Ibo Lo Ti Lè Rí Ẹ̀kọ́ Tó Dára Jù Lọ?
Ibo Lo Ti Lè Rí Ẹ̀kọ́ Tó Dára Jù Lọ?
“Gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè fi òkúta mábìlì ṣe iṣẹ́ ọnà tó lẹ́wà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀kọ́ ṣe lè yí ọkàn padà.”—Joseph Addison, 1711.
ǸJẸ́ o lọ iléèwé rí? Àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ lè dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni—àmọ́ kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló lè sọ bẹ́ẹ̀. Báa ti wọnú ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé ni kì í lọ sí ilé ìwé bó ṣe yẹ. Ó sì pẹ́ tí èyí ti ń bá a bọ̀, débi pé lónìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù kan àwọn àgbàlagbà tí kò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà.
Síbẹ̀, ó dára gan-an kéèyàn kàwé. Dípò káwọn èèyàn kà á sí ohun afẹ́ kan tọ́wọ́ ò lè tẹ̀, ọ̀pọ̀ lónìí ló mọ̀ pé ẹ̀tọ́ tọmọdé-tàgbà ló jẹ́. Àmọ́, báwo ni ẹ̀kọ́ gidi ṣe lè ṣeé ṣe láìsí àwọn ohun tó pọn dandan táa nílò? Bí kò bá sí ìwé tó pọ̀ tó ńkọ́, tí kò sí àwọn olùkọ́ tó tóótun, táwọn ilé ẹ̀kọ́ kò sì tó?
Àní, ibo láwọn èèyàn ti lè rí ojúlówó ẹ̀kọ́, èyí tó ń fún ẹnì kọ̀ọ̀kan níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́, tó ń mú ìmọ̀ wọn nípa ayé tó yí wọn ká gbòòrò sí i, tó sì ń pèsè ìlànà tẹ̀mí gidi tó lè yí ìgbésí ayé wọn padà? Irú ẹ̀kọ́ wo ló ń tẹnu mọ́ ìlànà ìwà rere gbígbámúṣé, tó ń jẹ́ kéèyàn mọ bí a ṣe lè gbé ìgbésí ayé kan tó sàn jù, tó sì ń fúnni ní ìrètí tó dúró gírígírí nípa ọjọ́ ọ̀la? Ṣé ní tòótọ́ ni gbogbo èèyàn lè rí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ gbà?
Ìpìlẹ̀ fún Ẹ̀kọ́ Tó Dára Jù Lọ
Bó ti wù kó yani lẹ́nu tó, a lè fọwọ́ sọ̀yà pé ojúlówó ẹ̀kọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo gbòò. Ìdí ni pé irinṣẹ́ kan fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wà tó lágbára láti pèsè ìpìlẹ̀ fún un. Ìyẹn ni “ìwé” kan táa gbóríyìn fún pé ó bá ìgbà mu lọ́jọ́kọ́jọ́, tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó lódindi tàbí lápá kan ní nǹkan tó ju ẹgbọ̀kànlá [2,200] èdè lọ. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé ló lè ní i ní èdè tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lè lóye. Ìwé wo gan-an tiẹ̀ ni?
Bíbélì ni, ìwé kan tí a kan sáárá sí níbi gbogbo gẹ́gẹ́ bí ìwé tó ṣe pàtàkì jù lọ tí a tí ì kọ rí. William Lyon Phelps, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún kọ̀wé pé: “Lóòótọ́, gbogbo ẹni tó bá mọ Bíbélì lámọ̀dunjú la lè pè ní ọ̀mọ̀wé. Kò tún sí ẹ̀kọ́ kankan tàbí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, bó ti wù kó gbòòrò tàbí kó lẹ́wà tó, tó . . . lè rọ́pò rẹ̀.”
Bíbélì jẹ́ àkójọpọ̀ ìwé tí a kọ fún nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ ọdún [1,600]. Phelps tún sọ síwájú sí i nípa àkójọ ìwé pàtàkì yìí pé: “Àwọn èrò wa, ọgbọ́n wa, ọgbọ́n èrò orí wa, àwọn ìwé wa, ọgbọ́n-ọnà wa, àti àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n pípé wa tí wọ́n wá látinú Bíbélì pọ̀ ju gbogbo àwọn tí wọ́n wá látinú gbogbo ìwé yòókù lápapọ̀. . . . Mo gbà pé kéèyàn ní ìmọ̀ Bíbélì láìsí ìmọ̀ yunifásítì sàn ju kó ní ìmọ̀ yunifásítì kó má ní ti Bíbélì lọ.”
Lónìí, iṣẹ́ ribiribi làwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì yíká ayé. Ẹ̀kọ́ táa ń wí yìí kọjá ti ìwé kíkà àti ìwé kíkọ o. Ó ń sọni di géńdé ní ti èrò orí àti ti ìwà rere. Ó ń ní ipa rere lórí ìfojúsọ́nà àwọn ènìyàn fún ọjọ́ iwájú, ó ń pèsè ìpìlẹ̀ fún ìrètí gúnmọ́, pé ohun tó wà lọ́jọ́ iwájú sàn fíìfíì ju ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ látẹ̀yìnwá lọ.
Jọ̀wọ́ kà nípa ètò ẹ̀kọ́ tí ń fúnni ní ìyè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.