Ẹ̀dùn Ọkàn Lóríṣiríṣi
Ẹ̀dùn Ọkàn Lóríṣiríṣi
BÀBÁ àgbàlagbà kan sọ pé: “Lẹ́yìn tí wọ́n sọ fún mi pé mo ti láìsàn tó ń gbẹ̀mí èèyàn, mo gbìyànjú láti gbé ìbẹ̀rù mi tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, àmọ́ ńṣe ni èrò àìdánilójú bẹ̀rẹ̀ sí í káàárẹ̀ bá mi.” Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ túbọ̀ jẹ́ ká mọ òtítọ́ náà pé kì í ṣe ìrora nìkan ni àìsàn líle máa ń mú bá ara, ó tún máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni pẹ̀lú. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn wà tí wọ́n ń kojú àwọn ìṣòro náà ní àkòlà. Púpọ̀ lára wọn á fẹ́ láti mú un dá ọ lójú pé ọ̀nà wà tóo lè gbà ko àìsàn bára kú lójú tí wàá sì yege. Ṣùgbọ́n ká tó sọ̀rọ̀ lórí ohun tóo lè ṣe, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo díẹ̀ lára àwọn èrò tó lè yọjú níbẹ̀rẹ̀.
Àìgbàgbọ́, Sísẹ́ Ohun Tó Ṣẹlẹ̀, àti Ìbànújẹ́
Àwọn èrò tìrẹ lè yàtọ̀ gan-an sí tàwọn ẹlòmíràn. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ògbógi nínú ìmọ̀ ìlera àtàwọn aláìsàn náà pẹ̀lú sọ pé irú èrò kan náà làwọn èèyàn tí àrùn kọ lù sábà máa ń ní. Ìjayà àti àìgbàgbọ́ ló máa ń ṣáájú, lẹ́yìn náà, sísẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ lè wá tẹ̀ lé e, irú bíi: ‘Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀.’ ‘Bóyá wọ́n ṣàṣìṣe ni.’ ‘Bóyá èsì àyẹ̀wò àrùn ti ẹlòmíì ni wọ́n gbé fún mi.’ Nígbà tóbìnrin kan ń ṣàpèjúwe bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tó mọ̀ pé òun ti ní àrùn jẹjẹrẹ, ó ní: “Ńṣe ló máa dà bí pé kóo daṣọ borí, nígbà tóo bá sì fi máa ká a kúrò báyìí, kí àìsàn náà ti wábi gbà.”
Ṣùgbọ́n, bóo ti ń rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ ọ̀hún, sísẹ́ tóo ti ń sẹ́ tẹ́lẹ̀ yóò wá bẹ̀rẹ̀ sí di ìbànújẹ́, àìláyọ̀ á wá bò ọ́ mọ́lẹ̀ bámúbámú bí ìgbà tí jàǹbá kan tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ fẹ́ ṣẹlẹ̀ sí ọ. Àwọn ìbéèrè bíi, ‘Báwo làsìkò tó kù tí màá gbé láyé ṣe gùn tó?’ ‘Ṣé pé nínú ìrora ni máa ti gbé ìyókù ayé mi?’ àtàwọn ìbéèrè míì bẹ́ẹ̀ lè dà bò ọ́. Lójú ẹ, ó lè dà bíi pé kóo máa gbé ìgbésí ayé tóo ti ń gbé tẹ́lẹ̀ kóo tó mọ̀ nípa àìsàn náà, àmọ́ ìyẹn ò ṣeé ṣe fún ọ mọ́. Láìpẹ́ láìjìnnà, o lè bẹ̀rẹ̀ sí ní ọ̀pọ̀ èrò tí ń bà ọ́ nínú jẹ́. Irú àwọn èrò wo?
Àìsídàánilójú, Àníyàn, Ìbẹ̀rù
Àìsàn kan tó burú jáì ti wá da àìsídàánilójú àti àníyàn sínú ìgbésí ayé ẹ. Ọkùnrin kan tó ní àrùn Parkinson sọ pé: “Àìmọ ibi tọ́rọ̀ mi máa já sí máa ń mú káyé sú mi nígbà míì. Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, mo ní láti máa ṣọ́ ọwọ́ tó máa yọ.” Àìsàn náà tiẹ̀ lè máa kó jìnnìjìnnì bá ọ. Tó bá lọ jẹ́ pé àìròtẹ́lẹ̀ ló dé sí ọ, ẹ̀rù tó máa bà ọ́ lè kọjá àfẹnusọ. Àmọ́ o, ìbẹ̀rù náà lè dà bí èyí tí kò tó nǹkan
tó bá lọ jẹ́ pé wọ́n wá ṣàwárí irú àrùn tó ń ṣe ọ lẹ́yìn tóo ti dààmú fún ọ̀pọ̀ ọdún nítorí pé tẹ́lẹ̀ rí, nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn àmì àrùn tí wọ́n rí lára ẹ, ohun tí kò ṣe ọ́ ni wọ́n sọ pé ó ń ṣe ọ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó tiẹ̀ lè dà bí ẹni pé ara tù ọ́, pé àwọn èèyàn á tiẹ̀ jàjà gbà pé òótọ́ ni nǹkan ṣe ọ́ àti pé kì í ṣe pé o wulẹ̀ ń díbọ́n. Ṣùgbọ́n ó lè má pẹ́ rárá tí ìbẹ̀rù mímọ àwọn nǹkan tí àyẹ̀wò ìṣègùn náà mú lọ́wọ́ yóò fi tẹ̀ lé ìtura tóo rò pé o ní.Ìbẹ̀rù pé o ò ní lè ṣàkóso ìgbésí ayé rẹ mọ́ lè kó ìdààmú bá ọ pẹ̀lú. Àgàgà tóo bá fẹ́ràn láti máa fúnra rẹ ṣe nǹkan, ẹ̀rù lè bà ọ́ nígbà tóo bá wá ronú pé àwọn ẹlòmíràn lá wá máa bá ọ ṣe púpọ̀ àwọn nǹkan. O lè bẹ̀rẹ̀ sí dààmú pé àìsàn rẹ ti ń jọba lórí ìgbésí ayé ẹ àti pé òun ló ń pinnu ohun tóo gbọ́dọ̀ ṣe.
Ìbínú, Ìtìjú, Ìnìkanwà
Bóo ti ń rí i tágbára rẹ túbọ̀ ń tán lọ lè mú ọ́ bẹ̀rẹ̀ sí bínú. O lè wá máa bi ara rẹ pé, ‘Kí ló dé tó jẹ́ emi? Kí ni mo ṣe tó fi yẹ kí irú èyí ṣẹlẹ̀ sí mi?’ O ò rí ìdí kankan tó bọ́gbọ́n mu tó fi yẹ kí irú àìsàn ńlá báyìí ṣe ọ́. Ojú tún lè bẹ̀rẹ̀ sí tì ọ́ kí o sì wá bọ́ sínú ipò àìnírètí. Ẹnì kan tó ní àrùn rọpárọsẹ̀ sọ pé: “Ojú tì mí gidigidi nítorí pé ohun tó fa gbogbo èyí bá mi kò ju jàǹbá burúkú kan báyìí!”
Ìnìkanwà pẹ̀lú tún lè sọ pé ó ku ibi tóo máa gbà. Ìnìkanwà tètè máa ń yọrí sí ṣíṣàìbẹ́gbẹ́ ṣe mọ́. Bí àìsàn tó ń ṣe ọ́ bá lọ sọ ọ́ di dandan fún ẹ láti fìdí mọ́lé, o lè má lè kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tẹ́lẹ̀ mọ́. Síbẹ̀, àsìkò yìí gan-an ni wàá fẹ́ máa rí àwọn èèyàn ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn bá ti bẹ̀ ọ́ wò tí wọ́n sì ti bá ọ sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù níbẹ̀rẹ̀, àwọn tó máa wá máa bẹ̀ ọ́ wò lè máa dín kù díẹ̀ díẹ̀ tí wọn kò ní tò nǹkan mọ́.
Nítorí pé ó máa ń dunni láti rí i káwọn ọ̀rẹ́ yẹra fúnni, ìwọ náà kúkú lè wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn tó ń dùn ọ́ yìí, kóo wá bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn èèyàn. Ká sòótọ́, o lè fẹ́ kó ṣe díẹ̀ kóo tó tún máa yọjú sáwọn èèyàn. Àmọ́ tó bá lọ jẹ́ pé irú àsìkò yìí lo túbọ̀ ń yẹra fáwọn èèyàn, ọ̀rọ̀ rẹ lè kúrò látorí ìdẹ́yẹsíni (nígbà táwọn èèyàn ò wá wò ọ́) lọ dórí ìbẹ́gbẹ́-yan-odì (nígbà tó jẹ́ pé ìwọ lo ò fẹ́ rí àwọn èèyàn). Èyí ó wù ó jẹ́ nínú ẹ̀, ipò ìnìkanwà tó burú jáì lè máa bá ọ fínra. a Àwọn ìgbà míì tiẹ̀ wà tí wàá máa rò ó pé bóyá ni wàá dọjọ́ kejì.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ẹlòmíràn
Bo ti wù kó rí, ìrètí ń bẹ. Bí àrùn burúkú kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ lù ọ́, àwọn nǹkan tó gbéṣẹ́ wà tóo lè ṣe láti padà ní agbára díẹ̀ lórí ìgbésí ayé rẹ.
Irú èyí tó wù kí àìlera rẹ tó ti di bára kú jẹ́, a gbà pé ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ò lè yanjú ẹ̀. Síbẹ̀, ìsọfúnni tó wà níbẹ̀ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí àwọn ọ̀nà tóo fi lè kojú wọn. Obìnrin kan tó ní àrùn jẹjẹrẹ ṣàkópọ̀ àwọn ohun tó là kọjá pé: “Lẹ́yìn ti mo ti kọ́kọ́ sọ pé irọ́ ni, kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀, inú bẹ̀rẹ̀ sí bí mi gidigidi, lẹ́yìn náà ni mó wá bẹ̀rẹ̀ sí wá ohun tí mo lè ṣe sí i.” Ìwọ náà lè ṣe irú ìwákiri bẹ́ẹ̀, nípa yíyíjú sáwọn èèyàn tó ti ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀ ṣáájú tìẹ, kóo sì kọ́ bóo ṣe lè jàǹfààní látinú àwọn ojútùú tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ẹ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àmọ́ ṣá o, bí onírúurú nǹkan yìí ṣe ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń jura wọn lọ, bí wọ́n sì ṣe ń ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra máa ń yàtọ̀ síra wọn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]
O lé wá máa bi ara rẹ pé, ‘Kí ló dé tó jẹ́ èmi? Kí ni mo ṣe tó fi yẹ kí irú èyí ṣẹlẹ̀ sí mi?’