Òwe 30:1-33
30 Àwọn ohun pàtàkì tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Ágúrì ọmọ Jákè sọ fún Ítíélì, ìyẹn fún Ítíélì àti Úkálì.
2 Mo jẹ́ aláìmọ̀kan ju ẹnikẹ́ni lọ,+Mi ò sì ní òye tó yẹ kí èèyàn ní.
3 Mi ò tíì kọ́ ọgbọ́n,Mi ò sì tíì ní ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ.
4 Ta ló ti gòkè lọ sí ọ̀run tó sì sọ̀ kalẹ̀ wá?+
Ta ló ti kó ẹ̀fúùfù jọ sí àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ méjèèjì?
Ta ló ti di omi sínú aṣọ rẹ̀?+
Ta ló ti fi ìdí gbogbo ìkángun ayé sọlẹ̀?*+
Kí ni orúkọ rẹ̀, kí sì ni orúkọ ọmọ rẹ̀, tí o bá mọ̀ ọ́n?
5 Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́.+
Ó* jẹ́ apata fún àwọn tó ń wá ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀.+
6 Má fi nǹkan kan kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,+Nítorí á bá ọ wí,Wàá sì di òpùrọ́.
7 Ohun méjì ni mo béèrè lọ́wọ́ rẹ.
Má ṣàì fún mi kí n tó kú.
8 Mú kí àìṣòótọ́ àti irọ́ jìnnà sí mi.+
Má ṣe fún mi ní òṣì tàbí ọrọ̀.
Ṣáà jẹ́ kí n jẹ ìwọ̀nba oúnjẹ tí ó tó mi,+
9 Kí n má bàa yó tán, kí n sì sẹ́ ọ, kí n sọ pé, “Ta ni Jèhófà?”+
Má sì jẹ́ kí n tòṣì, kí n wá jalè, kí n sì kó ìtìjú bá* orúkọ Ọlọ́run mi.
10 Má ṣe ba ìránṣẹ́ jẹ́ lójú ọ̀gá rẹ̀,Nítorí ó lè gégùn-ún fún ọ, wàá sì jẹ̀bi.+
11 Ìran kan wà tó ń gégùn-ún fún bàbá rẹ̀,Kì í sì í súre fún ìyá rẹ̀.+
12 Ìran kan wà tó mọ́ lójú ara rẹ̀+Àmọ́ a kò tíì wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀gbin* rẹ̀.
13 Ìran kan wà tó ní ojú ìgbéragaÓ sì jọ ara rẹ̀ lójú gan-an!+
14 Ìran kan wà tí eyín rẹ̀ jẹ́ idà,Egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀bẹ ìpẹran;Wọ́n ń jẹ àwọn aláìní inú ayé runWọ́n sì ń jẹ àwọn òtòṣì run láàárín aráyé.+
15 Àwọn eṣúṣú* ní ọmọbìnrin méjì tó ń ké pé, “Mú wá! Mú wá!”
Ohun mẹ́ta wà tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn,Àní ohun mẹ́rin tí kì í sọ pé, “Ó tó!”
16 Isà Òkú*+ àti inú àgàn,*Ilẹ̀ tí kò ní omiÀti iná tí kì í sọ pé, “Ó tó!”
17 Ojú tó ń fi bàbá ṣẹ̀sín, tí kì í sì í ṣègbọràn sí ìyá,+Àwọn ẹyẹ ìwò tó wà ní àfonífojì yóò yọ ọ́ jáde,Àwọn ọmọ ẹyẹ idì yóò sì mú un jẹ.+
18 Ohun mẹ́ta wà tó kọjá òye mi,*Àní ohun mẹ́rin tí kò yé mi:
19 Ọ̀nà ẹyẹ idì lójú ọ̀run,Ọ̀nà ejò lórí àpáta,Ọ̀nà ọkọ̀ òkun lójú agbami,Àti ọ̀nà ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀dọ́bìnrin.
20 Ọ̀nà obìnrin alágbèrè nìyí:
Ó jẹun, ó nu ẹnu rẹ̀;Ó sì sọ pé, “Mi ò ṣe nǹkan kan tó burú.”+
21 Ohun mẹ́ta wà tó ń mú kí ayé mì jìgìjìgì,Àní ohun mẹ́rin tí ayé kò lè fara dà:
22 Tí ẹrú bá di ọba,+Tí òmùgọ̀ bá jẹun yó,
23 Tí obìnrin tí wọ́n kórìíra* bá di ìyàwó,Àti nígbà tí ìránṣẹ́bìnrin bá gba ipò ọ̀gá rẹ̀ obìnrin.*+
24 Àwọn ohun mẹ́rin kan wà lára àwọn ohun tó kéré jù lọ ní ayé,Àmọ́ tí wọ́n ní ọgbọ́n àdámọ́ni:*+
25 Àwọn èèrà jẹ́ ẹ̀dá* tí kò lágbára,Síbẹ̀, wọ́n ń kó oúnjẹ wọn jọ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn.+
26 Àwọn gara orí àpáta*+ jẹ́ ẹ̀dá* tí kò lágbára,Síbẹ̀, wọ́n ń kọ́ ilé wọn sínú àpáta.+
27 Àwọn eéṣú+ kò ní ọba,Síbẹ̀, gbogbo wọn máa ń jáde lọ létòlétò.*+
28 Ọmọńlé+ máa ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ lẹ̀ mọ́ nǹkan,Ó sì ń wọnú ààfin ọba.
29 Àwọn ohun mẹ́ta wà tí ìṣísẹ̀ wọn jọni lójú,Àní ohun mẹ́rin tí ìrìn wọn dùn-ún wò:
30 Kìnnìún, tó jẹ́ pé òun ló lágbára jù nínú àwọn ẹranko,Tí kì í sì í yíjú pa dà níwájú ẹnikẹ́ni;+
31 Ajá ọdẹ; òbúkọ;Àti ọba tí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
32 Tí o bá ti jẹ́ kí ìwà òmùgọ̀ mú kí o gbéra ga+Tàbí tí o bá ti gbèrò láti ṣe bẹ́ẹ̀,Fi ọwọ́ bo ẹnu rẹ.+
33 Nítorí bí pípo wàrà pọ̀ ṣe ń mú bọ́tà jáde,Tí fífún imú pọ̀ sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde,Bẹ́ẹ̀ ni mímú inú bíni máa ń dá ìjà sílẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “gbé gbogbo ìkángun ayé dìde.”
^ Ìyẹn, Ọlọ́run.
^ Tàbí “dojú ìjà kọ.”
^ Ní Héb., “ìgbọ̀nsẹ̀.”
^ Tàbí “kòkòrò mùjẹ̀mùjẹ̀.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ilé ọmọ tí kò lè gba oyún dúró.”
^ Tàbí “tó jẹ́ àgbàyanu fún mi.”
^ Tàbí “tí wọn ò fẹ́ràn.”
^ Tàbí “bá lé ọ̀gá rẹ̀ obìnrin jáde.”
^ Tàbí “ọgbọ́n tó ga gan-an.”
^ Ní Héb., “èèyàn.”
^ Ní Héb., “èèyàn.”
^ Ìyẹn, ẹranko kan tó jọ ehoro tó máa ń gbé níbi tí àpáta wà.
^ Tàbí “ní àwùjọ-àwùjọ.”