Hábákúkù 1:1-17

  • Wòlíì náà ké pe Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ (1-4)

    • “Jèhófà, báwo ló ṣe máa pẹ́ tó?” (2)

    • ‘Kí nìdí tí o fi fàyè gba ìnilára?’ (3)

  • Ọlọ́run lo àwọn ará Kálídíà láti ṣèdájọ́ (5-11)

  • Wòlíì náà bẹ Jèhófà (12-17)

    • ‘Ọlọ́run mi, ìwọ kì í kú’ (12)

    • ‘O ti mọ́ jù láti máa wo ohun búburú’ (13)

1  Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ fún wòlíì Hábákúkù* nínú ìran pé kó kéde nìyí:   Jèhófà, báwo ló ṣe máa pẹ́ tó tí màá fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ àmọ́ tí o kò gbọ́?+ Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó tí màá fi ké pè ọ́ pé kí o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá àmọ́ tí o kò dá sí i?*+   Kí nìdí tí o fi ń jẹ́ kí ohun búburú ṣẹlẹ̀ níṣojú mi? Kí sì nìdí tí o fi fàyè gba ìnilára? Kí nìdí tí ìparun àti ìwà ipá fi ń ṣẹlẹ̀ níṣojú mi? Kí sì nìdí tí ìjà àti aáwọ̀ fi wà káàkiri?   Òfin kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́,Kò sì sí ìdájọ́ òdodo rárá. Torí àwọn ẹni ibi yí olódodo ká;Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń yí ìdájọ́ po.+   “Ẹ wo àwọn orílẹ̀-èdè kí ẹ sì kíyè sí i! Kí ẹnu yà yín bí ẹ ṣe ń wò wọ́n, kí ó sì jọ yín lójú;Torí ohun kan máa ṣẹlẹ̀ lásìkò yín,Tí ẹ ò ní gbà gbọ́ tí wọ́n bá tiẹ̀ sọ ọ́ fún yín.+   Mò ń gbé àwọn ará Kálídíà dìde,+Orílẹ̀-èdè tí kò lójú àánú, tí kì í fi nǹkan falẹ̀. Wọ́n yára bolẹ̀ káàkiri ayéLáti gba àwọn ilé tí kì í ṣe tiwọn.+   Wọ́n ń dẹ́rù bani, wọ́n sì ń kóni láyà jẹ. Wọ́n ń gbé ìdájọ́ àti àṣẹ* tiwọn kalẹ̀.+   Àwọn ẹṣin wọn yára ju àmọ̀tẹ́kùn lọ,Wọ́n sì burú ju ìkookò ní alẹ́.+ Àwọn ẹṣin ogun wọn ń bẹ́ gìjàgìjà;Ọ̀nà jíjìn làwọn ẹṣin wọn ti wá. Wọ́n já ṣòòrò wálẹ̀ bí ẹyẹ idì tó fẹ́ yára gbé oúnjẹ.+   Torí wọ́n fẹ́ hùwà ipá ni wọ́n ṣe wá.+ Gbogbo wọn kọjú síbì kan náà bí afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ bọ̀ láti ìlà oòrùn,+Wọ́n sì ń kó àwọn èèyàn lẹ́rú bí ẹni ń kó iyanrìn. 10  Wọ́n ń fi àwọn ọba ṣe yẹ̀yẹ́,Wọ́n sì ń fi àwọn ìjòyè ṣe ẹlẹ́yà.+ Wọ́n ń fi gbogbo ibi olódi rẹ́rìn-ín;+Wọ́n fi iyẹ̀pẹ̀ mọ òkìtì, wọ́n sì gbà á. 11  Wọ́n rọ́ lọ síwájú bí afẹ́fẹ́, wọ́n sì fẹ́ kọjá,Àmọ́ wọ́n máa jẹ̀bi,+Torí wọ́n gbà pé ọlọ́run wọn ló ń fún wọn lágbára.”*+ 12  Jèhófà, ṣebí láti ayérayé ni ìwọ ti wà?+ Ọlọ́run mi, Ẹni Mímọ́ mi, ìwọ kì í kú.*+ Jèhófà, ìwọ lo yàn wọ́n láti ṣèdájọ́;Àpáta mi,+ o lò wọ́n láti fìyà jẹni.*+ 13  Ojú rẹ ti mọ́ jù láti wo ohun búburú,Ìwọ kò sì ní gba ìwà burúkú láyè.+ Kí ló wá dé tí o fi fàyè gba àwọn ọ̀dàlẹ̀,+Tí o sì dákẹ́ títí ẹni burúkú fi gbé ẹni tó jẹ́ olódodo jù ú lọ mì?+ 14  Kí nìdí tí o fi jẹ́ kí àwọn èèyàn dà bí ẹja inú òkun,Bí àwọn ohun tó ń rákò, tí wọn ò ní olórí? 15  Ó* fi ìwọ̀ kó gbogbo wọn sókè. Ó fi àwọ̀n rẹ̀ kó wọn,Ó sì fi àwọ̀n ìpẹja rẹ̀ kó wọn jọ. Ìdí nìyẹn tí inú rẹ̀ fi ń dùn ṣìnkìn.+ 16  Ìdí nìyẹn tó fi ń rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀,Tó sì ń rú ẹbọ* sí àwọ̀n ìpẹja rẹ̀;Torí wọ́n ń mú kí nǹkan ṣẹnuure fún un,*Oúnjẹ tó dára jù ló sì ń jẹ. 17  Ṣé gbogbo ìgbà ni yóò máa kó nǹkan jáde nínú àwọ̀n rẹ̀ ni?* Ṣé bí á ṣe máa pa àwọn orílẹ̀-èdè lọ láì ṣàánú wọn nìyí?+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Gbáni Mọ́ra Tọkàntọkàn.”
Tàbí “gbani là.”
Tàbí “iyì.”
Tàbí kó jẹ́, “agbára wọn ni ọlọ́run wọn.”
Tàbí kó jẹ́, “àwa kò ní kú.”
Tàbí “láti báni wí.”
Ìyẹn, àwọn ará Kálídíà tó jẹ́ ọ̀tá.
Tàbí “èéfín ẹbọ.”
Ní Héb., “òróró dun oúnjẹ rẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “máa fa idà rẹ̀ yọ?”