Ẹ́kísódù 36:1-38

  • Ọrẹ náà tó, ó ṣẹ́ kù (1-7)

  • Wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn (8-38)

36  “Kí Bẹ́sálẹ́lì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Òhólíábù àti gbogbo ọkùnrin tó mọṣẹ́* tí Jèhófà ti fún ní ọgbọ́n àti òye kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn mímọ́ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ.”+  Lẹ́yìn náà, Mósè pe Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù àti gbogbo ọkùnrin tó mọṣẹ́ tí Jèhófà fi ọgbọ́n sínú ọkàn wọn,+ gbogbo ẹni tí ọkàn rẹ̀ sún láti yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ náà.+  Wọ́n wá gba gbogbo ọrẹ+ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́ náà lọ́wọ́ Mósè. Síbẹ̀, wọ́n ṣì ń mú ọrẹ àtinúwá wá fún Mósè láràárọ̀.  Lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mímọ́ náà, gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ ń wá, ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn,  wọ́n sì ń sọ fún Mósè pé: “Ohun tí àwọn èèyàn ń mú wá pọ̀ gan-an ju ohun tí a nílò fún iṣẹ́ tí Jèhófà pa láṣẹ pé ká ṣe.”  Mósè wá pàṣẹ pé kí wọ́n kéde káàkiri àgọ́ náà pé: “Ẹ̀yin èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ẹ má ṣe mú nǹkan kan wá mọ́ láti fi ṣe ọrẹ mímọ́.” Bí wọn ò ṣe jẹ́ káwọn èèyàn náà mú ohunkóhun wá mọ́ nìyẹn.  Ohun tí wọ́n mú wá tó fún gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ ṣe, ó sì tún ṣẹ́ kù.  Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́+ mú aṣọ mẹ́wàá tó jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa, tí wọ́n fi ń pa àgọ́, pẹ̀lú fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, wọ́n sì fi ṣe àgọ́ ìjọsìn;+ ó* kó iṣẹ́ sí wọn lára, iṣẹ́ náà jẹ́ àwòrán àwọn kérúbù.+  Gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjìdínlọ́gbọ̀n (28), fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Ìwọ̀n gbogbo aṣọ àgọ́ náà dọ́gba. 10  Ó wá so márùn-ún nínú aṣọ àgọ́ náà mọ́ra, ó sì so aṣọ àgọ́ márùn-ún yòókù pọ̀. 11  Lẹ́yìn náà, ó fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe àwọn ihò sí etí aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan níbi tó ti so mọ́ ìkejì. Ó ṣe ohun kan náà sí etí aṣọ àgọ́ tó wà ní ìkángun níbi tó yẹ kó ti so pọ̀ mọ́ ti àkọ́kọ́. 12  Ó lu àádọ́ta (50) ihò sí aṣọ àgọ́ kan, ó sì lu àádọ́ta (50) ihò sí aṣọ àgọ́ náà ní ẹ̀gbẹ́ kejì níbi tí yóò ti so pọ̀ kí àwọn ihò náà lè wà ní òdìkejì ara wọn. 13  Níkẹyìn, ó fi wúrà ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́, ó sì fi àwọn ìkọ́ náà so àwọn aṣọ àgọ́ náà pọ̀, kí àgọ́ ìjọsìn náà lè di odindi. 14  Ó wá fi irun ewúrẹ́ ṣe àwọn aṣọ àgọ́ láti fi bo àgọ́ ìjọsìn náà. Ó ṣe aṣọ àgọ́ mọkànlá (11).+ 15  Gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Ìwọn aṣọ àgọ́ mọ́kànlá (11) náà dọ́gba. 16  Ó so márùn-ún nínú àwọn aṣọ àgọ́ náà mọ́ra, ó sì so aṣọ àgọ́ mẹ́fà yòókù pọ̀ mọ́ra. 17  Lẹ́yìn náà, ó lu àádọ́ta (50) ihò sí etí aṣọ àgọ́ tó wà ní ìkángun níbi tó ti so pọ̀, ó sì lu àádọ́ta (50) ihò sí etí aṣọ àgọ́ kejì tó so pọ̀ mọ́ ọn. 18  Ó fi bàbà ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́ láti so àgọ́ náà pọ̀ kó lè di odindi. 19  Ó fi awọ àgbò tí wọ́n pa láró pupa ṣe ìbòrí àgọ́ náà, ó sì fi awọ séálì bo awọ àgbò náà.+ 20  Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní+ ṣe àwọn férémù àgọ́ ìjọsìn náà, wọ́n sì wà ní òró.+ 21  Gígùn férémù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀. 22  Férémù kọ̀ọ̀kan ní ìtẹ̀bọ̀ méjì* lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe ṣe gbogbo férémù àgọ́ ìjọsìn náà. 23  Ó ṣe àwọn férémù sí apá gúúsù àgọ́ ìjọsìn náà, ogún (20) férémù tó dojú kọ gúúsù. 24  Ó wá fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò sábẹ́ ogún (20) férémù náà, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sábẹ́ férémù kan kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀, ó sì ṣe ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù, kí ìtẹ̀bọ̀ méjì férémù náà lè wọnú rẹ̀.+ 25  Ó ṣe ogún (20) férémù sí ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà, ní apá àríwá, 26  ó sì fi fàdákà ṣe ogójì (40) ìtẹ́lẹ̀ oníhò fún wọn, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò lábẹ́ férémù kan àti ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò lábẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn férémù yòókù. 27  Ó ṣe férémù mẹ́fà sí ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn náà lápá ìwọ̀ oòrùn.+ 28  Ó fi férémù méjì ṣe òpó sí igun méjèèjì àgọ́ ìjọsìn náà lápá ẹ̀yìn. 29  Àwọn òpó náà ní igi méjì láti ìsàlẹ̀ dé òkè, níbi òrùka àkọ́kọ́. Ohun tó ṣe sí òpó tó wà ní igun méjèèjì nìyẹn. 30  Gbogbo rẹ̀ wá jẹ́ férémù mẹ́jọ, pẹ̀lú ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn mẹ́rìndínlógún (16) tí wọ́n fi fàdákà ṣe, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sì wà lábẹ́ férémù kọ̀ọ̀kan. 31  Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá gbọọrọ, ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan àgọ́ ìjọsìn náà+ 32  àti ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún àwọn férémù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì àgọ́ ìjọsìn náà àti ọ̀pá gbọọrọ márùn-ún fún férémù ọwọ́ ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn náà lápá ìwọ̀ oòrùn. 33  Ó ṣe ọ̀pá gbọọrọ sí àárín, èyí tó gba àárín àwọn férémù náà kọjá láti ìkángun kan sí èkejì. 34  Ó fi wúrà bo àwọn férémù náà, ó fi wúrà ṣe òrùka tó máa di àwọn ọ̀pá náà mú, ó sì fi wúrà bo àwọn ọ̀pá náà.+ 35  Ó sì fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ṣe aṣọ ìdábùú.+ Ó kó iṣẹ́ sí i lára,+ iṣẹ́ náà jẹ́ àwòrán àwọn kérúbù.+ 36  Lẹ́yìn náà, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe òpó mẹ́rin fún un, ó sì fi wúrà bò wọ́n, pẹ̀lú àwọn ìkọ́ tó fi wúrà ṣe, ó sì fi fàdákà rọ ìtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó ní ihò fún wọn. 37  Ó fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa tí wọ́n hun pọ̀ ṣe aṣọ* tí wọ́n máa ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà,+ 38  pẹ̀lú òpó rẹ̀ márùn-ún àti àwọn ìkọ́ wọn. Ó fi wúrà bo orí wọn àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀,* àmọ́ bàbà ló fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn márààrún.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “jẹ́ ọlọgbọ́n ní ọkàn.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Ó ṣe kedere pé Bẹ́sálẹ́lì ló ń tọ́ka sí.
Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.
Tàbí “òpó méjì tó wà ní òró.”
Tàbí “aṣọ ìdábùú.”
Tàbí “òrùka wọn” tí wọ́n fi ń so nǹkan pọ̀.