Sáàmù 55:1-23
Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Másíkílì.* Ti Dáfídì.
55 Gbọ́ àdúrà mi, Ọlọ́run,+Má sì ṣàìka ẹ̀bẹ̀ àánú mi sí.*+
2 Fiyè sí mi, kí o sì dá mi lóhùn.+
Àníyàn mi ò jẹ́ kí n ní ìsinmi,+Ọkàn mi ò sì balẹ̀
3 Nítorí ohun tí ọ̀tá ń sọÀti bí ẹni burúkú ṣe ń dà mí láàmú.
Wọ́n ń rọ̀jò wàhálà lé mi lórí,Wọ́n sì dì mí sínú torí pé wọ́n ń bínú mi.+
4 Ọkàn mi ń jẹ̀rora nínú mi,+Jìnnìjìnnì ikú sì bò mí.+
5 Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì dé bá mi,Gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.
6 Mò ń sọ pé: “Ká ní mo ní ìyẹ́ apá bí àdàbà ni!
Mi ò bá fò lọ, mi ò bá sì máa gbé lábẹ́ ààbò.
7 Wò ó! Màá lọ jìnnà réré.+
Màá lọ máa gbé inú aginjù.+ (Sélà)
8 Màá yára lọ sí ibi tó láàbòKúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù líle àti kúrò lọ́wọ́ ìjì.”
9 Da èrò wọn rú, Jèhófà, sì mú kí èrò wọn já sófo,*+Nítorí mo ti rí ìwà ipá àti ìjà nínú ìlú náà.
10 Tọ̀sántòru ni wọ́n ń rìn kiri lórí ògiri rẹ̀;Èrò ibi àti ìjàngbọ̀n ló wà nínú rẹ̀.+
11 Ìparun wà nínú rẹ̀;Ìnilára àti ẹ̀tàn kì í kúrò ní ojúde rẹ̀.+
12 Kì í ṣe ọ̀tá ló ń pẹ̀gàn mi;+Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, mi ò bá fara dà á.
Kì í ṣe elénìní ló dìde sí mi;Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, mi ò bá sá pa mọ́ fún un.
13 Àmọ́ ìwọ ni, èèyàn bíi tèmi,*+Alábàákẹ́gbẹ́ mi tí mo mọ̀ dáadáa.+
14 Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni wá tẹ́lẹ̀, a sì gbádùn ọ̀rẹ́ wa;A máa ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn rìn lọ sí ilé Ọlọ́run.
15 Kí ìparun dé bá wọn!+
Kí wọ́n wọnú Isà Òkú* láàyè;Nítorí ìwà ibi wà láàárín wọn, ó sì ń gbé inú wọn.
16 Ní tèmi, màá ké pe Ọlọ́run,Jèhófà yóò sì gbà mí sílẹ̀.+
17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán, ìdààmú bá mi, mò ń kérora,*+Ó sì ń gbọ́ ohùn mi.+
18 Yóò gbà mí sílẹ̀* lọ́wọ́ àwọn tó ń bá mi jà, yóò sì jẹ́ kí n* ní àlàáfíà,Nítorí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ló ń gbéjà kò mí.+
19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì fún wọn lésì,+Ẹni tó ti ń jókòó lórí ìtẹ́ tipẹ́tipẹ́.+ (Sélà)
Wọn ò ní yí pa dà,Àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run.+
20 Ó* gbéjà ko àwọn tó wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀;+Ó da májẹ̀mú rẹ̀.+
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ jọ̀lọ̀ ju bọ́tà lọ,+Àmọ́ ìjà ló wà lọ́kàn rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tuni lára ju òróró lọ,Àmọ́ idà tí a fà yọ ni wọ́n.+
22 Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà,+Yóò sì gbé ọ ró.+
Kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú* láé.+
23 Àmọ́ ìwọ, Ọlọ́run, yóò rẹ̀ wọ́n wálẹ̀ sínú kòtò tó jìn jù lọ.+
Àwọn tó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́tàn kò ní lo ààbọ̀ ọjọ́ ayé wọn.+
Àmọ́ ní tèmi, màá gbẹ́kẹ̀ lé ọ.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “Má sì fara pa mọ́ nígbà tí mo bá bẹ̀ ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.”
^ Ní Héb., “pín ahọ́n wọn níyà.”
^ Tàbí “èèyàn, tí a jọ jẹ́ ẹgbẹ́.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “kígbe.”
^ Ní Héb., “rà mí pa dà.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Ìyẹn, ọ̀rẹ́ àtijọ́ tí ẹsẹ 13 àti 14 sọ.
^ Tàbí “ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́; ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”