Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Dáníẹ́lì

Orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Àwọn ará Bábílónì dó ti Jerúsálẹ́mù (1, 2)

    • Wọ́n dìídì dá àwọn ọmọ ọba tí wọ́n kó lẹ́rú lẹ́kọ̀ọ́ (3-5)

    • Wọ́n dán ìṣòtítọ́ àwọn Hébérù mẹ́rin wò (6-21)

  • 2

    • Ọba Nebukadinésárì lá àlá tó bà á lẹ́rù (1-4)

    • Amòye kankan ò lè rọ́ àlá náà (5-13)

    • Dáníẹ́lì ní kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ (14-18)

    • Dáníẹ́lì yin Ọlọ́run torí pé Ó ṣí àṣírí náà payá (19-23)

    • Dáníẹ́lì rọ́ àlá náà fún ọba (24-35)

    • Ìtumọ̀ àlá náà (36-45)

      • Òkúta tó ṣàpẹẹrẹ ìjọba máa fọ́ ère náà túútúú (44, 45)

    • Ọba dá Dáníẹ́lì lọ́lá (46-49)

  • 3

    • Ère wúrà tí Ọba Nebukadinésárì ṣe (1-7)

      • Ó ní kí wọ́n jọ́sìn ère náà (4-6)

    • Wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn Hébérù mẹ́ta pé wọn ò ṣègbọràn (8-18)

      • “A ò ní sin àwọn ọlọ́run rẹ” (18)

    • Wọ́n jù wọ́n sínú iná ìléru (19-23)

    • Ọlọ́run gbà wọ́n sílẹ̀ nínú iná náà lọ́nà ìyanu (24-27)

    • Ọba gbé Ọlọ́run àwọn Hébérù ga (28-30)

  • 4

    • Ọba Nebukadinésárì gbà pé Ọlọ́run ni ọba (1-3)

    • Ọba lá àlá nípa igi kan (4-18)

      • Ìgbà méje kọjá lórí igi tí wọ́n gé (16)

      • Ọlọ́run ni Alákòóso aráyé (17)

    • Dáníẹ́lì túmọ̀ àlá náà (19-27)

    • Ó kọ́kọ́ ṣẹ sí ọba lára (28-36)

      • Orí ọba dà rú fún ìgbà méje (32, 33)

    • Ọba gbé Ọlọ́run ọ̀run ga (37)

  • 5

    • Àsè Ọba Bẹliṣásárì (1-4)

    • Ìkọ̀wé lára ògiri (5-12)

    • Wọ́n ní kí Dáníẹ́lì sọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà (13-25)

    • Ìtumọ̀: Bábílónì máa ṣubú (26-31)

  • 6

    • Àwọn ìjòyè ilẹ̀ Páṣíà gbìmọ̀ pọ̀ láti mú Dáníẹ́lì (1-9)

    • Dáníẹ́lì ò yéé gbàdúrà (10-15)

    • Wọ́n ju Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún (16-24)

    • Ọba Dáríúsì bọlá fún Ọlọ́run Dáníẹ́lì (25-28)

  • 7

    • Ìran àwọn ẹranko mẹ́rin (1-8)

      • Ìwo kékeré kan tó ń gbéra ga jáde (8)

    • Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé mú ìjókòó ní kọ́ọ̀tù (9-14)

      • Wọ́n fi ọmọ èèyàn ṣe ọba (13, 14)

    • A fi ìtumọ̀ han Dáníẹ́lì (15-28)

      • Ọba mẹ́rin ni àwọn ẹranko mẹ́rin náà (17)

      • Àwọn ẹni mímọ́ máa gba ìjọba (18)

      • Ìwo mẹ́wàá, tàbí ọba mẹ́wàá, máa dìde (24)

  • 8

    • Ìran àgbò àti òbúkọ (1-14)

      • Ìwo kékeré kan gbé ara rẹ̀ ga (9-12)

      • Títí di 2,300 alẹ́ àti àárọ̀ (14)

    • Gébúrẹ́lì túmọ̀ ìran náà (15-27)

      • Àlàyé nípa àgbò àti òbúkọ náà (20, 21)

      • Ọba kan tí ojú rẹ̀ le dìde (23-25)

  • 9

    • Dáníẹ́lì gbàdúrà ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ (1-19)

      • Jerúsálẹ́mù máa dahoro fún 70 ọdún (2)

    • Gébúrẹ́lì wá bá Dáníẹ́lì (20-23)

    • Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àádọ́rin ọ̀sẹ̀ (24-27)

      • Mèsáyà máa fara hàn lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ 69 (25)

      • Wọ́n máa pa Mèsáyà (26)

      • Ìlú náà àti ibi mímọ́ máa pa run (26)

  • 10

    • Ìránṣẹ́ Ọlọ́run bẹ Dáníẹ́lì wò (1-21)

      • Máíkẹ́lì ran áńgẹ́lì náà lọ́wọ́ (13)

  • 11

    • Àwọn ọba Páṣíà àti Gíríìsì (1-4)

    • Àwọn ọba gúúsù àti àríwá (5-45)

      • Afipámúni máa dìde (20)

      • A ṣẹ́ Aṣáájú májẹ̀mú náà (22)

      • Ó yin ọlọ́run ibi ààbò lógo (38)

      • Ọba gúúsù àti ọba àríwá máa kọ lu ara wọn (40)

      • Ìròyìn tó ń yọni lẹ́nu láti ìlà oòrùn àti àríwá (44)

  • 12

    • “Àkókò òpin” àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà (1-13)

      • Máíkẹ́lì máa dìde (1)

      • Àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa tàn yinrin (3)

      • Ìmọ̀ tòótọ́ máa pọ̀ yanturu (4)

      • Dáníẹ́lì máa dìde fún ìpín rẹ̀ (13)