Òwe 8:1-36
8 Ǹjẹ́ ọgbọ́n ò máa ké jáde?
Ṣé òye ò máa gbé ohùn rẹ̀ sókè?+
2 Ní orí àwọn ibi gíga+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà,Ó dúró ní àwọn oríta.
3 Lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè tó wọnú ìlú,Ní àtiwọ àwọn ẹnu ọ̀nà,Ó ń ké tantan pé:+
4 “Ẹ̀yin ni mò ń pè, ẹ̀yin èèyàn;Gbogbo yín* ni mò ń ké sí.
5 Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́ àròjinlẹ̀;+Ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ wá ọkàn òye.*
6 Ẹ fetí sílẹ̀, torí ohun tí mò ń sọ ṣe pàtàkì,Ètè mi ń sọ ohun tí ó tọ́;
7 Nítorí ẹnu mi ń sọ òtítọ́ ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,Ètè mi sì kórìíra ohun tó burú.
8 Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
Kò sí ẹ̀tàn kankan tàbí màgòmágó nínú wọn.
9 Gbogbo wọn tọ̀nà lójú ẹni tó lóyeWọ́n sì tọ́ lójú àwọn tó ti wá ìmọ̀ rí.
10 Ẹ gba ìbáwí mi dípò fàdákà,Àti ìmọ̀ dípò wúrà tó dára jù lọ,+
11 Nítorí ọgbọ́n sàn ju iyùn* lọ;Kò sí ohun ṣíṣeyebíye míì tí a lè fi wé e.
12 Èmi ọgbọ́n, mò ń bá àròjinlẹ̀ gbé;Mo ti wá ìmọ̀ àti làákàyè rí.+
13 Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìkórìíra ohun búburú.+
Mo kórìíra ìṣefọ́nńté àti ìgbéraga+ àti ọ̀nà ibi àti ọ̀rọ̀ àyídáyidà.+
14 Mo ní ìmọ̀ràn rere àti ọgbọ́n tó gbéṣẹ́;+Òye+ àti agbára+ jẹ́ tèmi.
15 Ipasẹ̀ mi ni àwọn ọba ń ṣàkóso,Tí àwọn aláṣẹ sì ń pàṣẹ òdodo.+
16 Ipasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣàkóso,Tí àwọn èèyàn pàtàkì sì ń fi òdodo ṣèdájọ́.
17 Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi,Àwọn tó sì ń wá mi yóò rí mi.+
18 Ọrọ̀ àti ògo wà lọ́dọ̀ mi,Ọlá tó wà pẹ́ títí* àti òdodo.
19 Èso mi sàn ju wúrà lọ, àní wúrà tí a yọ́ mọ́,Ohun tí mo sì ń mú jáde sàn ju fàdákà tó dára jù lọ.+
20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,Ní àárín àwọn ipa ọ̀nà ìdájọ́ òdodo;
21 Mo fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi ní ogún tó ṣeyebíye,Mo sì mú kí ilé ìkẹ́rùsí wọn kún.
22 Jèhófà ṣẹ̀dá mi gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀nà rẹ̀,+Àkọ́bẹ̀rẹ̀ àwọn àṣeyọrí rẹ̀ ti ìgbà láéláé.+
23 Láti ayébáyé* ni a ti gbé mi kalẹ̀,+Láti ìbẹ̀rẹ̀, ṣáájú kí ayé tó wà.+
24 Nígbà tí kò sí àwọn ibú omi,+ a mú mi jáde,*Nígbà tí kò sí àwọn ìsun omi tó kún dẹ́múdẹ́mú.
25 Kí a tó fìdí àwọn òkè ńlá kalẹ̀,Ṣáájú àwọn òkè kéékèèké, a ti mú mi jáde,
26 Nígbà tí kò tíì dá ayé àti àwọn pápá rẹ̀Tàbí erùpẹ̀ ilẹ̀ tó kọ́kọ́ wà.
27 Nígbà tó dá ọ̀run,+ mo wà níbẹ̀;Nígbà tó fi ààlà* sí orí omi,+
28 Nígbà tó ṣe àwọsánmà sókè,*Nígbà tó dá àwọn ìsun ibú omi,
29 Nígbà tó pàṣẹ fún òkunPé kí omi rẹ̀ má kọjá àṣẹ tó pa fún un,+Nígbà tó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,*
30 Nígbà náà, mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́.+
Èmi ni àrídunnú rẹ̀+ lójoojúmọ́;Inú mi sì ń dùn níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà;+
31 Inú mi ń dùn nítorí ayé tí ó dá fún èèyàn láti máa gbé,Mo sì fẹ́ràn àwọn ọmọ èèyàn* lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.
32 Ní báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi;Bẹ́ẹ̀ ni, aláyọ̀ ni àwọn tó ń pa àwọn ọ̀nà mi mọ́.
33 Ẹ fetí sí ìbáwí+ kí ẹ sì gbọ́n,Ẹ má ṣe pa á tì láé.
34 Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fetí sí miTó ń jí wá sẹ́nu* ọ̀nà mi lójoojúmọ́,Tó ń dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn mi;
35 Nítorí ẹni tó bá rí mi yóò rí ìyè,+Yóò sì rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.
36 Àmọ́ ẹni tó bá pa mí tì, ara* rẹ̀ ló ń ṣe,Àwọn tó sì kórìíra mi fẹ́ràn ikú.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “Ẹ̀yin ọmọ èèyàn.”
^ Ní Héb., “lóye ọkàn.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “Ohun àjogúnbá tó ṣeyebíye.”
^ Tàbí “Láti ayérayé.”
^ Tàbí “a bí mi nínú ìrora ìbímọ.”
^ Ní Héb., “àmì òbìrìkìtì.”
^ Ní Héb., “tó mú kí àwọsánmà lágbára lókè.”
^ Tàbí “tó fi àṣẹ gbé àwọn ìpìlẹ̀ ayé kalẹ̀.”
^ Tàbí “aráyé.”
^ Tàbí “Tó ń wà lójúfò lẹ́nu.”
^ Tàbí “ọkàn.”