Oníwàásù 9:1-18
9 Nítorí náà, mo fọkàn sí gbogbo èyí, mo sì gbà pé ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́ ni àwọn olódodo àti àwọn ọlọ́gbọ́n wà pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.+ Àwọn èèyàn kò mọ ìfẹ́ àti ìkórìíra tó ti wà ṣáájú wọn.
2 Ohun kan náà ló ń gbẹ̀yìn* gbogbo wọn,+ àti olódodo àti ẹni burúkú,+ ẹni rere pẹ̀lú ẹni tó mọ́ àti ẹni tí ò mọ́, àwọn tó ń rúbọ àti àwọn tí kì í rúbọ. Ìkan náà ni ẹni rere àti ẹlẹ́ṣẹ̀; bákan náà ni ẹni tó búra rí pẹ̀lú ẹni tó ń bẹ̀rù láti búra.
3 Ohun kan ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run* tó ń kó ìdààmú báni: Nítorí ohun* kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn,+ aburú ló kún ọkàn àwọn ọmọ èèyàn; ìwà wèrè wà lọ́kàn wọn ní ọjọ́ ayé wọn, lẹ́yìn náà wọ́n á kú!*
4 Ìrètí wà fún ẹni tó bá ṣì wà láàyè, nítorí ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ.+
5 Nítorí àwọn alààyè mọ̀* pé àwọn máa kú,+ àmọ́ àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá,+ wọn kò sì ní èrè* kankan mọ́, nítorí pé wọ́n ti di ẹni ìgbàgbé.+
6 Bákan náà, ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn pẹ̀lú owú wọn ti ṣègbé, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ nínú ohun tí à ń ṣe lábẹ́ ọ̀run.*+
7 Máa lọ, máa fi ayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ, kí o sì máa fi ìdùnnú mu wáìnì rẹ,+ nítorí inú Ọlọ́run tòótọ́ ti dùn sí àwọn iṣẹ́ rẹ.+
8 Kí aṣọ rẹ máa funfun* ní gbogbo ìgbà, kí o sì máa fi òróró pa orí rẹ.+
9 Máa gbádùn ayé rẹ pẹ̀lú aya rẹ ọ̀wọ́n+ ní gbogbo ọjọ́ ayé asán rẹ, tí Ó fún ọ lábẹ́ ọ̀run,* ní gbogbo ọjọ́ ayé asán rẹ, torí ìyẹn ni ìpín rẹ nígbèésí ayé àti nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ, èyí tí ò ń fi gbogbo agbára rẹ ṣe lábẹ́ ọ̀run.+
10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú,*+ ibi tí ìwọ ń lọ.
11 Mo tún ti rí nǹkan míì lábẹ́ ọ̀run,* pé ìgbà gbogbo kọ́ ni ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá máa ń mókè nínú eré ìje, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn alágbára máa ń borí lójú ogun,+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọlọ́gbọ́n kì í fìgbà gbogbo rí oúnjẹ jẹ, ìgbà gbogbo kọ́ sì ni àwọn olórí pípé máa ń ní ọrọ̀,+ bákan náà àwọn tó ní ìmọ̀ kì í fìgbà gbogbo ṣe àṣeyọrí,+ nítorí ìgbà àti èèṣì* ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.
12 Èèyàn kò mọ ìgbà tirẹ̀.+ Bí ẹja ṣe ń kó sínú àwọ̀n ikú, tí àwọn ẹyẹ sì ń kó sínú pańpẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èèyàn ṣe ń kó sínú ìdẹkùn ní àkókò àjálù, nígbà tó bá dé bá wọn lójijì.
13 Mo tún kíyè sí nǹkan kan nípa ọgbọ́n lábẹ́ ọ̀run,* ó sì wú mi lórí:
14 Ìlú kékeré kan wà tí èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí; ọba alágbára kan wá gbéjà kò ó, ó yí i ká, ó sì ṣe àwọn nǹkan ńlá tí á fi gbógun ti ìlú náà.
15 Ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó jẹ́ aláìní àmọ́ tó ní ọgbọ́n, ó sì fi ọgbọ́n rẹ̀ gba ìlú náà sílẹ̀. Àmọ́ kò sẹ́ni tó rántí ọkùnrin aláìní náà.+
16 Mo wá sọ fún ara mi pé: ‘Ọgbọ́n sàn ju agbára lọ;+ síbẹ̀ àwọn èèyàn kì í ka ọgbọ́n aláìní sí, wọn kì í sì í ṣe ohun tó bá sọ.’+
17 Ó sàn kéèyàn tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí ọlọ́gbọ́n sọ ju kéèyàn máa fetí sí ariwo ẹni tó ń ṣàkóso láàárín àwọn òmùgọ̀.
18 Ọgbọ́n sàn ju àwọn ohun ìjà ogun lọ, àmọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ṣoṣo lè ba ọ̀pọ̀ ohun rere jẹ́.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Àtúbọ̀tán kan náà ló wà fún.”
^ Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
^ Tàbí “àtúbọ̀tán.”
^ Ní Héb., “lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ àwọn òkú yá!”
^ Tàbí “mọ̀ dáadáa.”
^ Tàbí “owó iṣẹ́.”
^ Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
^ Ìyẹn, aṣọ tí àwọ̀ rẹ̀ ń tàn tó fi hàn pé inú èèyàn ń dùn, kì í ṣe aṣọ ọ̀fọ̀.
^ Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.”
^ Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
^ Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”