Kíkojú Ìfàsẹ́yìn Nípa Gbígbé Góńgó Kalẹ̀
Kíkojú Ìfàsẹ́yìn Nípa Gbígbé Góńgó Kalẹ̀
ILÉ kan tó wà nítòsí Pápákọ̀ Òfuurufú LaGuardia ní ìlú New York ni William (Bill) Meiners àti ìyàwó rẹ̀, Rose, ń gbé. Ibẹ̀ ni Rose, obìnrin kan tára ẹ̀ yá mọ́ọ̀yàn tó sì ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún ti máa ń fi tẹ̀ríntẹ̀yẹ kí àlejò rẹ̀ káàbọ̀. Nínú ilé yẹn, kò sí béèyàn ò ṣe ní ṣàkíyèsí bí ìtura tó wà nínú pálọ̀ wọn ṣe fi hàn pé ẹlẹ́mìí nǹkan á dára lobìnrin ọ̀hún. Bí wọ́n ṣe ṣètò àwọn òdòdó tó wà lẹ́nu ọ̀nà wọn ní rèǹtè-rente, àtàwọn àwòrán ara ògiri tí wọ́n kùn lọ́nà tó jojú ní gbèsè fi hàn pé, yùngbà ni wọ́n ń gbádùn ayé wọn.
Nínú yàrá mímọ́lẹ̀ kan tó kángun sí pálọ̀ ni Bill, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin wà, tó fẹ̀yìn lélẹ̀ lórí ibùsùn, tí wọ́n sì fi mátírẹ́ẹ̀sì kan tó ṣeé sún sókè-sódò rọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Bó bá ti fojú kan àlejò rẹ̀ báyìí, bẹ́ẹ̀ layọ̀ á gba ojú rẹ̀ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ kan, tí yóò sì rẹ́rìn-ín músẹ́. Ì bá wù ú kó dìde ńlẹ̀, kó bọ àlejò lọ́wọ́, kó sì gbá a mọ́ra, àmọ́, kì í ṣeé ṣe fún un. Yàtọ̀ sí apá òsì ẹ̀ tó máa ń gbé díẹ̀díẹ̀, Bill yarọ láti ọrùn dé ìsàlẹ̀.
Nítorí pé àtìgbà tí Bill ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ló ti di aláìlera, wọ́n béèrè ohun tó ti ràn án lọ́wọ́ láti kojú àìsàn fún ohun tó ti ju àádọ́ta ọdún lọ. Bill àti Rose wojú ara wọn, wọ́n sì rọra rẹ́rìn-ín músẹ́. Bí ẹ̀rín Rose ti gba gbogbo inú yàrá kan, ó ní: “Àwa ò lẹ́nì kankan níbí tó ń ṣàìsàn o!” Ńṣe lojú Bill ní tiẹ̀ kún fún ìdùnnú; ó rẹ́rìn-ín sínú, ó sì rọra mi orí ẹ̀ láti fi hàn pé bí ìyàwó òun ṣe sọ lọ̀rọ̀ rí. Pẹ̀lú ohùn rẹ̀ tó ṣe gẹ̀dẹ̀gbẹ̀ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀ tí kò já gaara, ó ní: “Kò sẹ́ni tó ń ṣàìsàn níbí.” Rose àti Bill tún jọ dápàárá díẹ̀ síra wọn, kò sì pẹ́ rárá ti ẹ̀rín fi gba gbogbo inú yàrá náà kan. Kò sírọ́ ńbẹ̀, ìfẹ́ tí Bill àti Rose ní fúnra wọn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ pàdé ní September 1945 ṣì wà digbí. Wọ́n tún bi Bill lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Àní ká tiẹ̀ pa tàwàdà tì, àwọn ìfàsẹ́yìn wo lo ti bá pàdé? Kí lohun tó sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú ẹ̀ kóo sì máa gbé ìgbésí ayé pẹ̀lú ọ̀yàyà?” Lẹ́yìn tí wọ́n fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ rọ̀ ọ́, Bill gbà láti sọ ìtàn rẹ̀ fún wọn. Ohun tó tẹ̀ lé e yìí jẹ́ àyọkà díẹ̀ lára ìjíròrò tí Jí! ní pẹ̀lú Bill àti ìyàwó rẹ̀.
Àwọn Ìfàsẹ́yìn Bẹ̀rẹ̀ Sí Yọjú
Ní October 1949—ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí Bill gbé Rose níyàwó àti oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí wọ́n bí Vicki, ọmọbìnrin wọn—wọ́n sọ fún Bill pé
kókó ọlọ́yún kan ń dàgbà nínú ọ̀kan lára àwọn tán-án-ná rẹ̀, wọ́n sì mú kókó náà kúrò. Kò ju oṣù mélòó kan lọ lẹ́yìn náà, ni dókítà Bill bá tún sọ fún un nípa ìṣòro mìíràn—àrùn jẹjẹrẹ náà ti mú gbogbo gògòńgò rẹ̀. Bill ní: “Wọ́n sọ fún mi pé tí wọn kò bá fi iṣẹ́ abẹ mú gògòńgò náà kúrò lódindi—kò le ju ọdún méjì lọ tí màá gbé sí i láyé.”Wọ́n sọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde iṣẹ́ abẹ yìí fún Bill àti Rose. Gògòńgò tàbí àpò ohùn yìí ló gba ibi tí ahọ́n ti bẹ̀rẹ̀ lọ sí ọ̀nà ọ̀fun. Tán-án-ná méjì ni gògòńgò máa ń ní. Nígbà tí èémí tó ń jáde látinú ẹ̀dọ̀fóró bá gba inú àwọn tán-án-ná náà, wọ́n á gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, èyí ló sì ń gbé ohùn tó ń di ọ̀rọ̀ tí a ń sọ jáde. Tí wọ́n bá ti yọ gògòńgò náà kúrò, wọ́n á wá so kòmóòkun tó wà níbẹ̀ pọ̀ pẹ̀lú ihò kan tí wọ́n gé jáde níbi ọrùn lọ́wọ́ iwájú. Lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà, ibi ihò tí wọ́n ṣe yìí ni aláìsàn náà á ti máa gbà mí—àmọ́ kò ní lè sọ̀rọ̀ mọ́.
Bill sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ àlàyé yìí, inú bí mi. Ọmọbìnrin wa ṣì kéré, mo níṣẹ́ gidi lọ́wọ́, àwọn ohun ribiribi wà táa fẹ́ gbé ṣe ní ìgbésí ayé wa, àmọ́ nísinsìnyí, gbogbo ìrètí mi pátá ló ti wọmi.” Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí iṣẹ́ abẹ láti fi yọ gògòńgò kúrò yìí yóò ti gba ẹ̀mí Bill là, ó gbà láti ṣe é. Bill ṣàlàyé pé: “Lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà, mi ò lè gbé ohunkóhun mì. Mi ò lè sọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan. Mo di odi kalẹ̀.” Nígbà tí Rose lọ bẹ Bill wò, kìkì nípa kíkọ̀wé sórí pépà nìkan ló fi lè bá a sọ̀rọ̀. Àkókò yẹn ò fararọ rárá. Láti lè kojú ìṣòro yìí, wọ́n ní láti gbé àwọn góńgó tuntun kalẹ̀.
Kò Lè Sọ̀rọ̀, Kò Tún Níṣẹ́ Lọ́wọ́
Kì í ṣe pé iṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi mú gògòńgò Bill kúrò sọ ọ́ di odi nìkan ni, ó tún gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pẹ̀lú. Ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń to ẹ̀ya ara ẹ̀rọ papọ̀ ló ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí tó jẹ́ pé ihò tí wọ́n ṣe sí ọrùn rẹ̀ ló kù tó fi ń mí, ekuru àti èéfín lè ṣe ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀ ní jàǹbá. Ó wá pọndandan kó wáṣẹ́ míì ṣe. Síbẹ̀, pẹ̀lú àìlèsọ̀rọ̀ rẹ̀, ó lọ forúkọ sílẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe aago. Bill sọ pé: “O jọ iṣẹ́ mi àkọ́kọ́. Mo mọ bí wọ́n ṣe ń to ẹ̀yà-ara ẹ̀rọ pa pọ̀, téèyàn bá sì ń ṣe aago, ńṣe ni wàá máa to àwọn ẹ̀ya ara rẹ̀ pọ̀. Ó kàn jẹ́ pé gbogbo ẹ̀ya ara tirẹ̀ kò tó nǹkan kan lórí ìwọ̀n ni!” Bó ṣe parí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ aago, bẹ́ẹ̀ ló ríṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi olùṣe aago. Bí ọwọ́ ẹ̀ ṣe tẹ góńgó kan nìyẹn o.
Àmọ́ láàárín ìgbà yẹn, Bill tún ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ síbì kan tí wọ́n ti ń kọ́ bí èèyàn ṣe lè fi ihò ọ̀fun sọ̀rọ̀. Nínú fífi ihò ọ̀fun sọ̀rọ̀ yìí, kì í ṣe tán-án-ná ló tún ń gbé ìró ohùn jáde mọ́, àmọ́ ìgbọ̀npẹ̀pẹ̀ nínú ihò ọ̀fun, ìyẹn ọ̀pá tó ń gbé oúnjẹ láti ọ̀fun lọ sí ikùn ló wá ń ṣiṣẹ́ yẹn. Lákọ̀ọ́kọ́, èèyàn á kọ́ bí wọ́n ṣe ń gbé atẹ́gùn mì, èèyàn á sì ti èémí yí sínú ihò ọ̀fun dáadáa. Lẹ́yìn náà, èèyàn á wá rọra gùnfẹ̀ síta. Bí afẹ́fẹ́ yìí ti ń jáde padà, á mú kí àwọn ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ihò ọ̀fun bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Ìyẹn ló máa wá mú ìró gẹ̀dẹ̀gbẹ̀ kan wá, téèyàn á fi lè lo ẹnu àti ètè láti mú ọ̀rọ̀ jáde.
Bill sọ pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, tí mo bá yó jù nìkan ni mo máa ń gùnfẹ̀, àmọ́, ó ti wá di pé kí n kọ́ bí màá ṣe máa gùnfẹ̀ ní gbogbo ìgbà báyìí. Nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, mi ò lè pè ju ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo lẹ́ẹ̀kan, bí mo ṣe ń ṣe é rèé: ‘[Mí sínú, gbé e mì, gùnfẹ̀] Ṣé [mí sínú, gbé e mì, gùnfẹ̀] àlááfíà [mí sínú, gbé e mì, gùnfẹ̀] ni?’ Kò rọrùn rárá. Ẹ̀yìn náà ni olùkọ́ mi sọ fún mi pé kí n rí i pé mo ń mu ọtí tí wọ́n fi atalẹ̀ ṣe dáadáa nítorí pé gáàsì inú rẹ̀ á jẹ́ kí n máa gùnfẹ̀ déédéé. Nítorí náà, ìgbàkigbà tí Rose bá mú Vicki jáde lọ gba atẹ́gùn, màá mu ún, màá gùnfẹ̀, màá tún mu ún, màá sì tún gùnfẹ̀. Mo ṣiṣẹ́ kára lórí ẹ̀!”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn aláìsàn tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ tí wọ́n fi ń mú gògòńgò kúrò fún ni kì í lè fi ihò ọ̀fun wọn sọ̀rọ̀, Bill ṣàṣeyọrí ní tiẹ̀. Vicki, tó ti ń lọ pé ọmọ ọdún méjì nígbà yẹn máa ń fi tipátipá tì í pé kó sọ̀rọ̀, ṣé òun ò sì mọ nǹkan kan ní tiẹ̀. Bill sọ pé: “Vicki á sọ̀rọ̀ sí mi á wá máa wojú mi pé kí n dáhùn. Àmọ́ mi ò lè sọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan láti fún un lésì. Á tún sọ̀rọ̀ sí i, síbẹ̀ mi ò ní lè dáhùn padà. Pẹ̀lú ìbínú, lá bá kọjú sí ìyá rẹ̀, á sì sọ fún un pé: ‘Ẹ ní kí Dádì bá mi sọ̀rọ̀!’ Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí dùn mí wọra, ó sì jẹ́ kí n pinnu pé máa ri pé mo tún bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀.” Bill ṣàṣeyọrí o, èyí sì múnú Vicki, Rose àtàwọn mìíràn dùn. Ọwọ́ ẹ̀ tún tẹ góńgó kan sí i.
Àjálù Míì Tún Já Lù Ú
Bí ọdún 1951 ti ń parí lọ, Bill àti Rose tún dojú kọ ìṣòro lílekoko míì. Bí àwọn dókítà ti ń bẹ̀rù pé àrùn jẹjẹrẹ náà tún lè padà, wọ́n rọ Bill pé kó bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú onítànṣán. Bill gbà. Nígbà tí ìtọ́jú náà parí, ó bẹ̀rẹ̀ sí hára gàgà láti tún bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé lákọ̀tun. Kò mọ̀ rárá pé àjálù mìíràn máa tó tún já lu ìlera òun!
Nǹkan bí ọdún kan kọjá. Bẹ́ẹ̀ ló di ọjọ́ kan làwọn ọmọ ìka Bill bá kú tipiri. Lẹ́yìn náà, kò lè gun àtẹ̀gùn mọ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ló ṣubú níbi tó ti ń rìn lọ, kò sì lè dá dìde fúnra ẹ̀ mọ́. Àwọn àyẹ̀wò tó ṣe fi hàn pé ìtọ́jú onítànṣán tí Bill ṣe (èyí tí kò péye nígbà yẹn bíi tòde oní) ti ba okùn ògóóró ẹ̀yìn rẹ̀ jẹ́. Wọ́n sọ fún un pé ipò rẹ̀ ṣì máa burú sí i. Dókítà kan tiẹ̀ sọ fún un pé “kò dájú” pé ó máa yè é. Ìbànújẹ́ gbé Bill àti Rose mì.
Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, láti kojú ìṣòro yìí, Bill lọ sí ilé ìwòsàn kan fún ìtọ́jú olóṣù mẹ́fà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtọ́jú yẹn kò yí ipò rẹ̀ padà, àmọ́ wíwà tó wà ní ilé ìwòsàn náà yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà—ìyípadà tó wá mú kó mọ Jèhófà nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Báwo nìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀?
Mímọ Okùnfà Àwọn Ìfàsẹ́yìn Rẹ̀ Fún Un Lókun
Ní gbogbo oṣù mẹ́fà yẹn, Bill wà nínú yàrá kan náà nílé ìwòsàn àwọn Júù pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mọ́kàndínlógún mìíràn táwọn náà ti rọ lápá rọ lẹ́sẹ̀—gbogbo wọn jẹ́ ẹlẹ́sìn Júù. Ọ̀sán ọjọ́ kan ò kọjá káwọn ọkùnrin yìí má sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Bill, tó jẹ́ pé ìjọ Onítẹ̀bọmi ló ń lọ ṣáà kàn máa ń tẹ́tí sóhun tí wọ́n ń sọ ni. Ṣùgbọ́n nígbà tó fi máa fi ilé ìwòsàn náà sílẹ̀, ìwọ̀nba ohun tó ti gbọ́ ti mú kó gbà pé ẹnì kan ṣoṣo ni Ọlọ́run Olódùmarè í ṣe àti pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan kò bá Bíbélì mu. Èyí ló fà á tí Bill kò tún fẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ ṣọ́ọ̀ṣì tó ti ń lọ tẹ́lẹ̀ mọ́. Síbẹ̀síbẹ̀, ó mọ̀ pé òun nílò ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí láti fi kojú àwọn ìṣòro tó bá ìgbésí ayé rẹ̀. Bill sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́, ó sì dáhùn àwọn àdúrà mi.”
Ní ọjọ́ Sátidé kan ní ọdún 1953, Roy Douglas, ọkùnrin àgbàlagbà kan tó tí jẹ́ aládùúgbò Bill tẹ́lẹ̀ rí, gbọ́ nípa wàhálà tí Bill wà nínú ẹ̀, ló bá yà kí i. Roy, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ fún Bill pé kó jẹ́ kóun máa bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Bill sì gbà. Ńṣe ni ohun tí Bill kà nínú Bíbélì àti nínú ìwé náà “Jẹki Ọlọrun Jẹ́ Olõtọ́” a là á lóye. Ó sọ nípa ohun tó kọ́ fún Rose, nìyẹn náà bá dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Rose sọ pé: “Wọ́n ti sọ fún wa ní ṣọ́ọ̀ṣì pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àìsàn jẹ́, àmọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa jẹ́ ká mọ̀ pé èyí kì í ṣe òótọ́. Pẹ̀sẹ̀ ni ara tù wá.” Bill fi kún un pé: “Mímọ̀ látinú Bíbélì nípa ohun tó ń fa wàhálà, títí kan àìsàn tó ń ṣe mí, àti rírí i pé ọjọ́ iwájú tó sàn kàn ń bọ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ipò tí mo bá ara mi.” Lọ́dún 1954, ọwọ́ Bill àti Rose tún ba góńgó mìíràn. Àwọn méjèèjì ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ṣíṣe Àwọn Àtúnṣe Mìíràn
Ní gbogbo ìgbà yẹn, ipò Bill ti burú débi tí kò lè bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ mọ́. Láti lè gbọ́ bùkátà wọn, Bill àti Rose ṣe pàṣípààrọ̀ iṣẹ́ wọn: Bill ń dúró ti Vicki nílé, Rose sì ń lọ ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ aago wọn—odindi ọdún márùndínlógójì gbáko ló fi ṣiṣẹ́ yẹn!
Bill sọ pé: “Bíbójútó ọmọbìnrin wa fún mi láyọ̀ tó pọ̀ gan-an. Vicki náà sì gbádùn ẹ̀ pẹ̀lú. Ó tiẹ̀ tún máa ń fi yangàn nípa sísọ fáwọn èèyàn tó bá rí pé: ‘Èmi ni mo ń tọ́jú Dádì!’ Nígbà tó di pé ó bẹ̀rẹ̀ iléèwé, mo máa ń bá a ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀, a sì tún jọ máa ń ṣeré ìdárayá pa pọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, mo tún ni àǹfààní tó dára láti fún un ní ìtọ́ni Bíbélì.”
Lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tún jẹ́ ohun mìíràn tó máa ń fún Bill àti ìdílé rẹ̀ láyọ̀. Ó máa ń gbà á ní wákàtí kan kó tó tiro láti ilé rẹ̀ dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, àmọ́ o, kì í pa ìpàdé jẹ. Nígbà tí Bill àti Rose kó lọ sí apá ibòmíràn nínú ìlú yẹn lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kékeré kan, Rose sì máa ń wa ìdílé wọn lọ sípàdé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bill ò lè sọ̀rọ̀ púpọ̀, ó forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Bill ṣàlàyé pé: “Mo máa ń kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀, arákùnrin mìíràn á sì wá bá mi ṣe é. Lẹ́yìn tọ́rọ̀ náà bá parí, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á wá fún mi ní ìtọ́ni lórí ohun tí mo kọ sílẹ̀.”
Àwọn tó wà nínú ìjọ tún máa ń ran Bill lọ́wọ́ láti kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù. Kò sì ya àwọn tó ti ń kíyè sí ìfọkànsìn rẹ̀ lẹ́nu nígbà tí a yan Bill gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ náà. Nígbà tó wá di pe àwọn ẹsẹ rẹ̀ kọṣẹ́ tí àrùn rọpárọsẹ̀ náà túbọ̀ wá wọ̀ ọ́ lára, ló wá di pé kò lè kúrò nínú ilé rẹ̀ mọ́, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó dẹni tí kò lè dìde nílẹ̀ mọ́. Ǹjẹ́ yóò lè kojú ìfàsẹ́yìn yìí?
Ohun Ìgbádùn Kan Tí Ń Gba Àfiyèsí
Bill sọ pé: “Nígbà tó di pé ilé ni mo ń wà látàárọ̀ ṣúlẹ̀, mo wa ohun kan tí màá máa fi pawọ́ dà. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, kí n tó rọ lápá rọ lẹ́sẹ̀, mo máa ń gbádùn fọ́tò yíyà. Nítorí náà, mo ronú pé mo lè máa ya àwòrán, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ya àwòrán rí ní ìgbésí ayé mi. Bákan náà, ọwọ́ ọ̀tún ni mo máa ń lò, àmọ́, ọwọ́ ọ̀tún mi ọ̀hún àti méjì lára ìka ọwọ́ òsì mi ti rọ pátápátá. Tóò, Rose ra ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tó sọ nípa ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ya àwòrán. Mo kà wọ́n dáadáa, ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí lo ọwọ́ òsì mi láti ya àwòrán. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn àwòrán tí mo yà ló jẹ́ pé ṣe la fi iná sun wọ́n kẹ́yìn, àmọ́, nígbà tó ṣe, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí mọ̀ ọ́n.”
Àwọn àwòrán àfọwọ́yà lóríṣiríṣi tó wá ṣe ilé Bill àti Rose lọ́ṣọ̀ọ́ báyìí fi hàn pé Bill ṣàṣeyọrí kọjá bó ṣe rò. Bill fi kún un pé: “Ní nǹkan bí ọdún márùn-ún sẹ́yìn, ọwọ́ mi òsì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n débi pé mo ní láti gbàgbé nípa búrọ́ọ̀ṣì mi pátápátá, àmọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún ni iṣẹ́ àfipawọ́ yìí fi fún mi ní ìgbádùn tó pọ̀.”
Góńgó Kan Tó Ṣẹ́ Kù
Bill sọ pé: “Àádọ́ta ọdún ti kọjá báyìí látìgbà tí àìlera mi ti bẹ̀rẹ̀. Bíbélì kíkà ṣì máa ń tù mí nínú, àgàgà nígbà tí mo bá ka Sáàmù àti ìwé Jóòbù. Mo sì tún ń gbádùn kíka àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society. Mo tún máa ń rí ọ̀pọ̀ ìṣírí gbà nígbà táwọn ará ìjọ wa, àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò bá bẹ̀ mí wò tí wọ́n sì sọ àwọn ìrírí tí ń dáni lárayá fún mi. Láfikún sí i, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alátagbà láti Gbọ̀ngàn Ìjọba ń jẹ́ kí n lè tẹ́tí sí àwọn ìpàdé, mó tilẹ̀ tún máa ń wo àwọn fídíò tí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ wà nínú wọn.
“Mo kún fún ọpẹ́ pé Ọlọ́run fi ìyàwó tó nífẹ̀ẹ́ mi jíǹkí mi. Jálẹ̀ gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí wá, ó ti jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ mi tímọ́tímọ́. Ọmọbìnrin wa, tóun náà ń sin Jèhófà báyìí pẹ̀lú ìdílé tirẹ̀ ṣì jẹ́ orísun ayọ̀ púpọ̀ fún wa. Ní pàtàkì jù lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ń lè sún mọ́ òun tímọ́tímọ́. Lọ́jọ́ tòní, bí ara mi àti ohùn mi ti túbọ̀ ń di ahẹrẹpẹ sí i, mo sábà máa ń ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Àwa kò juwọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ẹni tí a jẹ́ ní òde bá tilẹ̀ ń joro, dájúdájú, ẹni tí àwa jẹ́ ní inú ni a ń sọ dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́.” (2 Kọ́ríńtì 4:16) Bẹ́ẹ̀ ni, níwọ̀n ìgbà tí mo bá ṣì wà láàyè, wíwà lójúfò nípa tẹ̀mí, ni góńgó mi tó ṣẹ́ kù.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ̀ ẹ́; a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]
“Lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà, mi ò lè gbé ohunkóhun mì. Mi ò lè sọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan. Mo di odi kalẹ̀”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Bill àti Rose rèé ní báyìí