Sekaráyà 3:1-10

  • Ìran 4: Wọ́n fún àlùfáà àgbà ní aṣọ míì (1-10)

    • Sátánì ta ko Àlùfáà Àgbà Jóṣúà (1)

    • ‘Màá mú ìránṣẹ́ mi tó ń jẹ́ Èéhù wá!’ (8)

3  Ó sì fi Jóṣúà + tó jẹ́ àlùfáà àgbà hàn mí, ó dúró níwájú áńgẹ́lì Jèhófà, Sátánì+ sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kó lè ta kò ó.  Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún Sátánì pé: “Kí Jèhófà bá ọ wí, ìwọ Sátánì,+ bẹ́ẹ̀ ni, kí Jèhófà, ẹni tó yan Jerúsálẹ́mù+ bá ọ wí! Ṣebí ẹni yìí ni igi tó ń jó tí wọ́n yọ kúrò nínú iná?”  Aṣọ ọrùn Jóṣúà dọ̀tí, ó sì dúró níwájú áńgẹ́lì náà.  Áńgẹ́lì náà sọ fún àwọn tó dúró níwájú rẹ̀ pé: “Ẹ bọ́ aṣọ ìdọ̀tí tó wà lọ́rùn rẹ̀.” Ó wá sọ fún un pé: “Wò ó, mo ti mú ẹ̀ṣẹ̀* rẹ kúrò, ìwọ yóò sì wọ aṣọ tó mọ́.”*+  Torí náà, mo sọ pé: “Ẹ fi láwàní tó mọ́ wé e lórí.”+ Wọ́n fi láwàní náà wé e lórí, wọ́n sì wọ aṣọ fún un; áńgẹ́lì Jèhófà sì dúró nítòsí.  Áńgẹ́lì Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé:  “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Tí o bá rìn ní àwọn ọ̀nà mi, tí o sì ń ṣe ojúṣe rẹ sí mi, ìwọ yóò di adájọ́ ní ilé mi,+ ìwọ yóò sì máa bójú tó* àwọn àgbàlá mi; èmi yóò sì fún ọ láǹfààní bíi ti àwọn tó dúró síbí.’  “‘Àlùfáà Àgbà Jóṣúà, jọ̀ọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ àti àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n jókòó níwájú rẹ, torí àwọn ọkùnrin yìí jẹ́ àmì; wò ó! mò ń mú ìránṣẹ́ mi+ tó ń jẹ́ Èéhù+ bọ̀!  Wo òkúta tí mo fi síwájú Jóṣúà! Ojú méje ló wà lára òkúta náà; èmi yóò kọ nǹkan sí ara rẹ̀, èmi yóò sì mú ẹ̀bi ilẹ̀ náà kúrò ní ọjọ́ kan ṣoṣo,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.+ 10  “‘Ní ọjọ́ yẹn, kálukú yín yóò pe aládùúgbò rẹ̀ pé kó wá sí abẹ́ àjàrà àti abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ òun,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ẹ̀bi.”
Tàbí “aṣọ ìgúnwà.”
Tàbí “tọ́jú; ṣọ́.”