YAN Ọ̀KAN Ìwé Bíbélì Jẹ́nẹ́sísì Ẹ́kísódù Léfítíkù Nọ́ńbà Diutarónómì Jóṣúà Àwọn Onídàájọ́ Rúùtù 1 Sámúẹ́lì 2 Sámúẹ́lì 1 Àwọn Ọba 2 Àwọn Ọba 1 Kíróníkà 2 Kíróníkà Ẹ́sírà Nehemáyà Ẹ́sítà Jóòbù Sáàmù Òwe Oníwàásù Orin Sólómọ́nì Àìsáyà Jeremáyà Ìdárò Ìsíkíẹ́lì Dáníẹ́lì Hósíà Jóẹ́lì Émọ́sì Ọbadáyà Jónà Míkà Náhúmù Hábákúkù Sefanáyà Hágáì Sekaráyà Málákì Mátíù Máàkù Lúùkù Jòhánù Ìṣe Róòmù 1 Kọ́ríńtì 2 Kọ́ríńtì Gálátíà Éfésù Fílípì Kólósè 1 Tẹsalóníkà 2 Tẹsalóníkà 1 Tímótì 2 Tímótì Títù Fílémónì Hébérù Jémíìsì 1 Pétérù 2 Pétérù 1 Jòhánù 2 Jòhánù 3 Jòhánù Júùdù Ìfihàn Orí 1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 Ìwé Diutarónómì Orí 1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí 1 Wọ́n kúrò ní Òkè Hórébù (1-8) Wọ́n yan àwọn olórí àti àwọn onídàájọ́ (9-18) Wọ́n ṣàìgbọràn ní Kadeṣi-bánéà (19-46) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ láti wọ ilẹ̀ náà (26-33) Wọn ò borí àwọn ọmọ Kénáánì (41-46) 2 Wọ́n fi ọdún 38 rìn kiri ní aginjù (1-23) Wọ́n ṣẹ́gun Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì (24-37) 3 Wọ́n ṣẹ́gun Ógù ọba Báṣánì (1-7) Wọ́n pín ilẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì (8-20) Mósè sọ fún Jóṣúà pé kó má bẹ̀rù (21, 22) Mósè ò ní wọ ilẹ̀ náà (23-29) 4 Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn (1-14) Wọn ò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣe (9) Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa jọ́sìn òun nìkan (15-31) Kò sí Ọlọ́run míì àfi Jèhófà (32-40) Àwọn ìlú ààbò ní ìlà oòrùn Jọ́dánì (41-43) Ó fún Ísírẹ́lì ní Òfin (44-49) 5 Jèhófà bá wọn dá májẹ̀mú ní Hórébù (1-5) Wọ́n tún Òfin Mẹ́wàá sọ (6-22) Ẹ̀rù ba àwọn èèyàn náà ní Òkè Sínáì (23-33) 6 Fi gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà (1-9) “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì” (4) Kí àwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn (6, 7) Ẹ má ṣe gbàgbé Jèhófà (10-15) Ẹ ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà wò (16-19) Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín (20-25) 7 Orílẹ̀-èdè méje tí wọ́n máa pa run (1-6) Ìdí tí Ọlọ́run fi yan Ísírẹ́lì (7-11) Wọ́n á ṣàṣeyọrí tí wọ́n bá ṣègbọràn (12-26) 8 Ó rán wọn létí bí Jèhófà ṣe bù kún wọn (1-9) “Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè” (3) Má ṣe gbàgbé Jèhófà (10-20) 9 Ìdí tó fi fún Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ náà (1-6) Ísírẹ́lì múnú bí Jèhófà lẹ́ẹ̀mẹrin (7-29) Ère ọmọ màlúù tí wọ́n fi wúrà ṣe (7-14) Mósè bá wọn bẹ̀bẹ̀ (15-21, 25-29) Wọ́n tún múnú bí Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹta (22) 10 Ó gbẹ́ wàláà òkúta méjì míì (1-11) Ohun tí Jèhófà fẹ́ (12-22) Bẹ̀rù Jèhófà, kí o sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ (12) 11 Ẹ ti rí bí Jèhófà ṣe tóbi tó (1-7) Ilẹ̀ Ìlérí (8-12) Wọ́n á rí ìbùkún tí wọ́n bá ṣègbọràn (13-17) Kí wọ́n tẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ ọkàn wọn (18-25) “Ìbùkún àti ègún” (26-32) 12 Ibi tí Ọlọ́run bá yàn ni kí ẹ ti máa jọ́sìn (1-14) Wọ́n lè jẹ ẹran àmọ́ wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ (15-28) Má ṣe kó sí ìdẹkùn àwọn ọlọ́run míì (29-32) 13 Ohun tí wọ́n máa ṣe fún ẹni tó bá sin ọlọ́run míì (1-18) 14 Ohun tí kò yẹ kí wọ́n ṣe nítorí òkú (1, 2) Àwọn oúnjẹ tó mọ́ àti èyí tí kò mọ́ (3-21) Kí wọ́n mú ìdá mẹ́wàá wá fún Jèhófà (22-29) 15 Lẹ́yìn ọdún méje-méje, kí wọ́n má ṣe san gbèsè pa dà (1-6) Bí wọ́n á ṣe máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́ (7-11) Kí wọ́n máa dá ẹrú sílẹ̀ ní ọdún keje (12-18) Kí wọ́n fi òòlù dá etí ẹrú wọn lu (16, 17) Kí wọ́n ya àwọn àkọ́bí ẹran sí mímọ́ (19-23) 16 Ìrékọjá; Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú (1-8) Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ (9-12) Àjọyọ̀ Àtíbàbà (13-17) Bí wọ́n ṣe máa yan àwọn onídàájọ́ (18-20) Àwọn ohun tí wọn ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn (21, 22) 17 Ẹbọ wọn kò gbọ́dọ̀ ní àbùkù lára (1) Ohun tí wọ́n máa ṣe fún ẹni tó bá sin ọlọ́run míì (2-7) Àwọn ẹjọ́ tó bá ṣòroó dá (8-13) Ìlànà fún ọba tí wọ́n bá yàn (14-20) Kí ọba fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ẹ̀dà Òfin (18) 18 Ìpín àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì (1-8) Wọn ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò (9-14) Wòlíì bíi Mósè (15-19) Bí wọ́n ṣe máa mọ wòlíì èké (20-22) 19 Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àtàwọn ìlú ààbò (1-13) Wọn ò gbọ́dọ̀ sún ààlà sẹ́yìn (14) Àwọn ẹlẹ́rìí níbi ìgbẹ́jọ́ (15-21) Ẹni méjì tàbí mẹ́ta ni kó jẹ́ ẹlẹ́rìí (15) 20 Àwọn òfin tó wà fún ogun jíjà (1-20) Àwọn tí kò ní lọ sójú ogun (5-9) 21 Tí wọn ò bá mọ ẹni tó pààyàn (1-9) Tí wọ́n bá fẹ́ fi ẹrú ṣaya (10-14) Ẹ̀tọ́ àkọ́bí (15-17) Tí ọmọ bá ya alágídí (18-21) Ẹni ègún ni ẹni tí wọ́n bá gbé kọ́ sórí òpó igi (22, 23) 22 Kí wọ́n máa bójú tó ẹran ọmọnìkejì wọn (1-4) Obìnrin ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, ọkùnrin ò sì gbọ́dọ̀ wọ ti obìnrin (5) Máa ṣàánú àwọn ẹyẹ (6, 7) Ṣe ìgbátí sí òrùlé (8) Àwọn ohun tí wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe pọ̀ (9-11) Kókó wajawaja lára aṣọ (12) Àwọn òfin nípa ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ (13-30) 23 Àwọn tí kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Ọlọ́run (1-8) Kí ibùdó máa wà ní mímọ́ (9-14) Ẹrú tó sá lọ (15, 16) Wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe aṣẹ́wó (17, 18) Èlé àti ẹ̀jẹ́ (19-23) Ohun tí ẹni tó ń kọjá lọ lè jẹ (24, 25) 24 Ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀ (1-5) Kí wọ́n máa ka ẹ̀mí sí pàtàkì (6-9) Kí wọ́n máa gba tàwọn aláìní rò (10-18) Òfin nípa pípèéṣẹ́ (19-22) 25 Iye ẹgba tí wọ́n lè na èèyàn (1-3) O ò gbọ́dọ̀ dí akọ màlúù tó ń pa ọkà lẹ́nu (4) Ṣíṣú obìnrin lópó (5-10) Tí obìnrin bá rá ọkùnrin mú ní abẹ́ (11, 12) Ìwọ̀n àti òṣùwọ̀n tó péye (13-16) Kí wọ́n pa àwọn Ámálékì run (17-19) 26 Kí wọ́n mú àkọ́so èso wọn wá (1-11) Ìdá mẹ́wàá kejì (12-15) Ísírẹ́lì jẹ́ ohun ìní pàtàkì fún Jèhófà (16-19) 27 Kí wọ́n kọ Òfin sára òkúta (1-10) Òkè Ébálì àti Òkè Gérísímù (11-14) Wọ́n tún àwọn ègún náà kà (15-26) 28 Ìbùkún fún àwọn tó bá ṣègbọràn (1-14) Ègún fún àwọn tó bá ṣàìgbọràn (15-68) 29 Májẹ̀mú tó bá Ísírẹ́lì dá ní Móábù (1-13) Ìkìlọ̀ fún àwọn tó bá ṣàìgbọràn (14-29) Ohun tó wà nípamọ́, ohun tí a ṣí payá (29) 30 Bí wọ́n ṣe máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (1-10) Àwọn àṣẹ Jèhófà kò nira (11-14) Kí wọ́n yan ìyè tàbí ikú (15-20) 31 Ikú Mósè sún mọ́lé (1-8) Kí wọ́n máa ka Òfin Ọlọ́run sí wọn létí (9-13) Ó faṣẹ́ lé Jóṣúà lọ́wọ́ (14, 15) Àsọtẹ́lẹ̀ bí Ísírẹ́lì ṣe máa ya ọlọ̀tẹ̀ (16-30) Orin láti fi kọ́ Ísírẹ́lì (19, 22, 30) 32 Orin tí Mósè kọ (1-47) Jèhófà jẹ́ Àpáta (4) Ísírẹ́lì gbàgbé Àpáta rẹ̀ (18) “Tèmi ni ẹ̀san” (35) “Ẹ bá àwọn èèyàn rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè” (43) Mósè máa kú sórí Òkè Nébò (48-52) 33 Mósè súre fún àwọn ẹ̀yà wọn (1-29) “Ọwọ́ ayérayé” Jèhófà (27) 34 Jèhófà fi ilẹ̀ náà han Mósè (1-4) Ikú Mósè (5-12) Pa Dà Èyí Tó Kàn Tẹ̀ ẹ́ Fi ránṣẹ́ Fi ránṣẹ́ Diutarónómì—Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí BÍBÉLÌ MÍMỌ́ TI ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN (TÍ A TÚN ṢE LỌ́DÚN 2018) Diutarónómì—Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí Yorùbá Diutarónómì—Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/1001061100/univ/wpub/1001061100_univ_sqr_xl.jpg nwt Diutarónómì ojú ìwé 267-273