ÌBÉÈRÈ 6
Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà?
ÀSỌTẸ́LẸ̀
“Ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà, . . . inú rẹ ni ẹni tí mo fẹ́ kó ṣàkóso Ísírẹ́lì ti máa jáde wá.”
ÌMÚṢẸ
“Lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà ní àwọn ọjọ́ Ọba Hẹ́rọ́dù, wò ó! àwọn awòràwọ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù láti Ìlà Oòrùn.”
ÀSỌTẸ́LẸ̀
“Wọ́n pín ẹ̀wù mi láàárín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ kèké nítorí aṣọ mi.”
ÌMÚṢẸ
“Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun kan Jésù mọ́gi tán, wọ́n mú aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, wọ́n pín in sí mẹ́rin . . . Àmọ́ aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà ò ní ojú rírán, ṣe ni wọ́n hun ún látòkè délẹ̀. Torí náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ ká ya á, àmọ́ ẹ jẹ́ ká fi kèké pinnu ti ẹni tó máa jẹ́.’”
ÀSỌTẸ́LẸ̀
“Ó ń dáàbò bo gbogbo egungun rẹ̀; kò sí ìkankan nínú wọn tí a ṣẹ́.”
ÌMÚṢẸ
“Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n rí i pé ó ti kú, torí náà, wọn ò ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”
ÀSỌTẸ́LẸ̀
“Wọ́n gún un torí àṣìṣe wa.”
ÌMÚṢẸ
“Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”
ÀSỌTẸ́LẸ̀
“Wọ́n . . . san owó iṣẹ́ mi, ó jẹ́ ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà.”
ÌMÚṢẸ
“Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn Méjìlá náà, tí wọ́n ń pè ní Júdásì Ìsìkáríọ́tù, lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, ó sì sọ pé: ‘Kí lẹ máa fún mi, kí n lè fà á lé yín lọ́wọ́?’ Wọ́n bá a ṣe àdéhùn ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà.”