Òwe 19:1-29
19 Ó sàn kéèyàn jẹ́ aláìní àmọ́ kó máa rìn nínú ìwà títọ́+Ju kéèyàn jẹ́ òmùgọ̀ kó sì máa parọ́.+
2 Kò dára kí èèyàn* wà láìní ìmọ̀,+Ẹ̀ṣẹ̀ sì ni kéèyàn máa fi wàdùwàdù ṣe nǹkan.*
3 Ìwà òmùgọ̀ èèyàn ló ń lọ́ ọ̀nà rẹ̀ po,Tí ọkàn rẹ̀ fi ń bínú gidigidi sí Jèhófà.
4 Ọrọ̀ ń mú kéèyàn ní ọ̀rẹ́ púpọ̀,Àmọ́ ọ̀rẹ́ tálákà pàápàá yóò fi í sílẹ̀.+
5 Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,+Ẹni tí kò sì lè ṣe kó má parọ́ kò ní yè bọ́.+
6 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá ojú rere èèyàn pàtàkì,*Gbogbo èèyàn ló sì ń bá ẹni tó ń fúnni lẹ́bùn ṣọ̀rẹ́.
7 Gbogbo ọmọ ìyá tálákà máa ń kórìíra rẹ̀;+Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó pa á tì!+
Ó ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ wọn ṣáá, àmọ́ kò sẹ́ni tó dá a lóhùn.
8 Ẹni tó ní làákàyè* fẹ́ràn ara* rẹ̀.+
Ẹni tó fi òye ṣe ìṣúra yóò ṣàṣeyọrí.*+
9 Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà,Ẹni tí kò sì lè ṣe kó má parọ́ yóò ṣègbé.+
10 Kò yẹ kí òmùgọ̀ máa gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ;Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí ìránṣẹ́ máa ṣe olórí àwọn ìjòyè!+
11 Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní ló máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀,+Ẹwà ló sì jẹ́ fún un pé kó gbójú fo* àṣìṣe.*+
12 Ìrunú ọba dà bí ìgbà tí kìnnìún* bá ń kùn,+Àmọ́ ojú rere rẹ̀ dà bí ìrì lára ewéko.
13 Òmùgọ̀ ọmọ ń fa àjálù bá bàbá rẹ̀,+Oníjà* aya sì dà bí òrùlé tó ń jò ṣáá.+
14 Ọ̀dọ̀ àwọn baba ni a ti ń jogún ilé àti ọrọ̀,Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni aya olóye ti ń wá.+
15 Ìwà ọ̀lẹ máa ń fa oorun àsùnwọra,Ebi yóò sì pa ẹni* tó ń ṣe ìmẹ́lẹ́.+
16 Ẹni tó ń pa àṣẹ mọ́ ń pa ẹ̀mí* rẹ̀ mọ́;+Ẹni tí kì í kíyè sí ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.+
17 Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan,+Á sì san án* pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.+
18 Bá ọmọ rẹ wí nígbà tí ìrètí ṣì wà,+Kí o má bàa jẹ̀bi* ikú rẹ̀.+
19 Onínúfùfù yóò jìyà ìwà rẹ̀;Tí o bá gbà á sílẹ̀, wàá tún ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ léraléra.+
20 Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí,+Kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.+
21 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni èèyàn ń gbèrò nínú ọkàn rẹ̀,Àmọ́ ìmọ̀ràn* Jèhófà ni yóò borí.+
22 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ẹwà èèyàn;+Ó sì sàn kéèyàn jẹ́ aláìní ju kí ó jẹ́ òpùrọ́.
23 Ìbẹ̀rù Jèhófà ń yọrí sí ìyè;+Ẹni tó bá ní in yóò sun oorun àsùnwọra, láìsí aburú kankan.+
24 Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú abọ́ oúnjẹ,Àmọ́ kò wulẹ̀ janpata láti gbé e pa dà sí ẹnu.+
25 Gbá afiniṣẹ̀sín,+ kí aláìmọ̀kan lè ní àròjinlẹ̀,+Sì bá olóye wí, kí ìmọ̀ rẹ̀ lè pọ̀ sí i.+
26 Ẹni tó ṣe àìdáa sí bàbá rẹ̀ tó sì lé ìyá rẹ̀ lọJẹ́ ọmọ tó ń fa ìtìjú àti àbùkù.+
27 Ọmọ mi, tí o bá ṣíwọ́ fífi etí sí ìbáwí,Wàá yà kúrò ní ọ̀nà ìmọ̀.
28 Ẹlẹ́rìí tí kò ní láárí ń fi ìdájọ́ òdodo ṣẹ̀sín,+Ẹnu èèyàn burúkú sì ń gbé ibi mì.+
29 Ìdájọ́ ń dúró de àwọn afiniṣẹ̀sín,+Ẹgba sì ń dúró de ẹ̀yìn àwọn òmùgọ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “kí ẹsẹ̀ èèyàn yá.”
^ Tàbí “ẹni tó lawọ́.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “rí ire.”
^ Ní Héb., “ọkàn.”
^ Ní Héb., “mójú kúrò nínú.”
^ Tàbí “ìṣìnà.”
^ Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
^ Tàbí “Ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “èrè.”
^ Tàbí “fẹ́.” Ní Héb., “gbé ọkàn rẹ sí.”
^ Tàbí “ìpinnu.”