Sáàmù 8:1-9

  • Ògo Ọlọ́run àti iyì ọmọ èèyàn

    • ‘Orúkọ rẹ mà níyì o!’ (1, 9)

    • ‘Kí ni ẹni kíkú jẹ́?’ (4)

    • A fi ọlá ńlá dé èèyàn ládé (5)

Sí olùdarí; lórí Gítítì.* Orin Dáfídì. 8  Jèhófà Olúwa wa, orúkọ rẹ mà níyì ní gbogbo ayé o;O ti gbé ògo rẹ ga, kódà ó ga ju ọ̀run lọ!*+   O fìdí agbára rẹ múlẹ̀ láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ jòjòló+Nítorí àwọn elénìní rẹ,Kí o lè pa ọ̀tá àti olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.   Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ,Òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti ṣètò sílẹ̀,+   Kí ni ẹni kíkú jẹ́ tí o fi ń fi í sọ́kànÀti ọmọ aráyé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?+   O mú kó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ẹni bí Ọlọ́run,*O sì fi ògo àti ọlá ńlá dé e ládé.   O fún un ní àṣẹ lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;+O ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:   Gbogbo àwọn agbo ẹran àti màlúù,Àti àwọn ẹran inú igbó,*+   Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú òkun,Ohunkóhun tó ń gba inú òkun kọjá.   Jèhófà Olúwa wa, orúkọ rẹ mà níyì ní gbogbo ayé o!

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “Ìwọ tí à ń ròyìn iyì rẹ lókè ọ̀run.”
Tàbí “àwọn áńgẹ́lì.”
Ní Héb., “àwọn ẹranko inú pápá.”