Jóòbù 37:1-24

  • Àwọn ohun tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ bó ṣe tóbi tó (1-24)

    • Ọlọ́run lè fòpin sáwọn ohun téèyàn ń ṣe (7)

    • “Ronú nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run” (14)

    • Ó kọjá agbára èèyàn láti lóye Ọlọ́run (23)

    • Kí èèyàn kankan má rò pé òun gbọ́n (24)

37  “Èyí mú kí ọkàn mi lù kìkì,Ó sì ń fò sókè láti àyè rẹ̀.   Ẹ fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohùn rẹ̀ tó ń kù rìrì,Àti ààrá tó ń ti ẹnu rẹ̀ jáde.   Ó ń tú u jáde lábẹ́ gbogbo ọ̀run,Ó sì ń rán mànàmáná+ rẹ̀ lọ dé àwọn ìkángun ayé.   Lẹ́yìn náà ni ìró tó ń bú ramúramù;Ó ń fi ohùn tó ga lọ́lá sán ààrá,+Kì í sì í dá a dúró tí wọ́n bá gbọ́ ohùn rẹ̀.   Ọlọ́run ń fi ohùn rẹ̀ sán ààrá+ lọ́nà àgbàyanu;Ó ń ṣe àwọn ohun ńlá tí kò lè yé wa.+   Nítorí ó sọ fún yìnyín pé, ‘Rọ̀ sórí ayé,’+Ó sì sọ fún ọ̀wààrà òjò pé, ‘Rọ̀ sílẹ̀ rẹpẹtẹ.’+   Ọlọ́run fòpin sí gbogbo ohun tí èèyàn ń ṣe,*Kí gbogbo ẹni kíkú lè mọ iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ̀.   Àwọn ẹran igbó lọ sí ibùba wọn,Wọn ò sì kúrò ní ibùgbé wọn.   Ìjì ń fẹ́ wá láti àyè rẹ̀,+Òtútù sì ń wá látinú atẹ́gùn àríwá.+ 10  Èémí Ọlọ́run ń mú kí omi dì,+Omi tó lọ salalu sì máa ń dì gbagidi.+ 11  Àní, ó fi ìrì sínú àwọsánmà* kó lè wúwo;Ó fọ́n ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká+ sínú àwọsánmà;* 12  Wọ́n ń lọ yí ká sáwọn ibi tó ń darí wọn sí;Wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tó bá pa láṣẹ+ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.* 13  Ì báà jẹ́ torí ìyà*+ tàbí torí ilẹ̀ náà,Tàbí torí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ó ń mú kó wáyé.+ 14  Fetí sí èyí, Jóòbù;Dúró, kí o sì fara balẹ̀ ronú nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run.+ 15  Ṣé o mọ bí Ọlọ́run ṣe ń darí* àwọsánmà*Àti bó ṣe ń mú kí mànàmáná kọ yẹ̀rì látinú àwọsánmà* rẹ̀? 16  Ṣé o mọ bí àwọsánmà* ṣe ń léfòó?+ Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ pé nìyí.+ 17  Kí ló dé tí aṣọ rẹ ń gbóná,Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù mú kí ayé dúró jẹ́ẹ́?+ 18  Ṣé ìwọ, pẹ̀lú rẹ̀, lè na òfúrufú jáde,*+Kó dúró gbagidi bíi dígí onírin? 19  Sọ fún wa, ohun tí a máa sọ fún un;A ò lè fèsì torí inú òkùnkùn la wà. 20  Ṣé ó yẹ ká sọ fún un pé mo fẹ́ sọ̀rọ̀ ni? Àbí ẹnì kankan sọ̀rọ̀ tó yẹ ká lọ sọ fún un?+ 21  Wọn ò lè rí ìmọ́lẹ̀* pàápàá,Bó tiẹ̀ mọ́lẹ̀ yòò lójú ọ̀run,Títí atẹ́gùn fi kọjá tó sì fẹ́ ìkùukùu* lọ. 22  Iyì tó ń tàn bíi wúrà jáde wá láti àríwá;Ògo Ọlọ́run+ yẹ ní ohun tí à ń bẹ̀rù. 23  Ó kọjá agbára wa láti lóye Olódùmarè;+Agbára rẹ̀ pọ̀ gan-an,+Kì í ṣe ohun tó lòdì sí ìdájọ́ òdodo+ rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ tó pọ̀ gidigidi.+ 24  Torí náà, ó yẹ kí àwọn èèyàn bẹ̀rù rẹ̀.+ Torí kì í ṣe ojúure sí ẹnikẹ́ni tó gbọ́n lójú ara rẹ̀.”*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “fi èdìdì sí ọwọ́ gbogbo èèyàn.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “ilẹ̀ eléso ní ayé.”
Ní Héb., “ọ̀pá.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “pàṣẹ fún.”
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “rọ òfúrufú.”
Ìyẹn, ìmọ́lẹ̀ oòrùn.
Tàbí “àwọsánmà.”
Ní Héb., “tó gbọ́n ní ọkàn.”