Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Oríṣiríṣi Ọ̀nà Tó Lọ Sọ́dọ̀ Ọlọ́run Ni Àwọn Ìsìn Jẹ́?

Ṣé Oríṣiríṣi Ọ̀nà Tó Lọ Sọ́dọ̀ Ọlọ́run Ni Àwọn Ìsìn Jẹ́?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣé Oríṣiríṣi Ọ̀nà Tó Lọ Sọ́dọ̀ Ọlọ́run Ni Àwọn Ìsìn Jẹ́?

ÒǸKỌ̀WÉ Marcus Borg sọ pé: “Mi ò gbà pé ìlànà ẹ̀sìn kan péré ni Ọlọ́run gbogbo ayé sọ pé kí wọ́n máa fi sin òun.” Desmond Tutu tó gba Ẹ̀bùn Nobel Lórí Àlàáfíà sọ pé: “Kò sí ìsìn kankan tó lè sọ pé òun mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ àdììtú” nípa ìsìn. Èrò tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn Híńdù ni “Jotto moth, totto poth,” béèyàn bá kàn tú ọ̀rọ̀ yìí lọ́nà kan ṣá, ó túmọ̀ sí pé gbogbo ìsìn wulẹ̀ jẹ́ oríṣiríṣi ọ̀nà tó lọ sí ibì kan náà. Èròǹgbà àwọn ẹlẹ́sìn Búdà náà nìyẹn. Àní, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló gbà gbọ́ pé ńṣe ni gbogbo ìsìn jẹ́ oríṣiríṣi ọ̀nà tó lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Òpìtàn Geoffrey Parrinder sọ pé: “Wọ́n máa ń sọ ọ́ nígbà mìíràn pé góńgó kan náà ni gbogbo ìsìn ní, tàbí pé ọ̀nà kan náà téèyàn fi lè rí òtítọ́ ni gbogbo wọn jẹ́, tàbí kẹ̀ pé ẹ̀kọ́ kan náà ni gbogbo wọn fi ń kọ́ni.” Àwọn ẹ̀kọ́, ìrúbọ àtàwọn ọlọ́run àjúbàfún àwọn ìsìn jọra lóòótọ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìsìn ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́, wọn sì ń kọ́ni pé ìṣìkàpànìyàn, olè jíjà, àti irọ́ pípa kò dára. Nínú ọ̀pọ̀ àwùjọ ìsìn, tọkàntọkàn làwọn kan fi ń sapá láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́. Nígbà náà, ṣé ẹ̀sìn téèyàn ń ṣe tiẹ̀ já mọ́ nǹkankan béèyàn bá ti ń fòótọ́ inú sin Ọlọ́run tó sì ń gbé ìgbésí ayé tó mọ́? Tàbí, ṣé gbogbo ẹ̀sìn wulẹ̀ jẹ́ oríṣiríṣi ọ̀nà tó lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ni?

Ṣé Òótọ́ Inú Nìkan Ti Tó?

Gbé ọ̀ràn ọkùnrin Júù ọ̀rúndún kìíní tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù, tó wá di Kristẹni àpọ́sítélì táa mọ̀ sí Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Kò fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ìsìn àwọn Júù rárá, èyí ló sì mú kó gbìyànjú láti fòpin sí ìjọsìn àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó ronú pé kò bójú mu. (Ìṣe 8:1-3; 9:1, 2) Ṣùgbọ́n, pẹ̀lú àánú Ọlọ́run, Sọ́ọ̀lù wá rí i pé àwọn tí kì í fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré bíi tirẹ̀ lè ní ìtara fún Ọlọ́run, síbẹ̀, nítorí àìmọ bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an, wọ́n lè kùnà. (Róòmù 10:2) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìbálò rẹ̀, ó yí padà ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn pẹ̀lú àwọn ẹni tó ti ń ṣe inúnibíni sí, ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi.—1 Tímótì 1:12-16.

Bíbélì ha sọ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìsìn ló wà àti pé èyíkéyìí téèyàn bá yàn ni Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà? Ìsọfúnni tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà látọ̀dọ̀ Jésù Kristi tí a jí dìde yàtọ̀ pátápátá sí èyí. Jésù rán an lọ bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè “láti la ojú wọn, láti yí wọn padà láti inú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀ àti láti inú ọlá àṣẹ Sátánì sí Ọlọ́run.” (Ìṣe 26:17,18) Ó ṣe kedere pé yíyàn táa bá ṣe nípa ìsìn ṣe kókó. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí a rán Pọ́ọ̀lù lọ bá ló ní ìsìn tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀. Àmọ́ inú “òkùnkùn” ni wọ́n wà. Àní, tó bá jẹ́ pé gbogbo ìsìn wulẹ̀ jẹ́ oríṣiríṣi ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun àti ojú rere Ọlọ́run ni, Jésù kì bá tí kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tó pàṣẹ fún wọn láti ṣe.—Mátíù 28:19, 20.

Nínú Ìwàásù olókìkí tí Jésù ṣe Lórí Òkè, ó sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:13, 14) Bíbélì là á mọ́lẹ̀ pé “ìgbàgbọ́ kan” péré ló wà. (Éfésù 4:5) Ó hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà ní ojú ọ̀nà “gbígbòòrò” ní ìsìn tiwọn. Àmọ́ wọn ò ní “ìgbàgbọ́ kan.” Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ọ̀nà ìjọsìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà, àwọn tí wọ́n fẹ́ láti rí ìgbàgbọ́ tòótọ́ yẹn ní láti máa wá a títí ọwọ́ wọn á fi tẹ̀ ẹ́.

Wíwá Ọlọ́run Tòótọ́ Náà

Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọmọ aráyé ni Ọlọ́run ti sọ fún ẹ̀dá ènìyàn ohun tó fẹ́ kí wọ́n ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15-17; 4:3-5) Lóde òní, àwọn ohun tó ń béèrè fún ni a ṣàlàyé yékéyéké sínú Bíbélì. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ìjọsìn tó tẹ́wọ́ gbà àti èyí tí kò tẹ́wọ́ gbà. (Mátíù 15:3-9) Àjogúnbá ni ìsìn tí àwọn ẹlòmíràn ń ṣe, àwọn míì sì rèé, ohun aráyé ń ṣe ni màá bá wọn ṣe lọ̀rọ̀ tiwọn. Ọ̀pọ̀ ló jẹ́ pé ibi tí wọ́n bí wọn àti ìgbà tí wọ́n bí wọn ló pinnu ìsìn tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́ ṣá, ṣó wá yẹ kóo máa fòní-dónìí fọ̀la-dọ́la nípa ìsìn tóo máa ṣe tàbí kó jẹ́ ẹnì kan ló máa sọ fún ọ irú ìsìn tí wàá ṣe?

Ìsìn tóo bá máa ṣe gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tóo ti fi Ìwé Mímọ́ wádìí ẹ̀ dáadáa. Kì í ṣe bí àwọn ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ṣe dún létí ló jẹ́ kí àwọn ọ̀mọ̀wé kan ní ọ̀rúndún kìíní gbà á gbọ́. Wọ́n ‘ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.’ (Ìṣe 17:11; 1 Jòhánù 4:1) Kí ló dé tíwọ náà ò ṣe bẹ́ẹ̀?

Bíbélì sọ pé àwọn tó máa jọ́sìn rẹ̀ ní òtítọ́ ni Ọlọ́run àgbáyé ń wá. Jésù sọ gẹ́gẹ́ bó ti wà lákọọ́lẹ̀ ní Jòhánù 4:23, 24, pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun. Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” Kìkì ‘ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú Ọlọ́run àti Baba wa’ ni ó tẹ́wọ́ gbà. (Jákọ́bù 1:27) Ọlọ́run ti bù kún ìwákiri tí ọ̀pọ̀ ti ṣe láti rí ọ̀nà tóóró tó lọ sí ìyè. Kò ní fún àwọn tí kò ka nǹkan sí ní ìyè àìnípẹ̀kun, kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tó jà fitafita láti rí ọ̀nà tóóró náà tó ti là sílẹ̀ tí wọ́n sì tọ̀ ọ́ ló máa fún.—Málákì 3:18.