rí lára mi fún wọn tàbí àwọn ohun tí mo ń gbèrò láti ṣe. Nígbà míì ara máa ń dẹ̀ mí tí mo bá wà lọ́dọ̀ wọn ju tí mo bá wà pẹ̀lú àwọn òbí mi lọ. Mo gbà pé kò sóhun tí mi ò lè bá àwọn òbí mi àgbà sọ.”
Ìwọ náà ńkọ́? Ó ṣeé ṣe kóo sún mọ́ àwọn òbí rẹ àgbà nígbà tóo ṣì kéré. Àmọ́ ní báyìí tóo ti wá di ọ̀dọ́langba, ó lè jẹ́ pé o kò ṣe tó bó ṣe yẹ láti fún àjọṣe yẹn lókun ní lọ́wọ́lọ́wọ́. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, níbí lo ti lè mú ìlànà tó wà nínú ìmọ̀ràn Bíbélì ní 2 Kọ́ríńtì 6:11-13 lò dáadáa, ìyẹn ni láti “gbòòrò síwájú” nínú ìfẹ́ rẹ sí wọn. Ìbéèrè ibẹ̀ wá ni pé, Lọ́nà wo?
Lílo Ìdánúṣe
‘Gbígbòòrò síwájú’ ń béèrè fún lílo ìdánúṣe díẹ̀. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, Òwe 3:27) Nígbà tóo wà lọ́mọdé, o lè máà ní “agbára” tó tó láti ṣe ohunkóhun nípa àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ àgbà. Àmọ́ ní báyìí tóo ti kúrò lọ́mọdé, bóyá tóo tiẹ̀ ti dàgbà, ó lè wá rí i pé àwọn ìgbésẹ̀ kan wa tó bójú mu kóo gbé.
nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” (Fún àpẹẹrẹ, ká ní tòsí làwọn òbí rẹ àgbà ń gbé, o lè sọ ọ́ dàṣà láti máa yọjú sí wọn déédéé. Ṣé pé á sú ọ? Bóyá ó lè rí bẹ́ẹ̀ tóo bá kàn ń jókòó ṣáá láìsọ nǹkan kan. Nítorí náà, wá ohun kan tẹ́ẹ lè jíròrò rẹ̀! Kí lohun tóo lè sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Ìlànà Bíbélì tó wà ní Fílípì 2:4 wúlò. Ó sọ fún wa pé ká ‘má ṣe máa mójú tó ire ti ara wa nìkan, ṣùgbọ́n ire ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’ Lédè míì, nífẹ̀ẹ́ ọkàn sáwọn òbí rẹ àgbà. Rọ̀ wọ́n láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì sí wọn. Báwo ni nǹkan ṣe rí lára wọn? Kí ni wọ́n ti ń ṣe bọ̀ látẹ̀yìnwá? Sísọ nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá lè gbádùn mọ́ wọn. Nítorí náà, béèrè lọ́wọ́ wọn bí ìgbésí ayé ti rí nígbà tí wọ́n wà léwe. Tàbí kẹ̀ béèrè bí bàbá rẹ tàbí màmá rẹ ṣe rí nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ọ́? Táwọn òbí rẹ àgbà bá jẹ́ Kristẹni, béèrè pé kí ló mú kí òtítọ́ Bíbélì fà wọ́n mọ́ra.
Àwọn òbí àgbà sábàá máa ń mọ púpọ̀ nípa ìtàn ìdílé, ó sì dájú pé wọ́n á fẹ́ fi àwọn ìtàn fífani lọ́kàn mọ́ra dá ọ lára yá. Kódà, o tiẹ̀ lè lo irú àwọn àǹfààní yẹn bí àkókò fún eré ìnàjú gbígbádùn mọ́ni. Gbìyànjú láti fọ̀rọ̀ wá àwọn òbí rẹ àgbà lẹ́nu wò, bóyá kóo tiẹ̀ máa ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn tàbí kóo gbà á sílẹ̀ sórí kásẹ́ẹ̀tì tàbí sínú fídíò. Ká ní o kò mọ ohun tóo lè béèrè lọ́wọ́ wọn, sọ pé káwọn òbí rẹ bá ọ wá àwọn ìbéèrè bíbójú mu. Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa jẹ́ kóo túbọ̀ lóye àwọn òbí rẹ àgbà, àwọn òbí rẹ, àti ìwọ alára ni wàá mọ̀. Jóṣúà sọ pé: “Bàbá bàbá mi àti bàbá ìyá mi fẹ́ràn láti máa sọ ìtàn. Ìtàn wọn máa ń ràn mí lọ́wọ́ láti lóye àwọn èrò tèmi fúnra mi.”
Àmọ́, má wàá gbàgbé pé àwọn òbí rẹ àgbà náà á fẹ́ mọ̀ nípa ìgbésí ayé rẹ àtàwọn ìgbòkègbodò rẹ. Tóo bá sọ ohun tí o ń ṣe fún wọn, ńṣe lò ń pè wọ́n láti jẹ́ apá kan ìgbésí ayé rẹ. Ó dájú pé èyí á túbọ̀ jẹ́ kẹ́ẹ sún mọ́ra dáadáa. Èwe kan láti France tó ń jẹ́ Igor sọ pé: “Èmi àti ìyá ìyá mi jọ máa ń lọ mu tíì nílé àrójẹ kan, tí a ó sì jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun táa ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́.”
Kí La Lè Ṣe Pa Pọ̀?
Tẹ́ẹ bá ti lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ pá pọ̀, bóyá ẹ tún lè lọ sórí jíjọ ṣe àwọn nǹkan díẹ̀ pa pọ̀. Tí o bá ronú nípa rẹ̀ dáadáa, o lè rí onírúurú ìgbòkègbodò tẹ́ẹ lè jọ lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Èwe kan tó ń jẹ́ Dara sọ pé: “Ìyá bàbá mi àti ìyá ìyá mi kọ́ mi ní oúnjẹ sísè, fífi oúnjẹ pamọ́ sínú agolo, ṣíṣe kéèkì, gbíngbin nǹkan, àti títọ́jú ọgbà.” Amy ní tiẹ̀ ń dára pọ̀ mọ́ àwọn òbí rẹ̀ àgbà lásìkò tí ìdílé wọn bá ń ṣe àwẹ̀jẹ-wẹ̀mu àti lákòókò ìsinmi. Ara àwọn òbí àgbà kan ṣì gbé kánkán, ìyẹn sinmi lórí ọjọ́ orí wọn ṣá. Aaron máa ń gbádùn gbígbá bọ́ọ̀lù àfọ̀págbá pẹ̀lú ìyá ìyá rẹ̀. Jóṣúà ní tiẹ̀ máa ń lọ pẹja pẹ̀lú bàbá ìyá rẹ̀ ó sì tún máa ń bá bàbá bàbá rẹ̀ ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ láyìíká ilé.
Táwọn òbí rẹ àgbà bá wá lọ jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà, kíkópa pẹ̀lú wọn nínú àwọn apá ìjọsìn Jèhófà á tún jẹ́ ohun tó ti lọ wà jù, irú bíi bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Igor rìnrìn àjò pẹ̀lú ìyá ìyá rẹ̀ lọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Poland. Ó sọ pé: “Ohun táa jọ gbádùn níbẹ̀ kò ṣe é gbà gbé, ìgbàkígbà táa bá sì ti ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni inú wa máa ń dùn.” Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo òbí àgbà ló lè káàkiri bẹ́ẹ̀ yẹn. Síbẹ̀, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ láti lo àkókò pẹ̀lú wọn.
Ogún Tẹ̀mí
Lákòókò kíkọ Bíbélì, obìnrin kan tó ń jẹ́ Lọ́ìsì kó ipa pàtàkì nínú ríran Tímótì ọmọ ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti di ènìyàn Ọlọ́run tó ta yọ. (2 Tímótì 1:5) Kò yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ àwọn òbí àgbà tó jẹ́ Kristẹni ló ń kó irú ipa kan náà lónìí. Jóṣúà sọ nípa àwọn òbí rẹ̀ àgbà pé: “Mi ò tíì dáyé nígbà tí wọ́n ti ń sin Jèhófà, nítorí náà, mi ò kóyán wọn kéré rárá, kì í ṣe torí pé wọ́n jẹ́ òbí mi àgbà nìkan ni àmọ́ pé wọ́n jẹ́ olùpa ìwà títọ́ mọ́.” Amy sọ pé: “Ìgbà gbogbo làwọn òbí mi àgbà máa ń sọ pé bí àwọn ṣe ń rí mi tí mò ń sin Jèhófà pẹ̀lú ìṣòtítọ́ máa ń mórí àwọn wú ó sì ń múnú àwọn dùn. Síbẹ̀, àpẹẹrẹ rere wọn àti ìtara wọn fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà [ajíhìnrere alákòókò kíkún] ti fún èmi náà níṣìírí láti máa bá a lọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà.”
Chris pe ìyá rẹ̀ àgbà ní “ẹni tó fún mi níṣìírí jù lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ àti láti dàgbà dénú.” Ó fi kún un pé: “Mi ò jẹ́ gbà gbé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ‘ká ṣe gbogbo ohun táa bá lè ṣe fún Jèhófà.’” Àwọn òbí Pedro àgbà ti kó ipa ribiribi nínú ìdàgbàsókè rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Ó sọ pé: “Ìrírí wọn ti ràn mí lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Gbogbo ìgbà làwọn òbí mi àgbà máa ń mú mi lọ sóde ẹ̀rí, mo sì mọrírì rẹ̀ gidigidi.” Bẹ́ẹ̀ ni o, sísún mọ́ àwọn òbí àgbà tó bẹ̀rù Ọlọ́run lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sin Ọlọ́run ní kíkún sí i.
Àwọn Òbí Àgbà Tó Wà Lọ́nà Jíjìn
Ká sọ pé ọ̀nà jíjìn làwọn òbí rẹ àgbà ń gbé ńkọ́? Tó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú àti máa bẹ̀ wọ́n wò lóòrèkóòrè. Láàárín ìgbà tí o ò tíì lọ rí wọn, ṣe ohun tóo bá lè ṣe kẹ́ẹ lè máa gbúròó ara yín. Ẹ̀ẹ̀mẹta péré lọ́dún ni Hornan ń rí àwọn òbí rẹ̀ àgbà, àmọ́ ó ní: “Mo máa ń pè wọ́n lórí tẹlifóònù ní gbogbo ọjọ́ Sunday.” Dara, tóun náà ń gbé ibi tó jìnnà sáwọn òbí rẹ̀ àgbà sọ pe: “Wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí mímọ bí ìgbésí ayé mi ṣe ń lọ sí, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la máa ń sọ̀rọ̀ lórí fóònù tàbí ká kọ lẹ́tà síra wa lórí kọ̀ǹpútà.” Fífi lẹ́tà ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà àti sísọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù kò burú, àmọ́ má fojú kéré ohun tí lẹ́tà àfọwọ́kọ èyí tó ti wà fún ìgbà pípẹ́ lè ṣe. Ọ̀pọ̀ èwe ló yà lẹ́nu láti rí i pé ńṣe làwọn òbí wọn àgbà ń tọ́jú gbogbo lẹ́tà tí wọ́n kọ sí wọn látìgbà tí wọ́n ti wà ní kékeré. Èèyàn lè ka lẹ́tà lákàtúnkà—kéèyàn sì ṣìkẹ́ rẹ̀. Nítorí náà, rí i pé o ń kọ lẹ́tà!
Àwọn òbí àgbà sábàá máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ọmọ wọn lọ́nà àkànṣe. (Òwe 17:6) Ọ̀pọ̀ ọ̀nà lo lè fi ní àjọṣe tímọ́tímọ́ tí yóò wà pẹ́ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ àgbà ì báà jẹ́ tòsí ni wọ́n ń gbé tàbí ọ̀nà jíjìn. Dákun, ṣe gbogbo ohun tóo bá lè ṣe.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí N Sún Mọ́ Àwọn Òbí Mi Àgbà?” nínú ìtẹ̀jáde wa ti May 8, 2001.