Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?
Ṣé ayé yìí máa . . .
-
wà bó ṣe wà?
-
àbí ó máa burú sí i?
-
àbí ó ṣì máa dáa?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
“Ọlọ́run . . . máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìfihàn 21:3, 4, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ
Wàá ní iṣẹ́ gidi tó máa tẹ́ ọ lọ́rùn.—Àìsáyà 65:21-23.
Kò ní sí àìsàn àti ìyà kankan mọ́.—Àìsáyà 25:8; 33:24.
Inú rẹ á máa dùn, wàá sì lè wà láàyè títí láé pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ.—Sáàmù 37:11, 29.
ṢÉ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?
Bẹ́ẹ̀ ni. Méjì lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:
-
Ìlérí Ọlọ́run kì í yẹ̀. Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni Bíbélì pè ní “Olódùmarè” torí pé agbára rẹ̀ kò láàlà. (Ìfihàn 15:3) Torí náà, ó lágbára láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa bá wa tún ayé yìí ṣe. Bíbélì sọ pé, “ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”—Mátíù 19:26.
-
Ọlọ́run fẹ́ mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó ń wu Jèhófà gan-an pé kó jí àwọn tó ti kú dìde.—Jóòbù 14:14, 15.
Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù, Ọmọ Ọlọ́run, mú àwọn aláìsàn lára dá. Kí nìdí tó fi wò wọ́n sàn? Ìdí ni pé ó wù ú pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. (Máàkù 1:40, 41) Bí Jésù ṣe máa ń fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ń gbé ìwà Baba rẹ̀ yọ.—Jòhánù 14:9.
Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà àti Jésù fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wa dùn bí oyin!—Sáàmù 72:12-14; 145:16; 2 Pétérù 3:9.
RÒ Ó WÒ NÁ
Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa tún ayé yìí ṣe?
Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé MÁTÍÙ 6:9, 10 àti DÁNÍẸ́LÌ 2:44.