Àkọsílẹ̀ Lúùkù 3:1-38
3 Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún àkóso Tìbéríù Késárì, nígbà tí Pọ́ńtíù Pílátù jẹ́ gómìnà Jùdíà, tí Hẹ́rọ́dù*+ sì jẹ́ alákòóso agbègbè* Gálílì, tí Fílípì arákùnrin rẹ̀ jẹ́ alákòóso agbègbè ilẹ̀ Ítúréà àti Tírákónítì, tí Lísáníà sì jẹ́ alákòóso agbègbè Ábílénè,
2 nígbà ayé Ánásì olórí àlùfáà àti Káyáfà,+ Jòhánù+ ọmọ Sekaráyà gbọ́ ìkéde látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nínú aginjù.+
3 Ó wá lọ sí gbogbo ìgbèríko tó yí Jọ́dánì ká, ó ń wàásù pé kí àwọn èèyàn ṣèrìbọmi láti fi hàn pé wọ́n ti ronú pìwà dà, kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà,+
4 bí a ṣe kọ ọ́ sínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Àìsáyà pé: “Ohùn ẹnì kan ń ké nínú aginjù pé: ‘Ẹ ṣètò ọ̀nà Jèhófà!* Ẹ mú àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́.+
5 Gbogbo àfonífojì gbọ́dọ̀ ga sókè, kí gbogbo òkè ńlá àti òkè kéékèèké tẹ́jú; àwọn ọ̀nà tó wọ́ gbọ́dọ̀ tọ́, kí àwọn ọ̀nà tó rí gbágungbàgun sì dán;
6 gbogbo ẹran ara* sì máa rí ìgbàlà Ọlọ́run.’”*+
7 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn èrò tó ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ṣèrìbọmi pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, ta ló kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ sá fún ìbínú tó ń bọ̀?+
8 Torí náà, ẹ so èso tó yẹ ìrònúpìwàdà. Ẹ má bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ara yín pé, ‘A ní Ábúráhámù ní baba.’ Torí mò ń sọ fún yín pé Ọlọ́run lè gbé àwọn ọmọ dìde fún Ábúráhámù látinú àwọn òkúta yìí.
9 Ó dájú pé àáké ti wà níbi gbòǹgbò àwọn igi báyìí. Torí náà, gbogbo igi tí kò bá so èso tó dáa la máa gé lulẹ̀, tí a sì máa jù sínú iná.”+
10 Àwọn èrò náà wá ń bi í pé: “Kí wá ni ká ṣe?”
11 Ó sọ fún wọn pé: “Kí ẹni tó ní aṣọ méjì* fún ẹni tí kò ní lára aṣọ rẹ̀, kí ẹni tó sì ní ohun tó máa jẹ ṣe ohun kan náà.”+
12 Kódà, àwọn agbowó orí wá, kí wọ́n lè ṣèrìbọmi,+ wọ́n sì sọ fún un pé: “Olùkọ́, kí ni ká ṣe?”
13 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má gbà* ju iye owó orí lọ.”+
14 Bákan náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ológun ń bi í pé: “Kí ni ká ṣe?” Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe fòòró ẹnikẹ́ni* tàbí kí ẹ fẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni,+ àmọ́ ẹ jẹ́ kí àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbà* tẹ́ yín lọ́rùn.”
15 Àwọn èèyàn náà ń fojú sọ́nà, gbogbo wọn sì ń ronú nípa Jòhánù lọ́kàn wọn pé, “Àbí òun ni Kristi náà?”+
16 Jòhánù dá wọn lóhùn, ó sọ fún gbogbo wọn pé: “Ní tèmi, mò ń fi omi batisí yín, àmọ́ ẹni tó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, ẹni tí mi ò tó tú okùn bàtà rẹ̀.+ Ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ àti iná batisí yín.+
17 Ṣọ́bìrì tó fi ń fẹ́ ọkà wà lọ́wọ́ rẹ̀, kó lè gbá ibi ìpakà rẹ̀ mọ́ tónítóní, kó sì kó àlìkámà* jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí rẹ̀, àmọ́ ó máa fi iná tí kò ṣeé pa sun ìyàngbò.”*
18 Ó tún gba àwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyànjú míì, ó sì ń kéde ìhìn rere fún àwọn èèyàn.
19 Àmọ́ torí pé Jòhánù ti bá Hẹ́rọ́dù alákòóso agbègbè náà wí nípa Hẹrodíà ìyàwó arákùnrin rẹ̀ àti nípa gbogbo ohun burúkú tí Hẹ́rọ́dù ṣe,
20 ó tún fi èyí kún gbogbo ohun tó ṣe yẹn: Ó ti Jòhánù mọ́nú ẹ̀wọ̀n.+
21 Nígbà tí gbogbo àwọn èèyàn náà ṣèrìbọmi, Jésù náà ṣèrìbọmi.+ Bó ṣe ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀,+
22 ẹ̀mí mímọ́ bà lé e, ẹ̀mí náà rí bí àdàbà, ohùn kan sì dún láti ọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, àyànfẹ́; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”+
23 Nǹkan bí ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún+ ni Jésù+ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀, bí wọ́n sì ṣe rò, ó jẹ́ ọmọJósẹ́fù,+ọmọ Hélì,
24 ọmọ Mátátì,ọmọ Léfì,ọmọ Mélíkì,ọmọ Jánááì,ọmọ Jósẹ́fù,
25 ọmọ Mátátíà,ọmọ Émọ́sì,ọmọ Náhúmù,ọmọ Ésílì,ọmọ Nágáì,
26 ọmọ Máátì,ọmọ Mátátíà,ọmọ Séméínì,ọmọ Jósẹ́kì,ọmọ Jódà,
27 ọmọ Jóánánì,ọmọ Résà,ọmọ Serubábélì,+ọmọ Ṣéálítíẹ́lì,+ọmọ Nẹ́rì,
28 ọmọ Mélíkì,ọmọ Ádì,ọmọ Kósámù,ọmọ Élímádámù,ọmọ Éérì,
29 ọmọ Jésù,ọmọ Élíésérì,ọmọ Jórímù,ọmọ Mátátì,ọmọ Léfì,
30 ọmọ Símíónì,ọmọ Júdásì,ọmọ Jósẹ́fù,ọmọ Jónámù,ọmọ Élíákímù,
31 ọmọ Méléà,ọmọ Ménà,ọmọ Mátátà,ọmọ Nátánì,+ọmọ Dáfídì,+
32 ọmọ Jésè,+ọmọ Óbédì,+ọmọ Bóásì,+ọmọ Sálímọ́nì,+ọmọ Náṣónì, +
33 ọmọ Ámínádábù,ọmọ Áánì,ọmọ Hésírónì,ọmọ Pérésì,+ọmọ Júdà,+
34 ọmọ Jékọ́bù, +ọmọ Ísákì,+ọmọ Ábúráhámù,+ọmọ Térà,+ọmọ Náhórì,+
35 ọmọ Sérúgù,+ọmọ Réù,+ọmọ Pélégì, +ọmọ Ébérì,+ọmọ Ṣélà,+
36 ọmọ Káínánì,ọmọ Ápákíṣádì,+ọmọ Ṣémù,+ọmọ Nóà,+ọmọ Lámékì,+
37 ọmọ Mètúsélà, +ọmọ Énọ́kù,ọmọ Járédì,+ọmọ Máháláléélì,+ọmọ Káínánì,+
38 ọmọ Énọ́ṣì,+ọmọ Sẹ́ẹ̀tì,+ọmọ Ádámù,+ọmọ Ọlọ́run.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “alákòóso ìdá mẹ́rin.”
^ Ìyẹn, Hẹ́rọ́dù Áńtípà. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “gbogbo èèyàn.”
^ Tàbí “ohun tí Ọlọ́run fi máa gbani là.”
^ Tàbí “aṣọ míì.”
^ Tàbí “fipá béèrè.”
^ Tàbí “rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ.”
^ Tàbí “owó iṣẹ́ yín.”
^ Tàbí “wíìtì.”
^ Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.