Àìsáyà 29:1-24
29 “O gbé ìwọ Áríélì,* Áríélì, ìlú tí Dáfídì pàgọ́ sí!+
Ẹ máa bá a lọ lọ́dọọdún;Ẹ máa ṣe àwọn àjọyọ̀+ ní àkókò wọn.
2 Àmọ́ màá mú ìdààmú bá Áríélì,+Ó máa ṣọ̀fọ̀, ó máa dárò,+Ó sì máa dà bí ibi ìdáná pẹpẹ Ọlọ́run fún mi.+
3 Màá pàgọ́ yí ọ ká,Màá ṣe ọgbà láti dó tì ọ́,Màá sì ṣe àwọn ohun tí màá fi gbógun tì ọ́.+
4 A máa rẹ̀ ọ́ wálẹ̀;Wàá máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀,Iyẹ̀pẹ̀ ò sì ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere.
Ohùn rẹ á máa jáde látinú ilẹ̀+
Bí ohùn abẹ́mìílò,Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ á sì máa dún ṣíoṣío látinú iyẹ̀pẹ̀.
5 Àwọn ọ̀tá* rẹ tó pọ̀ rẹpẹtẹ máa dà bí eruku lẹ́búlẹ́bú,+Àwọn ìkà tó pọ̀ rẹpẹtẹ sì máa dà bí ìyàngbò* tó ń fẹ́ lọ.+
Ó sì máa ṣẹlẹ̀ lójijì, ká tó ṣẹ́jú pẹ́.+
6 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa fún ọ láfiyèsíPẹ̀lú ààrá, ìmìtìtì ilẹ̀ àti ariwo ńlá,Pẹ̀lú ìjì, atẹ́gùn líle àti ọwọ́ iná tó ń jẹni run.”+
7 Gbogbo orílẹ̀-èdè tó pọ̀ rẹpẹtẹ tí wọ́n ń gbógun ja Áríélì,+Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbógun jà á,Àwọn ilé gogoro tí wọ́n fi dó tì í,Àti àwọn tó ń kó ìdààmú bá a,Máa wá dà bí àlá, ìran òru.
8 Àní, ó máa dà bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa lá àlá pé òun ń jẹun,Àmọ́ tó jí, tí ebi ṣì ń pa á*Àti bí ìgbà tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi,Àmọ́ tó jí, tó ti rẹ̀ ẹ́, tí òùngbẹ ṣì ń gbẹ ẹ́.*
Bó ṣe máa rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè tó pọ̀ rẹpẹtẹ nìyí,Àwọn tó gbógun ja Òkè Síónì.+
9 Kí ẹnu yà yín, kí ẹ sì ṣe kàyéfì;+Ẹ fọ́ ara yín lójú, kí ẹ sì fọ́jú.+
Wọ́n ti yó, àmọ́ kì í ṣe wáìnì ni wọ́n mu yó;Wọ́n ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́, àmọ́ kì í ṣe ọtí ló ń mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.
10 Torí Jèhófà ti da ẹ̀mí oorun àsùnwọra lù yín;+Ó ti pa ojú yín dé, ẹ̀yin wòlíì,+Ó sì ti bo orí yín, ẹ̀yin aríran.+
11 Gbogbo ìran dà bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a gbé èdìdì lé fún yín.+ Tí wọ́n bá fún ẹni tó mọ̀wé kà, tí wọ́n sọ pé: “Jọ̀ọ́, kà á sókè,” á sọ pé: “Mi ò lè kà á, torí wọ́n ti gbé èdìdì lé e.”
12 Tí wọ́n bá sì fún ẹni tí kò mọ̀wé kà ní ìwé náà, tí wọ́n sọ pé: “Jọ̀ọ́, kà á,” á sọ pé: “Mi ò lè kàwé rárá.”
13 Jèhófà sọ pé: “Àwọn èèyàn yìí ń fi ẹnu wọn sún mọ́ mi,Wọ́n sì ń fi ètè wọn bọlá fún mi,+Àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi;Àṣẹ èèyàn tí wọ́n kọ́ wọn ló sì ń mú kí wọ́n máa bẹ̀rù mi.+
14 Torí náà, èmi ni Ẹni tó tún máa ṣe àwọn ohun àgbàyanu sí àwọn èèyàn yìí,+Ohun àgbàyanu kan tẹ̀ lé òmíràn;Ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n wọn máa ṣègbé,Òye àwọn olóye wọn sì máa fara pa mọ́.”+
15 Ó mà ṣe o, fún àwọn tó sapá gidigidi kí wọ́n lè fi ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe* pa mọ́ fún Jèhófà.+
Ibi tó ṣókùnkùn ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ wọn,Tí wọ́n ń sọ pé: “Ta ló rí wa,Ta ló mọ̀ nípa wa?”+
16 Ẹ wo bí ẹ ṣe ń dorí nǹkan kodò!*
Ṣé ojú kan náà ló yẹ ká fi wo amọ̀kòkò àti amọ̀?+
Ṣé ó yẹ kí ohun tí a dá sọ nípa ẹni tó dá a pé:
“Òun kọ́ ló dá mi”?+
Ṣé ohun tí a ṣe sì máa ń sọ fún ẹni tó ṣe é pé:
“Kò fi òye hàn”?+
17 Kò ní pẹ́ rárá tí Lẹ́bánónì fi máa di ọgbà eléso,+A sì máa ka ọgbà eléso náà sí igbó.+
18 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn adití máa gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìwé náà,Àwọn afọ́jú sì máa ríran látinú ìṣúdùdù àti òkùnkùn.+
19 Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ máa yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà,Àwọn tó sì jẹ́ aláìní láàárín àwọn èèyàn máa yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+
20 Torí pé ìkà èèyàn kò ní sí mọ́,Òpin máa dé bá afọ́nnu,Gbogbo àwọn tó sì wà lójúfò láti ṣe ìkà máa pa run,+
21 Àwọn tó ń fi ọ̀rọ̀ èké dá àwọn míì lẹ́bi,Tí wọ́n ń dẹ pańpẹ́ sílẹ̀ de olùgbèjà* ní ẹnubodè ìlú+Àti àwọn tó ń jiyàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti fi ìdájọ́ òdodo du olódodo.+
22 Torí náà, ohun tí Jèhófà, ẹni tó ra Ábúráhámù pa dà,+ sọ fún ilé Jékọ́bù nìyí:
“Ojú ò ní ti Jékọ́bù mọ́,Ojú rẹ̀ ò sì ní funfun mọ́.*+
23 Torí tó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀,Tí wọ́n jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ mi, ní àárín rẹ̀,+Wọ́n máa sọ orúkọ mi di mímọ́;Àní, wọ́n máa sọ Ẹni Mímọ́ Jékọ́bù di mímọ́,Wọ́n sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run Ísírẹ́lì gidigidi.+
24 Àwọn tó ní èrò tí kò tọ́* máa ní òye,Àwọn tó ń ráhùn sì máa gba ìtọ́ni.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ibi Ìdáná Pẹpẹ Ọlọ́run,” ó jọ pé Jerúsálẹ́mù ló ń tọ́ka sí.
^ Ní Héb., “àjèjì.”
^ Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.
^ Tàbí “tí ọkàn rẹ̀ sì ṣófo.”
^ Tàbí “tí ọkàn rẹ̀ sì gbẹ.”
^ Tàbí “ìmọ̀ràn wọn.”
^ Tàbí “Ẹ wo bí ẹ ṣe gbé nǹkan gbòdì.”
^ Ní Héb., “ẹni tó ń báni wí.”
^ Ìyẹn, nítorí ìtìjú àti ìjákulẹ̀.
^ Ní Héb., “ṣìnà nínú ẹ̀mí.”