Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Jóòbù

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Ìwà títọ́ Jóòbù àti ọrọ̀ rẹ̀ (1-5)

    • Sátánì fẹ̀sùn kan Jóòbù (6-12)

    • Jóòbù pàdánù ohun ìní rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ (13-19)

    • Jóòbù ò dá Ọlọ́run lẹ́bi (20-22)

  • 2

    • Sátánì tún fẹ̀sùn kan Jóòbù (1-5)

    • Ọlọ́run fàyè gba Sátánì pé kó kọlu ara Jóòbù (6-8)

    • Ìyàwó Jóòbù sọ pé: “Sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, kí o sì kú!” (9, 10)

    • Àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta dé (11-13)

  • 3

    • Jóòbù ń kábàámọ̀ ọjọ́ tí wọ́n bí i (1-26)

      • Ó béèrè ohun tó fa ìyà òun (20, 21)

  • 4

    • Ọ̀rọ̀ tí Élífásì kọ́kọ́ sọ (1-21)

      • Ó bẹnu àtẹ́ lu ìwà títọ́ Jóòbù (7, 8)

      • Ó sọ ohun tí ẹ̀mí kan bá a sọ (12-17)

      • ‘Ọlọ́run ò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀’ (18)

  • 5

    • Élífásì ń bá ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ sọ lọ (1-27)

      • ‘Ọlọ́run ń mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wọn’ (13)

      • ‘Kí Jóòbù má ṣe kọ ìbáwí Ọlọ́run’ (17)

  • 6

    • Jóòbù fèsì (1-30)

      • Ó sọ pé òun ò jẹ̀bi bí òun ṣe ń ké jáde (2-6)

      • Ọ̀dàlẹ̀ ni àwọn tó ń tù ú nínú (15-18)

      • “Òótọ́ ọ̀rọ̀ kì í dunni!” (25)

  • 7

    • Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-21)

      • Ìgbésí ayé dà bí iṣẹ́ àṣekára tó pọn dandan (1, 2)

      • “Kí ló dé tí o dájú sọ mí?” (20)

  • 8

    • Ọ̀rọ̀ tí Bílídádì kọ́kọ́ sọ (1-22)

      • Ó sọ pé àwọn ọmọ Jóòbù ti ṣẹ̀ (4)

      • ‘Tí o bá mọ́, Ọlọ́run máa dáàbò bò ọ́’ (6)

      • Ó sọ pé Jóòbù kò mọ Ọlọ́run (13)

  • 9

    • Jóòbù fèsì (1-35)

      • Ẹni kíkú ò lè bá Ọlọ́run fà á (2-4)

      • ‘Ọlọ́run ń ṣe àwọn ohun àwámáridìí’ (10)

      • Èèyàn ò lè bá Ọlọ́run jiyàn (32)

  • 10

    • Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-22)

      • ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run fi ń bá mi jà?’ (2)

      • Ọlọ́run yàtọ̀ sí Jóòbù tó jẹ́ ẹni kíkú (4-12)

      • ‘Kí ara tù mí díẹ̀’ (20)

  • 11

    • Ọ̀rọ̀ tí Sófárì kọ́kọ́ sọ (1-20)

      • Ó sọ pé ọ̀rọ̀ Jóòbù kò nítumọ̀ (2, 3)

      • Ó ní kí Jóòbù má ṣe ohun tí kò dáa (14)

  • 12

    • Jóòbù fèsì (1-25)

      • “Mi ò kéré sí yín” (3)

      • ‘Mo wá di ẹni tí wọ́n fi ń ṣe ẹlẹ́yà’ (4)

      • ‘Ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run’ (13)

      • Ọlọ́run ga ju àwọn adájọ́ àti ọba lọ (17, 18)

  • 13

    • Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-28)

      • ‘Màá kúkú bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀’ (3)

      • ‘Oníṣègùn tí kò wúlò ni yín’ (4)

      • “Mo mọ̀ pé èmi ni mo jàre” (18)

      • Ó fẹ́ mọ ìdí tí Ọlọ́run fi ka òun sí ọ̀tá (24)

  • 14

    • Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-22)

      • Èèyàn jẹ́ ọlọ́jọ́ kúkúrú, wàhálà tó bá a pọ̀ gan-an (1)

      • “Ìrètí wà fún igi pàápàá” (7)

      • “Ká ní o lè fi mí pa mọ́ sínú Isà Òkú ni” (13)

      • “Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè wà láàyè?” (14)

      • Ó máa wu Ọlọ́run gan-an pé kó rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ (15)

  • 15

    • Ìgbà kejì tí Élífásì sọ̀rọ̀ (1-35)

      • Ó sọ pé Jóòbù ò bẹ̀rù Ọlọ́run (4)

      • Ó ní Jóòbù ń gbéra ga (7-9)

      • ‘Ọlọ́run ò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀’ (15)

      • ‘Ẹni burúkú ló ń jìyà’ (20-24)

  • 16

    • Jóòbù fèsì (1-22)

      • ‘Olùtùnú tó ń dani láàmú ni yín!’ (2)

      • Ó ní Ọlọ́run dájú sọ òun (12)

  • 17

    • Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-16)

      • “Àwọn tó ń fini ṣe yẹ̀yẹ́ yí mi ká” (2)

      • “Ó ti sọ mí di ẹni ẹ̀gàn” (6)

      • “Isà Òkú máa di ilé mi” (13)

  • 18

    • Ìgbà kejì tí Bílídádì sọ̀rọ̀ (1-21)

      • Ó sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ (5-20)

      • Ó ń dọ́gbọ́n sọ pé Jóòbù kò mọ Ọlọ́run (21)

  • 19

    • Jóòbù fèsì (1-29)

      • Ó kọ ìbáwí àwọn “ọ̀rẹ́” rẹ̀ (1-6)

      • Ó ní wọ́n pa òun tì (13-19)

      • “Olùràpadà mi wà láàyè”(25)

  • 20

    • Ìgbà kejì tí Sófárì sọ̀rọ̀ (1-29)

      • Ó wò ó pé Jóòbù sọ̀rọ̀ sí òun (2, 3)

      • Ó dọ́gbọ́n sọ pé ẹni burúkú ni Jóòbù (5)

      • Ó ní ẹ̀ṣẹ̀ ń dùn mọ́ Jóòbù (12, 13)

  • 21

    • Jóòbù fèsì (1-34)

      • ‘Kí ló dé tí nǹkan ń lọ dáadáa fún ẹni burúkú?’ (7-13)

      • Ó sọ èrò ibi tó wà lọ́kàn àwọn tó ń tù ú nínú (27-34)

  • 22

    • Ìgbà kẹta tí Élífásì sọ̀rọ̀ (1-30)

      • ‘Ṣé èèyàn lè ṣe Ọlọ́run láǹfààní?’ (2, 3)

      • Ó fẹ̀sùn kan Jóòbù pé ó ń jẹ èrè tí kò tọ́, ó sì ń rẹ́ni jẹ (6-9)

      • ‘Pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, wàá sì pa dà sí àyè rẹ’ (23)

  • 23

    • Jóòbù fèsì (1-17)

      • Ó fẹ́ ro ẹjọ́ rẹ̀ níwájú Ọlọ́run (1-7)

      • Ó ní òun ò rí Ọlọ́run (8, 9)

      • “Mò ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀ ṣáá, mi ò sì yà kúrò níbẹ̀” (11)

  • 24

    • Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-25)

      • ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run ò yan àkókò?’ (1)

      • Ó ní Ọlọ́run fàyè gba ìwà ibi (12)

      • Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ fẹ́ràn òkùnkùn (13-17)

  • 25

    • Ìgbà kẹta tí Bílídádì sọ̀rọ̀ (1-6)

      • ‘Báwo ni èèyàn ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run?’ (4)

      • Ó ní ìwà títọ́ èèyàn kò já mọ́ nǹkan kan (5, 6)

  • 26

    • Jóòbù fèsì (1-14)

      • “Wo bí o ṣe ran ẹni tí kò lágbára lọ́wọ́!” (1-4)

      • ‘Ọlọ́run fi ayé rọ̀ sórí òfo’ (7)

      • ‘Bíńtín lára àwọn ọ̀nà Ọlọ́run’ (14)

  • 27

    • Jóòbù pinnu pé òun á máa pa ìwà títọ́ òun mọ́ (1-23)

      • “Mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀” (5)

      • Ẹni tí kò mọ Ọlọ́run kò nírètí (8)

      • “Kí ló dé tí ọ̀rọ̀ yín kò nítumọ̀ rárá?” (12)

      • Ohunkóhun ò ní ṣẹ́ kù fáwọn ẹni burúkú (13-23)

  • 28

    • Jóòbù fi àwọn ìṣúra ayé wé ọgbọ́n (1-28)

      • Bí èèyàn ṣe ń sapá láti wa kùsà (1-11)

      • Ọgbọ́n níye lórí ju péálì lọ (18)

      • Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọgbọ́n tòótọ́ (28)

  • 29

    • Jóòbù rántí bí nǹkan ṣe ń dùn kí àdánwò tó dé (1-25)

      • Ó jẹ́ èèyàn pàtàkì ní ẹnubodè (7-10)

      • Bó ṣe máa ń fi òdodo ṣèdájọ́ (11-17)

      • Gbogbo èèyàn máa ń gbọ́ ìmọ̀ràn rẹ̀ (21-23)

  • 30

    • Jóòbù sọ bí nǹkan ṣe wá yí pa dà fún òun (1-31)

      • Àwọn tí kò ní láárí ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ (1-15)

      • Ó jọ pé Ọlọ́run kò ràn án lọ́wọ́ (20, 21)

      • “Awọ ara mi ti dúdú” (30)

  • 31

    • Jóòbù gbèjà ìwà títọ́ rẹ̀ (1-40)

      • “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú” (1)

      • Ó ní kí Ọlọ́run wọn òun (6)

      • Kì í ṣe alágbèrè (9-12)

      • Kò nífẹ̀ẹ́ owó (24, 25)

      • Kì í ṣe abọ̀rìṣà (26-28)

  • 32

    • Élíhù tó kéré sí wọn dá sí ọ̀rọ̀ náà (1-22)

      • Ó bínú sí Jóòbù àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ (2, 3)

      • Kò tètè sọ̀rọ̀ torí ó bọ̀wọ̀ fún wọn (6, 7)

      • Ọjọ́ orí nìkan kọ́ ló ń sọ èèyàn di ọlọ́gbọ́n (9)

      • Ó wu Élíhù pé kó sọ̀rọ̀ (18-20)

  • 33

    • Élíhù bá Jóòbù wí torí ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀ (1-33)

      • Ó rí ìràpadà (24)

      • Kó pa dà ní okun ìgbà ọ̀dọ́ (25)

  • 34

    • Élíhù gbé ìdájọ́ àtàwọn ọ̀nà Ọlọ́run ga (1-37)

      • Jóòbù ní Ọlọ́run fi ìdájọ́ òdodo du òun (5)

      • Ọlọ́run tòótọ́ kì í hùwà burúkú (10)

      • Jóòbù ò ní ìmọ̀ (35)

  • 35

    • Élíhù sọ àwọn èrò tí kò tọ́ tí Jóòbù ní (1-16)

      • Jóòbù sọ pé òdodo òun ju ti Ọlọ́run lọ (2)

      • Ọlọ́run ga lọ́la, ẹ̀ṣẹ̀ kò sì lè ṣe nǹkan fún un (5, 6)

      • Kí Jóòbù dúró de Ọlọ́run (14)

  • 36

    • Élíhù gbé Ọlọ́run ga, ó ní bó ṣe ga lọ́lá jẹ́ àwámáridìí (1-33)

      • Nǹkan ń lọ dáadáa fún onígbọràn; a kò tẹ́wọ́ gba àwọn tí kò mọ Ọlọ́run (11-13)

      • ‘Olùkọ́ wo ló dà bí Ọlọ́run?’ (22)

      • Kí Jóòbù gbé Ọlọ́run ga (24)

      • “Ọlọ́run tóbi ju bí a ṣe lè mọ̀” (26)

      • Ọlọ́run ń darí òjò àti mànàmáná (27-33)

  • 37

    • Àwọn ohun tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ bó ṣe tóbi tó (1-24)

      • Ọlọ́run lè fòpin sáwọn ohun téèyàn ń ṣe (7)

      • “Ronú nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run” (14)

      • Ó kọjá agbára èèyàn láti lóye Ọlọ́run (23)

      • Kí èèyàn kankan má rò pé òun gbọ́n (24)

  • 38

    • Jèhófà jẹ́ ká mọ bí èèyàn ṣe kéré tó (1-41)

      • ‘Ibo lo wà nígbà tí mo dá ayé?’ (4-6)

      • Àwọn ọmọ Ọlọ́run hó yèè, wọ́n yìn ín (7)

      • Ìbéèrè nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá (8-32)

      • “Àwọn òfin tó ń darí ọ̀run” (33)

  • 39

    • Àwọn ẹran tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn ò mọ nǹkan kan (1-30)

      • Àwọn ewúrẹ́ orí òkè àti àgbọ̀nrín (1-4)

      • Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó (5-8)

      • Akọ màlúù inú igbó (9-12)

      • Ògòǹgò (13-18)

      • Ẹṣin (19-25)

      • Àṣáǹwéwé àti idì (26-30)

  • 40

    • Jèhófà tún bi í láwọn ìbéèrè (1-24)

      • Jóòbù gbà pé òun ò ní nǹkan kan láti sọ (3-5)

      • “Ṣé o máa sọ pé mi ò ṣèdájọ́ bó ṣe tọ́ ni?” (8)

      • Ọlọ́run jẹ́ ká mọ bí Béhémótì ṣe lágbára tó (15-24)

  • 41

    • Ọlọ́run jẹ́ ká mọ bí Léfíátánì ṣe ṣàrà ọ̀tọ̀ (1-34)

  • 42

    • Jóòbù dá Jèhófà lóhùn (1-6)

    • Ọlọ́run bínú sí àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta (7-9)

    • Jèhófà pa dà bù kún Jóòbù (10-17)

      • Àwọn ọmọ Jóòbù lọ́kùnrin àti lóbìnrin (13-15)