ÌBÉÈRÈ 5
Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
“Màá mú kí ìwọ àti obìnrin náà di ọ̀tá ara yín, ọmọ rẹ àti ọmọ rẹ̀ yóò sì di ọ̀tá. Òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì ṣe é léṣe ní gìgísẹ̀.”
“Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé yóò gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ ọmọ rẹ torí pé o fetí sí ohùn mi.”
“Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.”
“Ní tirẹ̀, Ọlọ́run tó ń fúnni ní àlàáfíà máa mú kí ẹsẹ̀ yín tẹ Sátánì rẹ́ láìpẹ́.”
“Nígbà tí a bá ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán, ìgbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ á fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún kálukú.”
“Àwọn ìlérí náà la sọ fún Ábúráhámù àti fún ọmọ rẹ̀ . . . , tó jẹ́ Kristi. Yàtọ̀ síyẹn, bí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, ẹ jẹ́ ọmọ Ábúráhámù lóòótọ́.”
“Ìjọba ayé ti di Ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀, ó sì máa jọba títí láé àti láéláé.”
“A wá ju dírágónì ńlá náà sísàlẹ̀, ejò àtijọ́ náà, ẹni tí à ń pè ní Èṣù àti Sátánì, tó ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé lọ́nà; a jù ú sí ayé, a sì ju àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”
“Ó gbá dírágónì náà mú, ejò àtijọ́ náà, òun ni Èṣù àti Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.”