Sáàmù 40:1-17
Sí olùdarí. Ti Dáfídì. Orin.
40 Taratara ni mo fi* dúró de Jèhófà,Ó fetí sí mi,* ó sì gbọ́ igbe mi fún ìrànlọ́wọ́.+
2 Ó gbé mi jáde látinú kòtò tó ní ìró omi púpọ̀,Láti inú ẹrẹ̀.
Ó sì fi ẹsẹ̀ mi lé orí àpáta;Ó fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ ṣinṣin.
3 Ó wá fi orin tuntun sí mi lẹ́nu,+Ìyìn sí Ọlọ́run wa.
Ọ̀pọ̀ èèyàn á rí nǹkan yìí, ẹ̀rù Ọlọ́run á bà wọ́n,Wọ́n á sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
4 Aláyọ̀ ni ọkùnrin tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,Tí kò sì yíjú sí àwọn aláfojúdi tàbí àwọn ẹlẹ́tàn.*
5 Wo bí àwọn ohun tí o ṣe ti pọ̀ tó,Jèhófà Ọlọ́run mi,Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti èrò rẹ sí wa.+
Kò sí ẹni tí a lè fi ọ́ wé;+Tí mo bá ní kí n máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn,Wọ́n pọ̀ ju ohun tí mo lè ròyìn!+
6 Ẹbọ àti ọrẹ kọ́ ni ohun tó wù ọ́,*+Àmọ́ o la etí mi sílẹ̀ kí n lè gbọ́.+
O kò béèrè ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+
7 Lẹ́yìn náà, mo sọ pé: “Wò ó, mo ti dé.
A ti kọ ọ́ nípa mi sínú àkájọ ìwé.+
8 Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run mi, ni inú mi dùn sí,*+Òfin rẹ sì wà nínú mi lọ́hùn-ún.+
9 Mo kéde ìhìn rere òdodo nínú ìjọ ńlá.+
Wò ó! Mi ò pa ẹnu mi mọ́,+Bí ìwọ náà ṣe mọ̀ dáadáa, Jèhófà.
10 Mi ò bo òdodo rẹ mọ́lẹ̀ nínú ọkàn mi.
Mo kéde ìṣòtítọ́ rẹ àti ìgbàlà rẹ.
Mi ò fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ pa mọ́ nínú ìjọ ńlá.”+
11 Jèhófà, má ṣe fawọ́ àánú rẹ sẹ́yìn lórí mi.
Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ máa dáàbò bò mí nígbà gbogbo.+
12 Àwọn àjálù tó yí mi ká kò ṣeé kà.+
Àwọn àṣìṣe mi pọ̀ débi pé mi ò tiẹ̀ mọ ibi tí mo forí lé;+Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,Ìrẹ̀wẹ̀sì sì ti bá ọkàn mi.
13 Jọ̀ọ́ Jèhófà, jẹ́ kó wù ọ́ láti gbà mí sílẹ̀.+
Jèhófà, tètè wá ràn mí lọ́wọ́.+
14 Kí ìtìjú àti ẹ̀tẹ́ báGbogbo àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi.*
Kí àwọn tí inú wọn ń dùn sí àjálù tó bá miSá pa dà nínú ẹ̀tẹ́.
15 Ní ti àwọn tó ń sọ nípa mi pé: “Àháà! Àháà!”
Kí jìnnìjìnnì bò wọ́n nítorí ìtìjú tó dé bá wọn.
16 Àmọ́ kí àwọn tó ń wá ọ+Máa yọ̀, kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ.+
Kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ máa sọ nígbà gbogbo pé:
“Ẹ gbé Jèhófà ga.”+
17 Àmọ́ aláìní ni mí, mi ò sì ní olùrànlọ́wọ́;Kí Jèhófà fiyè sí mi.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi àti olùgbàlà mi;+Ọlọ́run mi, má ṣe jẹ́ kó pẹ́.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Mo fi sùúrù.”
^ Tàbí “Ó tẹ̀ ba láti gbọ́ mi.”
^ Tàbí “onírọ́.”
^ Tàbí “kọ́ ló ń múnú rẹ dùn.”
^ Tàbí “ni ó wù mí.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”