ÌBÉÈRÈ 17
Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́?
ỌKỌ TÀBÍ BÀBÁ
“Lọ́nà kan náà, kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn bí ara wọn. Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, torí pé kò sí èèyàn kankan tó jẹ́ kórìíra ara rẹ̀, àmọ́ á máa bọ́ ara rẹ̀, á sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ . . . Kí kálukú yín nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.”
“Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa tọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.”
ÌYÀWÓ
“Kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”
“Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ yín, bó ṣe yẹ nínú Olúwa.”
ỌMỌ
“Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu nínú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo. ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,’ èyí ni àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí: ‘Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí o sì lè pẹ́ láyé.’”
“Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu nínú ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi lójú Olúwa.”