Nọ́ńbà 29:1-40
29 “‘Ní ọjọ́ kìíní oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára + kankan. Kí ẹ fun kàkàkí+ ní ọjọ́ náà.
2 Kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù kan wá pẹ̀lú àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ sísun tó ń mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,
3 pẹ̀lú ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà wọn, ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà fún akọ màlúù náà, ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún àgbò náà,
4 pẹ̀lú ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà
5 àti akọ ọmọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún yín.
6 Èyí jẹ́ àfikún sí ẹbọ sísun oṣooṣù àti ọrẹ ọkà+ rẹ̀ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà+ rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọrẹ ohun mímu+ wọn, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é, láti mú òórùn dídùn* jáde, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
7 “‘Kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́+ ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí, kí ẹ sì pọ́n ara yín* lójú. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.+
8 Kí ẹ sì mú akọ ọmọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan wá láti fi rú ẹbọ sísun tó ń mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá.+
9 Kí ọrẹ ọkà wọn sì jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró, ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù náà, ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún àgbò náà,
10 ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà,
11 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù+ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọrẹ ohun mímu wọn.
12 “‘Ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Ẹ má ṣe iṣẹ́ agbára kankan, kí ẹ sì fi ọjọ́ méje+ ṣe àjọyọ̀ fún Jèhófà.
13 Kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù mẹ́tàlá (13) wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ sísun,+ ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà. Kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá.+
14 Kí ọrẹ ọkà wọn sì jẹ́ ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró, ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù mẹ́tàlá (13) náà, ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àgbò méjì náà
15 àti ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) náà
16 àti ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ọrẹ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
17 “‘Ní ọjọ́ kejì, kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù méjìlá (12) wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+
18 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é,
19 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọrẹ ohun mímu+ wọn.
20 “‘Ní ọjọ́ kẹta, kí ẹ mú akọ màlúù mọ́kànlá (11) wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+
21 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é,
22 pẹ̀lú ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
23 “‘Ní ọjọ́ kẹrin, kí ẹ mú akọ màlúù mẹ́wàá wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+
24 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é,
25 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ọrẹ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
26 “‘Ní ọjọ́ karùn-ún, kí ẹ mú akọ màlúù mẹ́sàn-án wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+
27 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é,
28 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
29 “‘Ní ọjọ́ kẹfà, kí ẹ mú akọ màlúù mẹ́jọ wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+
30 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é,
31 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ọrẹ ọkà rẹ̀ àti àwọn ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
32 “‘Ní ọjọ́ keje, kí ẹ mú akọ màlúù méje wá pẹ̀lú àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá (14) tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+
33 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é,
34 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ọrẹ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
35 “‘Ní ọjọ́ kẹjọ, kí ẹ ṣe àpéjọ ọlọ́wọ̀. Ẹ má ṣe iṣẹ́ agbára kankan.+
36 Kí ẹ mú akọ màlúù kan wá pẹ̀lú àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan láti fi rú ẹbọ sísun, ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá,+
37 pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti àwọn ọrẹ ohun mímu tó wà fún àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn bí wọ́n bá ṣe pọ̀ tó, bí ẹ ṣe máa ń ṣe é,
38 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀, pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu+ rẹ̀.
39 “‘Èyí ni àwọn ohun tí ẹ máa fi rúbọ sí Jèhófà nígbà àwọn àjọyọ̀+ yín àtìgbàdégbà, ní àfikún sí àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́+ àti àwọn ọrẹ àtinúwá+ yín láti fi rú àwọn ẹbọ sísun+ yín àti àwọn ọrẹ ọkà+ yín pẹ̀lú àwọn ọrẹ ohun mímu+ yín àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ yín.’”
40 Mósè sọ gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
^ Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
^ Tàbí “ọkàn yín.” Kí èèyàn “pọ́n ara rẹ̀ lójú” sábà máa ń túmọ̀ sí kí èèyàn fi oríṣiríṣi nǹkan du ara rẹ̀, irú bíi kó gbààwẹ̀.
^ Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
^ Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
^ Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”